Ẹrú kíkó níṣe pẹ̀lú kí àwọn ológun kó àwọn ènìyàn kúrò ní agbègbè tí wọ́n ń gbé lọ sọ wọ́n di ẹrú ní ilẹ̀ ibòmíràn. Tẹ́lẹ̀, èyí jẹ́ ohun tó tọ́ tàbí tí ó jẹ mọ́ ogun jíjá, ṣùgbọ́n lóde-òní ẹ̀ṣẹ̀ ni ó jẹ́. Láti ìgbà ìwáṣẹ̀ ni ẹrú kíkó ti wà. Ní ilẹ̀ Sumer (tí a mọ̀ sí Iraq lóde-òní) ni àkọsílẹ̀ ẹrú kíkó ti wáyé jù lọ. Ìjénìyàngbé àti àwọn ẹrú láti ara ogun jíjà ni ó ṣokùnfà àwọn ẹrú ilẹ̀ Áfíríkà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣọ̀fà àti Ìjẹniníyà náà wà lára àwọn ohun tí ó bí ẹrú.

Àwọn Amúnisìn Ilẹ̀ Arab Nígbà tí wọ́n ń kó Ìlú Orílẹ̀-èdè Congo kan Lẹ́rù ní 1870s.


Ìmọ̀-ẹ̀rọ àti àwọn àyípadà tó ti ń dé bá àṣà àti ìṣe ti ń mu kí kíkó ẹrú àti ìfènìyàn ṣọfà máa parẹ́.

[1][2]

Àwọn Ìdí

àtúnṣe

Ẹrú kíkó jẹ́ ìlànà ipá láti mú ìdàgbàsókè bá ètò ọrọ̀-ajé, nígbà tí ọ̀wọ́n àwọn ohun-èlò bá wáyé, èyí máa ń fa kí wọ́n fi ipá pèsè iye àwọn ohun-èlò tó pọ̀, ìdí nìyí tí àwọn lílọ àwọn ènìyàn fún iṣẹ́ ṣe bẹ̀rẹ̀. Yàtọ̀ sí pé kíkó ènìyàn lẹ́rú bẹ̀rẹ̀ sí ní wáyé, ìlànà ipá láti ṣẹ̀dá àwọn ohun-èlò wọ̀nyí náà ni wọn ń ṣàmúlò láti pèsè oúnjẹ àti àwọn ohun-èlò mìíràn.

Ẹrú kíkó gbòòrò bẹ́ẹ̀ ó sì tún ń yá ní àwọn etí-òkun ilẹ̀ Áfíríkà, ilẹ̀ Europe ìgbàanì, Mesoamerica, àti ní sẹ́ńtúrì kẹrìnlá ilẹ̀ Asia. Kíkó àwọn ènìyàn lẹ́rú àwọn ará Crimean–Nogai ní agbègbè ìlà-oòrùn Europe pèsè àwọn ẹrú mílíọ̀nù méjì tàbí mẹ́ta fún Ẹkùn Ottoman láàárín sẹ́ńtúrì mẹ́rin. Bákan náà, àwọn ajalèlókun Barbary láti sẹ́ńtúrì kẹrìndínlógún títí kan 1830 kópa nínú kíkó àwọn ènìyàn lẹ́rú ní ilẹ̀ Áfíríkà àti àwọn etí-òkun agbègbè Europe títí kan Iceland, tí wọ́n sì tún kó àwọn ènìyàn lẹ́rú lọ sí ọjà ẹrú àwọn Mùsùlùmí ní agbègbè Àríwá ilẹ̀ Áfíríkà àti Àárín Ìlà-oòrùn. Kíkó àwọn ènìyàn lẹ́rú káàkiri agbami Atlantic jẹ́ èyí tí àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Europe kó èrè rẹ̀ gan-an, tí wọ́n sì ń fọwọ́ si kí ìtẹ̀síwájú láti máa kó àwọn ènìyàn ẹ̀yà Áfíríkà lẹ́rú kí wọ́n le máa ṣiṣẹ́ ní àwọn oko ọ̀gẹ̀dẹ̀ ilẹ̀ America.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "West Africa". National Museums Liverpool. Retrieved 2022-04-25. 
  2. "Capture and Captives | Slavery and Remembrance". slaveryandremembrance.org. Archived from the original on 2022-04-27. Retrieved 2022-04-25.