Ẹ̀yán
Ẹ̀yán ni a máa ń lò láti yán ọ̀rọ̀ orúkọ nínú àpólà tàbí gbólóhùn. Ẹ̀yán kò lè dá dúró fúnra rẹ̀ láìsí ọ̀rọ̀ orúkọ tí ó ń yán níbẹ̀. Bí ìgbín bá fà ìkarahun a tẹ̀lé e ni ọ̀rọ̀ ẹ̀yán àti ọ̀rọ̀ orúkọ tí ó ń yán. Bí a bá fẹ́ gbé ọ̀rọ̀ orúkọ kúrò nípò kan, a gbọ́dọ̀ gbé e papọ̀ pẹ̀lú ẹ̀yán rẹ̀ ni. Ọ̀rọ̀ orúkọ àti ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ gígùn nìkan ni ó lè gba ẹ̀yán. Ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ kúkúrú kò lè gba ẹ̀yán. Ọ̀rọ̀ orúkọ àti ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ gígùn ni ó lè jẹ́ ẹ̀yán. Àpẹẹrẹ :
Baba àgbà jẹ iṣu díndín
Ọmọ náà lọ ilé
Nínú àpẹẹrẹ àkọ́kọ́, iṣẹ́ ẹ̀yán ni "àgbà" ń ṣe nínú ẹ̀hun tàbí gbólóhùn náà. Nínú àpẹẹrẹ kejì, iṣẹ́ ẹ̀yán ni "náà" ń ṣe nínú ẹ̀hun náà.
Oríṣìí Ẹ̀yán
àtúnṣeOrísìí ẹ̀yán mẹ́fà ni ó wà nínú èdè Yorùbá, àwọn ni :
- Ẹ̀yán ajórúkọ
- Ẹ̀yán aṣàpèjúwe
- Ẹ̀yán asòǹkà
- Ẹ̀yán awẹ gbólóhùn
- Ẹ̀yán asàfihàn
- Ẹ̀yán atọ́ka asàfihàn
Ẹ̀YÁN AJÓRÚKỌ
àtúnṣeẸ̀yán ajórúkọ ni ibi tí ó ti jẹ́ pé ẹ̀yán tí ó ń yán orí náà máa ń jẹ́ ọ̀rọ̀ orúkọ. A lè pín ẹ̀yán ajórúkọ sí ọ̀nà méjì, àwọn ni Ẹ̀yán alálàjẹ́ àti ẹ̀yán oníbàátan.
Ẹ̀yán alálàjẹ́
àtúnṣeẸ̀yán alálàjẹ ni ibi tí orí àti ẹ̀yán tí ó ń yán orí ń ti jọ ń tọ́ka sí ẹnìkan. Bí àpẹẹrẹ :
- Òjó káfíntà kú lànà.
- Ọmọ aláìgbọràn náà padà kú.
- Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí, ẹnìkan náà ni ó ń jẹ́ Òjó àti káfíntà.
Ẹ̀yán Oníbàátan
àtúnṣeẸ̀yán oníbàátan máa ń fi ìní hàn láàárín ọ̀rọ̀ orúkọ tí ó jẹ́ orí àti ẹ̀yán rẹ̀.Bẹ́ẹ̀ náà ni ó máa ń fi ìgbà àti ibùgbé hàn. Bí àpẹẹrẹ :
- Ilée Délé jóná.
- Ọbẹ̀ àná tutù púpọ̀.
- Olóńgbò igbó náà dúdú gan-an.
Nínú àwọn àpẹẹrẹ òkè yìí, "Délé", "àná tutù" àti "igbó náà" jẹ́ ẹ̀yán oníbàátan tí ó ń yán orí nínú gbólóhùn òkè yìí.
Ẹyán Aṣàpèjúwe
àtúnṣeẸ̀yán asàpèjúwe ni a máa ń lò láti ṣe àpèjúwe bí orí ṣe rí. Nínú èdè Yorùbá, a kò ní ọ̀rọ̀ àsàpèjúwe ṣùgbọ́n a ní ẹ̀yán asàpèjúwe. Kọ́ńsónáńtì ni ó máa ń bẹ̀rẹ̀ ẹ̀yán asàpèjúwe nínú èdè Yorùbá. Àpẹẹrẹ :
- Aṣọ dúdú ni ọkùnrin náà rà.
- Ẹyin funfun ni adìyẹ náà yé.
