Ẹ̀yà ara ifọ̀
Ẹ̀yà ara ifọ̀ ni àwọn ẹ̀yà ara tí a máa ń lò fún gbígbé ìró ifọ̀ jáde. Bí a bá sọ pé "Mo fẹ́ jeun", àwọn ẹ̀yà ara kan wà láti orí dé ikùn wa tí wọ́n jùmọ̀ ń ṣiṣẹ́ papọ̀ láti gbé ìró yìí jáde ní ẹnu. Àwọn ẹ̀yà ara bẹ́ẹ̀ ni à ń pè ní ẹ̀yà ara wọn ifọ̀. Ìró tí àwọn ẹ̀yà ara wọ̀nyí gbé jáde ni à ń pè ní ìró ifọ̀.
Ẹ̀yà ara ifọ̀ tí a le fojú rí
àtúnṣeìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ara tí a le fi ojú rí nípa lílo dígí tàbí nǹkan mìíràn. Àwọn ni:
- Ètè òkè
- Ètè ìsàlè
- Eyín òkè
- Eyín ìsàlẹ̀
- Èrìgì
- Àjà ẹnu
- Ahọ́n
- Àfàsé
- Àjà ẹnu, abbl.
Ẹ̀yà ara ifọ̀ tí a kò le fojú rí
àtúnṣeÌwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ara ifọ̀ tí wọ́n wà láti inú ikùn sí ọ̀fun wa tí a kò le fojú rí. Àwọn:
- Ẹ̀dọ̀ fóóró
- Kòmóòkun
- Ẹ̀ka kòmóòkun
- Gògóńgò
- Káà ọ̀fun
- Tán-án-ná, abbl.
Àpèjúwe ìrísí àti ipa àwọn ẹ̀yà ara ifọ̀ kọ̀ọ̀kan
àtúnṣe1. Ẹ̀dọ̀-fóóró: Inú ẹ̀dọ̀-fóóró ni èémí tí à ń lò fún ìró ifọ̀ ti ń tú jáde.
2. Ẹ̀ka kòmóòkun: Ẹ̀ka kòmóòkun ni ẹ̀ka méjì tí wọ́n wọ inú ẹ̀dọ̀-fóóró láti ara kòmóòkun. Wọ́n jẹ́ ọ̀nà fún èémí láti gbà kọjá wọ́ inú gògóńgò.
3. Gògóńgò: Orí kòmóòkun téńté ni gògóńgò dábùú lé ní ọ̀fun. A le rí ìta gògóńgò ní ọ̀fun wa.
4. Tán-án-ná: Inú gògóńgò ni tán-án-ná wà. Inú rẹ̀ ni ìdíwọ́ ti ń ṣẹlẹ̀ sí èémí tó ń bọ̀ láti inú ẹ̀dọ̀ fóóró.
5. Àlàfo Tán-án-ná: Ó jẹ́ ààyè tó wà láàrin Tán-án-ná tí èémí àmísóde ti ń yí padà di ìró, tí yóò sì gbà jáde sí ọ̀nà ọ̀fun. Ipò méjì ni àlàfo Tán-án-ná le wà tí a bá gbé ìró jáde; ipò ìmí àti ìkùn.
7. Ahọ̀n: Ahọ̀n jẹ́ ẹ̀yà ara tí ó ṣe pàtàkì púpò nínú gbígbé ìró ohùn jáde, ọ̀nà mẹ́ta pàtàkì ni a le pín ahọ́n sí; iwájú, àárín, àti ẹ̀yìn. Ìró ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni à ń gbé jáde tí a bá lo ọ̀kọ̀ọ̀kan apá yìí.
ÀFIPÈ
Èyí ni àwọn ẹ̀yà ara ifọ̀ tí wọ́n ń kópa nínú pípé ìró èdè jáde. Àwọn ẹ̀yà ara ifọ̀ àfipè bẹ̀rẹ̀ láti òkè àlàfo tán-án-ná dé ihò ẹnu àti imú. Ọ̀gangan ibí wọ̀nyí ni à ń pè ní òpópónà ajẹmọ́hùn. A le pín Àfipè sí ọ̀nà méjì:
1. Àfipè Àsúnsí: Àwọn ẹ̀yà ara ifọ̀ tí wọ́n wà ní àgbọndò ìsàlẹ̀ ẹnu, tí wọ́n máa ń sún sókè sódò nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀. Àwọn ni: Ètè ìsàlẹ̀, eyín ìsàlẹ̀, èrìgì, àti ahọ́n.
2. Àfipè Àkànmọ́lẹ̀: Àwọn ẹ̀yà ara ifọ̀ tí wọ́n wà ní òkè ẹnu wa, tí wọ́n dúró gbári sí ojú kan nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀. Àwọn ni: ètè òkè, èrìgì, àjà-ẹnu, àfàsé.
Àfipè àsúnsí ni ó máa ń sún lọ bá àfipè àkànmọ́lẹ̀.