Ẹkún Ìyàwó
Ẹkún Ìyàwó jẹ́ ewì-àbáláyé nílẹ̀ Yorùbá. Ó jẹ́ ẹkún tí omidan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ lọlé ọkọ máa ń sún láti dárò bí ó ṣe fẹ́ filé àwọn òbí rẹ̀ sílẹ̀ lọlé ọkọ àti láti súre fún wọn fún titọ́ ọ dàgbà di àkókò náà. Ẹkún Ìyàwó jẹ́ pàtàkì àṣeyẹ nínú àṣà ìgbéyàwó láwùjọ ọmọ Oòduà.[1]
Ọjọ́ wo ni Ẹkún Ìyàwó máa ń wáyé?
àtúnṣeNílẹ̀ Yorùbá, alẹ́ ìgbéyàwó ku ọ̀la ni ìyàwó tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ lọlé ọkọ máa sun Ẹkùn Ìyàwó
Àwọn olùkópa nínú Ẹkùn Ìyàwó
àtúnṣeÌyàwó tí ó ń lọlé ọkọ, àwọn wọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ ló máa ń kópa níbi ayẹyẹ Ẹkún Ìyàwó. Lóòótọ́, omidan tó ń lọlé ọkọ ni Olú-ẹ̀dá Ẹkún Ìyàwó, àmọ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa ń gbè é lẹ́yìn, wọ́n á máa yẹ́ ẹ sí nígbà tí ó bá ń sun ẹkún yìí. Àwọn òbí rẹ̀ á sì máa rọ̀ ọ́ nígbà tí ó bá ń dárò wọn nínú ẹkún yìí. [2] [3]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Oyěwùmí, Oyèrónkẹ́ (2016). "The Poetry of Weeping Brides: The Role and Impact of Marriage Residence in The Making of Praise Names". What Gender is Motherhood?. New York: Palgrave Macmillan US. pp. 171–192. doi:10.1057/9781137521255_8. ISBN 978-1-349-58051-4.
- ↑ "A Stylistic Analysis of Ekun Iyawo - Second Language - Poetry". Scribd. 2013-07-03. Retrieved 2019-11-15.
- ↑ "̣Ẹkùn ìyàwó = the bride's chant (Book, 2001) [WorldCat.org]". WorldCat.org. 1999-02-22. Retrieved 2019-11-15.