Ẹ̀yà Àwórì
Ẹ̀yà Àwórì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìran Yorùbá tó sẹ̀ wá láti Ilé-Ifẹ̀. A lè rí àwọn Àwórì ní ìpínlẹ̀ Èkó àti [[Ògùn] .[1]
Ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn Àwórì
àtúnṣeBabańlá àwọn Àwórì, Ọlọ́fin Ògúnfúnminíre ni ìtàn sọ wípé ó kúrò ní Ilé-Ifẹ̀ , tí ń ṣe orírun àwọn Yorùbá. Nígbà tí ó fẹ́ rìnrìn àjò náà, Odùduwà tí ń ṣe Babańlá wọn fún un ní àwo kan, pẹ̀lú àṣẹ wípé kí ó gbé àwo náà sórí omi tó ń ṣàn, àti wípé ibikíbi tí àwo náà bá ti dúró sí, ibẹ̀ ni kí o tẹ̀dó sí. BÍ ó ti bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò náà, àwo náà kọ́kọ́ dúró sí Olókèméjì, ní ìtòsí Abẹ́òkúta, lẹ́yìn ọjọ́ méje, àwo náà tún bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣàn lọ, ó tún dúró ní abúlé kan tí wọ́n ń pè ní Òkè-ata àti apá àríwá Abẹ́òkúta, Ìṣẹri, fún odidi ọjọ́ méje méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Gbogbo ibi tí àwo yìí bá dúró sí ní ara àwọn ọmọlẹ́yìn Ọlọ́fin máa ń tẹ̀dó sí, àwọn tí ibẹ̀ kò bá tẹ́ lọ́rùn a sìn máa bá ìrìn àjò wọn lọ pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà àwo náà. Àwo yìí pẹ́ púpò ní Ìṣẹri tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí Ọlọ́fin fi pàṣẹ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ ibùgbé wọn. Lẹ́yìn tí èyí ṣẹlẹ̀, àwo yìí tún bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ kí ó tó wá dúró ní Ìdó ni Ìdúmọtà ní ìpínlẹ̀ Èkó. Lórí omi odò Ìdúmọtà ni àwo yìí tí yí káàkiri tí ó sì rì lọ́jọ́ kan tí Ọlọ́fin kò sí nílé. Nígbà tí ó dé, ó béèrè ibi tí àwo náà wà, wọ́n sìn sọ fún un pé àwo (náà) tí rì. Ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣokùnfà orúkọ àwọn Àwórì nìyí tí wọ́n fi ń pè wọ́n ní Àwórì. Ìdúmọtà yìí ni Ọlọ́fin àti àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù tẹ̀dó sí, kí wọ́n tó tún tàn káàkiri àgbègbè ibi tí àwọn Àwórì ń gbé títí di òní yìí. [2] [3] [4] [5] [6]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Ajayi, E.A.; Ajetunmobi, R.O.; A, A.S.; Akindele, S.A. (1998). A History of the Awori of Lagos State. Adeniran Ogunsanya College of Education. ISBN 978-978-142-035-1. https://books.google.com/books?id=TH0uAQAAIAAJ. Retrieved 2019-12-04.
- ↑ Eades, J.S.; Jeremy Seymour Eades, E. (1980). The Yoruba Today. Cambridge Latin Texts. Cambridge University Press. p. 15. ISBN 978-0-521-22656-1. https://books.google.com/books?id=fwc5AAAAIAAJ&pg=PA15. Retrieved 2019-12-04.
- ↑ Peil, M. (1991). Lagos: the city is the people. World cities series. G.K. Hall. ISBN 978-0-8161-7299-3. https://books.google.com/books?id=Iy6FAAAAIAAJ. Retrieved 2019-12-04.
- ↑ "Awori People: A brief history and belief of the original indigenes of Lagos". Pulse Nigeria. 2019-10-14. Retrieved 2019-12-04.
- ↑ "What does awori tribe mean?". Definitions.net. 2019-12-04. Retrieved 2019-12-04.
- ↑ "Awori own Lagos land, Bini produce Oba – Prof. Smith". Punch Newspapers. 2015-12-15. Retrieved 2019-12-04.