Ọ̀bàyéjẹ́
Ọ̀bàyéjẹ́ jẹ́ ìtàn àrósọ tí a kọ ní ède yorùba láti ọwọ́ Bunmi Olujinmi ní ọdún 1996. A ṣe atẹ̀jade rẹ̀ pẹ̀lu Vantage Publishers ni ilu Ibadan
Ìtàn ní ṣókí
àtúnṣeItan náà bèrè pèlu Àjàdí àti àwọn ẹbi rẹ̀ ni ìlu Ìlọfẹ. Àjàdí jókòó ó ń ronú ara rẹ̀ nítorípe ẹnu rẹ̀ kò tọ́rọ̀ mọ́ gẹ́gẹ́ bíi báálé ilé. Ìgbà ló yí bíríkítí tí ó sọọ́ di ẹni tí aya rẹ̀ ń bọ́. Àgbẹ̀ aládàá ńlá tí ó gbajúgbajà ni Àjàdí, ó lówó lọ́wọ́, ó sì níyì ní àwùjọ. Sùgbọ́n oko rẹ̀ gbina nítorí ìwà àìbìkíta rẹ̀. Àjàdí wá di ẹni ti aya ńbọ́, ti kò sì le bá àwọn ọmọ rẹ̀ wí mọ́ nínu ilé. Ìyàwó rẹ̀ Àdìká ni ń ṣọkọ nínu ilé, nítorí òwo rè ń tà dáadáa.
Nígbòóṣe, Ajadi rí iṣẹ́ si ilú miìŕàn gẹ́gẹ́ bíi atọ́gbàṣe nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ àna rẹ̀ ; Adégún. ó tipẹlẹ mọ́ iṣẹ́ naa, ó ṣe é tọkàntọkàn. Akitiyan àti ìjólóòtọ́ rẹ̀ yìí ni ó jẹ́ kí àwọn ọ̀ga rẹ̀ fẹ́ran rẹ̀. Kò pẹ́ púpọ̀ ni ó gba ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́ sí ipò ìránṣẹ̀ fún ọ̀ga àgbà ílé-iṣẹ́ náà.
Àìlè-panupọ̀ bá ọmọ wí ni ó sọ àkọ́bí Àjàdi, Ayọ̀bámi di aláìgbọràn. Ọmọ rẹ̀ keji, Akin ni ó sì fẹ́ràn, nítorí ó ń gba ìbáwí. Akín jẹ́ ọmọ olóri pípé ti o tayọ ni ilé ẹ̀kọ́. Àwọn ìgbìmọ̀ ìlu Ìlọfe dá ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ sílẹ̀ láti rán àwọn ọmọ méjì tí ó bá tayọ jùlọ sí ìlu ọ̀kè ọ̀kun. Àjàdí wá di ẹni tí ó rán ọmọ lọ sí òkè-òkun nítorí Akín tayọ nínu ìdánwò náà.
Ni òdìkejì ẹ̀wẹ̀, Ayọ̀bámi di ìdàkudà, ó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ìpáǹle tí ń da ìlú rú, tí ń dènà láti jínigbé.
Ẹ̀dá Ìtàn
àtúnṣe- Àjàdí - olú ìtàn
- Àdìká - Ìyàwo Àjàdí
- Ayọ̀bámi - Àkọ́bi ọmọ Àjàdí ati Àdìká
- Akin - ọmọ Àjàdí ati Àdìká
- Ayégún
- Àwọn Ọ̀mùti