Àwọn Yorùbá gbàgbó pé ẹ̀mí áìrí méjì ni ó wà. Bí rere ṣe wà bẹ́ẹ̀ náà ni búburú náà wa. Wọn tún ní èrò pé oríṣi ẹ̀mí áìrí méjì ló wà (àwọn òrìṣà ati àwọn òkú ọ̀run.

   Àwọn wọn èmi áìrí rere yìí ni ó máa ń ṣe àtilẹhin fún ènìyàn ní ojojúmọ́ ayé rẹ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn lé bínú sí ẹnikẹ́ni to bá kọ tàbí kùnà láti ṣe ojúṣe rẹ fún ẹlòmíràn.
  Láti ọ̀dọ̀ Orunmila tí ó jẹ agbẹnusọ àwọn ẹ́mi áìrí yìí ni ó máa ń mọ ẹbọ tàbí ètùtù tí wọn yóò gbà nígbà tí àwọn ẹ́mi áìrí yìí bá ń bínú láti fi tú wọn lójú. Àmọ́ sá a Yorùbá gbàgbó pé àwọn ẹ́mi yìí kì dédé bínú sí ẹnikẹ́ni ní kó ṣe pé wọn dabobo ẹni náà lọ́wọ́ èmi búburú yòókù.
   Oríṣi méje ni wọn gba pe ẹ̀mí áìrí búburú yìí pín sí. Àwọn ni Ajogun àti àwọn Ẹlẹyẹ tí a mọ sì àwọn Àjẹ́. Àwọn èyí wá láti bá Ire ọmọ ènìyàn jẹ tàbí yẹ kádàrá daada tí ènìyàn bá yàn. Orúkọ àwọn ajogun náà ni :Ikú, Àrùn, Ọfọ̀,Èpè, Éwọ̀n àti Ọ̀ràn. Ẹbọ ni wọn fi ń tú àwọn atogun yìí lójú.
    Gbogbo agbaye gbàgbọ́ pé kí ńkan bàjẹ̀ ni àwọn àjẹ̀ wá fún,wọn ṣe tán láti bà ohùn tí ó dà àti dùn jẹ́.ọ̀pọ̀ igbá orí ẹni ní máa ko ni yọ lọ́wọ́ wọn tàbí ẹbọ rírú. Àwọn Yorùbá gbàgbó pé ọ̀tá ènìyàn ni Iwin jẹ àti pé òru ni wọn máa ń jáde ti wọn si rìn bi ọmọ ènìyàn. Àwọn mìíràn ni ojú mẹ́ta tí òmíràn sì ni ojú kan ni ìpàkọ̀. Imúra ìjà àti ìjàmbá ni wọn má ń sábà ṣe fún ẹni tí wọn ba pade ni ojú ọ̀nà..