BUDDHISM (Ẹ̀SÌN BUDDA)

ÌBÍ BUDDA

Ìgbàgbọ́ ìbílẹ̀ fi han wí pé a bi Budda si ìdílé Ọba ni Orílé-èdè “Lumbini, Nepal ní Teria” lẹba “Himalayas”. Nítorí náà, àwọn àwòràwọ̀ wí pé ní ìlú “Kalinga” èyí tí o ti di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ ní ìlú “India” ni a gbé bí i.

O jẹ́ ọmọ ẹbí “Sakays”. Orùkọ bàbá rẹ ni “Suddhodana”. A bí Budda nínú ìdílé Ọba. Orúkọ ìyá rẹ ni “Maya”.

Kò si ẹni ti o mọ àkọsílẹ̀ ọjọ́ ibi rẹ̀ pàtó tàbí ti o ni àkọsílẹ̀ rẹ̀. Olúkúlùkù kan ńsọ àwọn ọjọ́ ti wọn rò pe o le jẹ́ ni nítorí kò si àkọsílẹ̀ kan pàtó ti a le tọka sí. Àwọn oǹpìtàn kan ní a bi i ni ọdun “623 tàbí 624 BCE”. Kò pé kò jiìnà yíì ni àwọn ẹlésìn kan sọ wí pé ọjọ ibii rẹ̀ títí di ọjọ́ ti o gbé lórí eèpẹ̀ jé ni aarin ọdún 567 si 487 BCE” .

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n wí pé a bí ì ni Ọdún 420 sí 502 BCE” ki a ma fi ọ̀pá pọ̀lọ̀pọlọ pa ejò, kò sí ìdánilójú ọjọ́ ibii rẹ̀ àti ọjọ́ ti ó lò láyé.

Àwọn ohun ti a ri nínú àkọsílẹ̀ ti o ṣe pàtàkì ni pé a bi i ni ọ̀nà ìyanu. Lẹ́hìn ìbí rẹ̀, o dìde dúró ó gbé àwọn ìgbésè nínú èyí tí o kede ara rẹ̀ wí pé òun yoo jẹ́ ìjòyè ayé. O wí pé èyí ni yoo jẹ́ ìgbà ti òun yoo padà wá sáyé gbẹ̀hìn.

Orúkọ ti àwọn obi rẹ́ sọ o ni “Siddhartha Gautama”. “Siddhartha” . Eyi túmọ̀ sí “ẹni ti o ti kẹ́sẹ járí ṣùgbọ́n “Gautama” ni orúkọ ìdílé tí a bí i si. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni wọn má n pe e ni “Sakayamuni”, itumọ̀ èyí tí ń jẹ́ amòye nínú “Sakyas”.

ÌBÈRÈ PẸ̀PẸ̀ AYÉ RẸ̀

“Sakyamuni” jẹ́ ẹni ti a tọ́ lọ́nà ẹ̀sìn “Hindu”, èrò àwọn òbí rẹ̀ ni ki o jẹ́ arópò Bàbá rẹ̀ lẹ́hìn ìgbà tí ó bá gbẹ́sẹ̀. Wọ́n ro wí pé yoo lánfààní lati jẹ́ ìlù mọọ́ká Ọba tàbí olórí ẹ̀sìn ńlá kan ti o se jìnmọ̀wò. Àwọn òbí rẹ̀ tọ́ọ ni ọna ọlá àti ọlà kí ohun ti o wá se l’áyé lé rọrùn fún-un àti ki o le gbé ìgbé ayé ẹ̀sìn wọn.

Ní ìgbà tí o di ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ni o gbé ìyàwó, orúkọ́ ìyàwó rẹ̀ a má jẹ́ “Yasodhara”, Nígbà tí o pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ́n ni ìyàwó rẹ̀ bi ọmọ ọkùnrin kan fún-un orúkọ rẹ̀ a ma jẹ́ “Rahula”. Lẹ́hìn tí o bi ọmọ yii tán ìtàn fi ye wa wí pé o se ìrìnàjò lori ẹ̀sìn lẹ́ẹ̀mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, nígbà tí ọ̀pọ̀ ìtàn sọ wí pé ń se ni o ri ìran lẹ́ẹ̀mẹ́rin. Nínú ìrìnàjò rẹ̀ àkókọ́ o ri ọkùnrin arúgbó kan ti o jẹ́ aláilòlùránlọ̀wọ́, ní ìrìnàjò rẹ kejì ó rí ọkùnrín ti àìsàn ti o lágbára juu lọ ń ba a fínra, ní ìrìn àjò rẹ kẹta o ri ìdílé kan ti ìbànújẹ́ bò mọ́lè ti wọn si ńgbé ọkàn nínú wọn ti o se aláìsí lọ si ibojì. Ó ronú jinlẹ̀ lórí ìsòro ti àwọn arúgbó n kójú bi àìsàn àti ikú.