Nínú àpẹẹrẹ méjèèjì òkè yìí, iṣẹ́ ẹ̀yán asàpèjúwe ni "dúdú" àti "funfun" ń ṣe nínú gbólóhùn náà.
Ẹyán Aṣòǹkà
àtúnṣeẸ̀yán asòǹkà ni a máa ń lò láti sọ iye tí nǹkan jẹ́. Ẹ̀yán asòǹkà máa ń sọ ní pàtó iye tí orí jẹ́. Bí àpẹẹrẹ :
- Bádéjọ kọ́ ilé méjì.
- Adìyẹ náà yé ẹyin mẹ́rin.
Nínú àwọn àpẹẹrẹ òkè yìí, iṣẹ́ ẹ̀yán asòǹkà ni "méjì" àti "mẹ́rin" ń ṣe nínú gbólóhùn náà.
Ẹyán awẹ́ gbólóhùn (APAM)
àtúnṣeẸ̀yán awẹ́ gbólóhùn náà ni a tún mọ̀ sí Àpólà Asàmúpé (APAM). Atọ́ka awẹ́ gbólóhùn asàmúpé ni "tí". Dípò ọ̀rọ̀ kan tí ó máa ń ṣiṣẹ́ ẹ̀yán, àpólà ọ̀rọ̀ ni ó máa ń ṣiṣẹ́ ẹ̀yán níbi báyìí. Fún àpẹẹrẹ :
- Ọmọ tí ó dé lánàá ti kú.
- Ọkùnrin tí ó jẹ́ iṣu láàárọ̀ kò yó.
Nínú àwọn àpẹẹrẹ òkè yìí, iṣẹ́ ẹ̀yán awẹ́ gbólóhùn ni "tí ó dé lánàá" àti "tí ó jẹ́ iṣu láàárọ̀" ń ṣe nínú ẹ̀hun tàbí gbólóhùn náà.
Ẹyán aṣàfihàn
àtúnṣeẸ̀yán asàfihàn ni a máa ń lò láti ṣe àfihàn nǹkan yálà nǹkan náà súnmọ́ wa tàbí ó jìnnà sí wa. A máa ń lo "yìí" fún nǹkan tí ó súnmọ́ wa nígbà tí a máa ń lò "yẹn" fún nǹkan tí or jìnnà sí wa. Àwọn atọ́ka ẹ̀yán asàfihàn mìíràn ni : náà àti kan. A máa ń lo kan nígbà tí kò bá sí ìdánilójú nǹkan tí à ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ :
- Ọmọ náà tètè dé.
- Ọkùnrin yìí ni ó kọrin.
- Ọmọdébìnrin kan ni ó ra bàtà yẹn.
Nínú àwọn àpẹẹrẹ òkè yìí, iṣẹ́ ẹ̀yán asàfihàn ni "náà", "yìí", "kan" àti "yẹn" ń ṣe nínú ẹ̀hun tàbí gbólóhùn náà.
Ẹ̀yán atọ́ka Aṣàfihàn
àtúnṣeA máa ń lo ẹ̀yán atọ́ka asàfihàn láti fi tọ́ka sí nǹkan ní pàtó ni. Àwọn atọ́ka ẹ̀yán atọ́ka asàfihàn ni :nìkan, gan-an, pàápàá, pẹ̀lú, kàkà. Bí àpẹẹrẹ :
- Adé nìkan ló wá.
- Èmi gan-an kò jẹun.
Nínú àwọn àpẹẹrẹ òkè yìí, iṣẹ́ ẹ̀yán atọ́ka asàfihàn ni "nìkan" àti "gan-an" ń ṣe nínú gbólóhùn náà.
Tẹ̀léńtẹ̀lé Ẹ̀yán
àtúnṣeÈyí ni pé bí àwọn ẹ̀yán se máa ń jẹyọ tẹ̀lé ara wọn nínú gbólóhùn. Nínú gbogbo gbólóhùn, orí ni ó máa ń síwájú kí gbogbo àwọn tàbí díẹ̀ nínú àwọn ẹ̀yán náà tó tẹ̀lé e. Tẹ̀léńtẹ̀lé ẹ̀yán ni :
Orí + ajórúkọ + asàpèjúwe + asòǹkà + awẹ́ gbólóhùn + asàfihàn + atọ́ka asàfihàn. Bí àpẹẹrẹ :
Ajá Tádé dúdú méjì tí ó kú lánàá náà ti di ṣinṣin.
Bàbá kọ́ ilé pẹ̀tẹ́sì alájà mẹ́wàá pẹ̀lú.