Èdè Lyélé language (Lele) jẹ́ èdè kan tí wọ́n ń sọ ní agbègbè Sanguié ní orílẹ̀ èdè Burkina Faso, àwọn tó ń sọ èdè náà tó ọ̀kẹ́ mẹ̀fà àbọ̀ (130,000), orúkọ tí wọ́n ń sì ń pe èdè yìí ni Lyéla, Léla, Gourounsi tàbí Gurunsi. Wọ́n ń só ní ìlú Réo, Kyon, Tenado, Dassa, Didyr, Godyr, Kordié, Pouni àti Zawara. Àwọn míràn tún ń pe èdè náà ní Gurunsi. Lyélé jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èdè SVO.

Lyélé
Lele
Sísọ níBurkina Faso
Ìye àwọn afisọ̀rọ̀Àdàkọ:Sigfig
Èdè ìbátan
Àwọn àmìọ̀rọ̀ èdè
ISO 639-3lee

Àwọn lẹ́tà áfábẹ́tì wọn àtúnṣe

Áfábẹ́tì Lyélé.[1]
a b c d e ə ɛ f g h i j k l ly m n ŋw ny o p r rh s sh t u v w y z zh

Wọ́n ma ń lọ àwọn àmì sí ara Áfábẹ́tì Lyele láti fi ṣe Ìyàtọ̀ láàrin ọ̀rọ. Ohùn òkè àti ìsàlẹ̀ ní àmì ṣùgbọ́n ti àárín kò ní.

Àwọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. Nikiema 1993, p. 50.