Nínu ìrìn àjò rẹ̀ kẹrin, o ri ẹlésìn kan ti o pè sí ìrònú nípa ohun ti o rí nígbà yii ni ọ̀kan rẹ to rú sókè láti tẹ̀lé ọ̀nà àti le se ìrànlọ́wọ́ nípa ti ẹ̀mí papa fún ìsòro ti o n kojú ọmọ ènìyàn.

Ó fi aya, ọmọ àti ìgbé ayé ìrọ̀rùn àti ìgbá ayé asáajú àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ lati se ìwadi ìyànjú ìsòro ẹ̀dá.

Ní àkókò nàá àwọn ọkùnrin miran a ma kúrò ni ilé lati lọ d’ánìkàn wà nínú igbó tàbí ibití o se kọ́lọ́fín nítorí wọn fẹ́ mọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ kan.

WÍWÁ Ọ̀NÀ SI ÌSÒRO TI O N KO Ẹ̀DÁ LÓJÚ

O kọ́kọ́ gbìyànjú lati ronú ohun tí o kó lati ọ̀dọ̀ àwọn olùkọ́ rẹ méjì òtóotọ́, o rò wí pé èyí ni ó se iyebíye.

Ṣùgbọ́n ìrònú yii kò le tẹ̀síwájú lọ títí nítorí náà o yípadà nínú ìrònú náà ki o le dojú kọ àwọn ìsoro náà tí ó ń fẹ́ yanjú èyí, ti o jẹmọ́ ìbímọ, àìsàn ọjọ́ ogbó àti ikú.

Ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ti wọn jọ ni èrò kan lorí wíwà ọ̀nà si ìsòro tí o n dojúkọ ènìyàn, ní bẹ́ẹ̀ ni o ti kọ onírúrú ohun bi ki a sé èémi àti bi a ti gba àwẹ̀ léraléra.

Àwọn ohun ti o gbékalẹ̀ fún ara rẹ yìí jẹ́ ohun ti o nira lópọ̀lọpọ̀ nítorí náà o fi sílẹ̀ lai tún tèsíwájú nípa rẹ mọ́, àwọn ti o se fífi íyá jẹ ara ẹni gbíga àwẹ̀ tàbi sìn rẹ̀ “Hendu” kò si ọ̀nà àbáyọ si ìsòro ti o ńfẹ́ ìyanjú nítorí náà o tún pinnu láti se àwárí ọ̀nà míràn láti le tú àwọn ènìyàn sílẹ̀ nínú ìsòro ti o ń dojú kọ wọ́n.

ÀWỌN ÌFOYÈHÀN BUDDA

Ni àsálẹ́ ọjọ́ kan ni “535 BCE” ni ìgbà tí o pé ọmọ ọdún márùndínlógòji O joko lábẹ́ igi ńla kan ti a mọ̀ si igi Bódì. O bẹ̀rẹ̀ si ni ri ìrírí nípa àseyọrí t’ẹ̀mí.

(1) Ní alẹ́ àkókó o rántí ìgbé ayé kí a kú ni ibikan ki a si tún wà ni ibòmíràn gẹ́gẹ́ bi alààyè.

(2) Ni ale ọjị keji o ri bi igbe aye ibi ati ika ti ọpọlọpọ̀ ma n gbe se ma n so ibiti wọn yóò lọ lẹhin iku.

(3) Ni alé ọjọ kẹta o kọ́ wí pé oun ti tèsíwájú kọja ipele biba ẹmi jẹ́ nipa ikorira, ibinu, ongbe, ibẹru àti ijaya o si pinnu wí pé oun ko tún ni wá s’áyé mọ́. O ti ni ifoyehan o si di “Olugbala, enito n gbani àti Olùràpadà”

Lẹ́hìn ìfoyèhàn rẹ̀ yi o gbìyànjú láti jẹ́ ki ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ̀ nípa pipolongo ẹ̀kó rẹ̀ si wọ́n èyí ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ si gbàgbọ́ ti wọn si ń tẹlẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀.