Ẹ̀pọ́n
Ẹ̀pọ́n ni ìsọ́rí gírámà tí a máa ń lò láti fi pọ́n ọ̀rọ̀-ìṣe lé. Ẹ̀pọ́n máa ń mú kí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀-ìṣe pé tàbí kí ó fi kún ìtumọ̀ tí ọ̀rọ̀-ìṣe ní. Nínú ìhun àpólà ìṣe, orí tí ó jẹ́ ọ̀rọ̀-ìṣe nìkan ni ó jẹ́ kàńpá, wọ̀fún ni àwọn ìyókù.
Ìpínsísọ̀rí ẹ̀pọ́n
àtúnṣeA lè pín ẹ̀pọ́n sí ọ̀nà méjì. Àwọn ni :Ẹ̀pọ́n asàfikún àti Ẹ̀pọ́n asàmúpé.
Ẹpọ́n aṣàfikún
àtúnṣeẸ̀pọ́n asàfikún ní ó máa ń fi kún ìtumọ̀ ọ̀rọ̀-ìṣe asorí, kì í mú kí ìtumọ̀ rẹ̀ pé. Orísìí ẹ̀pọ́n asàfikún méjì ló wà, a ní ẹ̀pọ́n asàfikún aṣáájú ọ̀rọ̀-ìṣe asorí àti ẹ̀pọ́n asàfikún atẹ̀lé ọ̀rọ̀-ìṣe asorí.
Ẹpọ́n aṣàfikún aṣáájú
àtúnṣeẸ̀pọ́n asàfikún aṣáájú ọ̀rọ̀-ìṣe asorí ni ẹ̀pọ́n tí ó máa ń ṣáájú ọ̀rọ̀-ìṣe.A lè pín ẹ̀pọ́n asàfikún aṣáájú ọ̀rọ̀-ìṣe sí ọ̀nà méjì,àwọn ni :Ẹ̀pọ́n asàfikún aṣáájú agbàbọ̀ àti ẹ̀pọ́n asàfikún aṣáájú aláìgbàbọ̀.
Ẹpọ́n aṣáájú agbàbọ̀
àtúnṣeÀwọn ni ẹ̀pọ́n tí ó máa ń ṣáájú ọ̀rọ̀-ìṣe asorí tí ó máa ń gba àbọ̀. Bí àpẹẹrẹ :
Olú bá Òjó ṣe ọbẹ̀
Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí, ẹ̀pọ́n ni "bá Òjó", iṣẹ́ àfikún ni ó sì ń ṣe pẹ̀lú. A lè yọ ọ́ kúrò nínú ẹ̀hun/gbólóhùn náà kí ó sì tún ní ìtumọ̀ tàbí kí ìsọ náà jẹ́ aseégbà.
Ẹpọ́n aṣáájú aláìgbàbọ̀
àtúnṣeÀwọn ni ẹ̀pọ́n tí ó máa ń ṣáájú ọ̀rọ̀-ìṣe asorí tí kì í gba àbọ̀. Bí àpẹẹrẹ :
Olú kọ́kọ́ mu gààrí
Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí, ẹ̀pọ́n ni "kọ́kọ́", iṣẹ́ àfikún ni ó sì ń ṣe pẹ̀lú. A lè yọ ọ́ kúrò nínú ẹ̀hun /gbólóhùn náà kí ó sì ní ìtumọ̀ tàbí kí ìsọ náà jẹ́ aseégbà
Ẹpọ́n aṣàfikún atẹ̀lé
àtúnṣeẸ̀pọ́n asàfikún atẹ̀lé ni ẹ̀pọ́n tí ó máa ń tẹ̀lé ọ̀rọ̀-ìṣe asorí. A lè pín ẹ̀pọ́n asàfikún atẹ̀lé ọ̀rọ̀-ìṣe asorí sí ọ̀nà méjì, àwọn ni : Ẹ̀pọ́n atẹ̀lé agbàbọ̀ àti ẹ̀pọ́n atẹ̀lé aláìgbàbọ̀
Ẹpọ́n atẹ̀lé agbàbọ̀
àtúnṣeẸ̀pọ́n atẹ̀lé agbàbọ̀ ni ẹ̀pọ́n atẹ̀lé ọ̀rọ̀-ìṣe asorí tí ó máa ń gba àbọ̀. Bí àpẹẹrẹ :
Olú mu gààrí ní àárọ̀
Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí, ẹ̀pọ́n ni "ní àárọ̀". A lè yọ ọ́ kúrò nínú gbólóhùn náà kí ó sì tún jẹ́ aseégbà tàbí kí ó sì tún ní ìtumọ̀.
Ẹpọ́n atẹ̀lé aláìgbàbọ̀
àtúnṣeẸ̀pọ́n atẹ̀lé aláígbàbọ̀ ni ẹ̀pọ́n atẹ̀lé ọ̀rọ̀-ìṣe asorí tí kì í gba àbọ̀. Bí àpẹẹrẹ :
Olú sùn fọnfọn
Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí, ẹ̀pọ́n ni" fọnfọn". A lè yọ ọ́ kúrò nínú ẹ̀hun/gbólóhùn náà kí ó sì tún jẹ́ aseégbà tàbí kí ó sì tún ní ìtumọ̀.
Ẹpọ́n asàmúpé
àtúnṣeẸ̀pọ́n asàmúpé máa ń mú kí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀-ìṣe asorí pé. Àpólà orúkọ (àbọ̀) àti àpólà asẹ̀pọ́n ni ó máa ń ṣiṣẹ́ asàmúpé nínú gbólóhùn. A lè rí méjèèjì nínú gbólóhùn kan, tàbí kí á rí wọn nínú gbólóhùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Bí àpẹẹrẹ.
Ẹṣin náà ta olówó rẹ̀ ní ìpá
Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí, àpólà orúkọ (àbọ̀) àti àpólà asẹ̀pọ́n ń mú kí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀-ìṣe asorí tíí ṣe "tá" pé. A kò lè yọ èyíkéyìí nínú àbọ̀ àti àpólà asẹ̀pọ́n inú gbólóhùn náà kí ìsọ náà sì tún jẹ́ aseégbà. Iṣẹ́ àmúpé ni "olówó rẹ̀ ní ìpá" ń ṣe nínú gbólóhùn náà.
Olú jẹ iṣu
Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí, àbọ̀ nìkan ni ọ̀rọ̀-ìṣe asorí gbà gẹ́gẹ́ bí àmúpé rẹ̀ láìsí àpólà asẹ̀pọ́n níbẹ̀. Iṣẹ́ àmúpé ni "jẹ iṣu" ń ṣe nínú gbólóhùn náà
Ọbẹ̀ náà ta ṣánṣán
Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí, àpólà asẹ̀pọ́n nìkan ni ọ̀rọ̀-ìṣe asorí gbà gẹ́gẹ́ bí àmúpé rẹ̀ láìsí àpólà orúkọ (àbọ̀) níbẹ̀. Iṣẹ́ àmúpé ni "ṣánṣán" ń ṣe nínú gbólóhùn náà.