Thomas Makanjuola Ilesanmi

Thomas Mákánjúọlá Ilésanmí (2002) Ẹ̀wù Àgbà Ibadan; University Press PLC Ibadan, ISBN 978-030-823-7 Ojú-iwé 68.

Ìfáárà

Ohun gún-ún mọ́ ń sọnù nílẹ̀ yìí.

Àwọn ènìyàn ní ò fura.

Ohun ràbàtà ń pòórá láwùjọ aṣùwàdà,

Ọmọ adáríhunrun ni kò náání

Àwọn àfín olókun wọlé tọ̀ wá wá.

Wọ́n fara nù wá lára,

Wọ́n ṣe bí eré bí eré,

Wọ́n jí orí Olókun lọ.

Wọ́n pọ́ mìnì mìnì bí ológìnní,

Wọ́n gbé iṣẹ́-ọnà ìṣẹ̀ǹbáyé lọ

Mọ́ gbogbo ọmọ Oòduà lọ́wọ́.

Agọ̀ eégún ń pòórá nígbó ìgbàlẹ̀,

Ilé orí ọlọ́jọ́ gbọọrọ ti báfẹ́fẹ́ wọn lọ.

Ẹdan tó ní láárí ń bẹ ní mùsíọ́ọ̀mù,

Ní ilé ààbò fún ìtọ́jú nǹkan ìṣẹ̀nbáyé, tí àwọn ẹni funfun

Tí wọ́n dira bí asínwín

Fi jí wa lóhun ribiribi lọ.