Ọ̀gbàgì
Ìlú Ọ̀gbàgì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìlú pàtàkì tó wà ní agbègbè àríwá Àkókó ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Ìlú yìí wà láàárín Ìkàrẹ́ àti Ìrùn tó jẹ́ ààlà àríwá Àkókó àti Èkìtì. Ìlú Ọ̀gbàgì wà ní ojú ọ̀nà tó wá láti Adó-Èkìtì sí Ìkàrẹ́-Àkókó ó sì jẹ́ kìlómítà mẹ́rìnláá sí ìlú Ìkàrẹ́. Láti Ìkàrẹ́, ìlú Ọ̀gbàgì wà ní apá ìwọ̀ oòrùn tí ó sì jẹ́ pé títì tí a yọ́ ọ̀dà sí ló so ó pọ̀ mọ́ ìlú Ìkàrẹ́ tó jẹ́ ibùjókòó ìjọba ìbílẹ̀ àríwá Àkókó.
Ogbagi | |
---|---|
Ilu | |
Orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Ipinle | Ipinle Ondo |
Ìlú Ọ̀gbàgì kò jìnnà sí àwọn ìlú ńlá mìíràn ní agbègbè rẹ̀. Ní ìlà oòrùn Ọ̀gbàgì, a lè rí ìlú bí i Ìkàrẹ́ àti Arigidi àti ní ìwọ̀ oòrùn ìlú yìí ni ìlú Ìrùn wà ní ọ̀nà tó lọ sí Adó-Èkìtì.
Ọ̀gbàgì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìlú mẹ́fà tí ó tóbi jùlọ ní agbègbè àríwá Àkókó nírorí ìwádìí sọ fún wa pé gẹ́gẹ́ bí ètò ìkànìyàn, ti ọdún `963, àwọn ènìyàn ìlú yìí ju Ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n lọ nígbà náà ṣùgbọ́n èyí yóò tit ó ìlọ́po méjì rẹ̀ lóde òní. Ìlú yìí jẹ́ ìlú ti a tẹ̀dó sí ibi tí ó tẹ́jú ṣùgbọ́n tí òkè yí i po, lára àwọn òkè wọ̀nyí sì ni a ti rí òkè Oròkè tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ojýbọ Òrìṣà Òkè Ọ̀gbàgì. `
Ojú ọ̀nà wọ ìlú yìí láti àwọn ìlú tó yí i pot í ó sì jẹ́ pé èyí mú ìrìnnjò láti Ọ̀gbàgì sí ìlúkílùú ní Ìpinlẹ̀ Oǹdó rọrùn. Àwọn ọ̀nà wọ̀nyí mú un rọrùn láti máa kó àwọn irè oko wọ̀lú láti gbogbo ìgbèríko tó yí ìlú Ọ̀gbàgì ká.
Gẹ́gẹ́ bi ó ti jẹ́ pé oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ni ó wà ní ilẹ̀ Yorùbá láyé àtijọ́ àti lóde òní, bẹ́ẹ̀ náà ni a lè rí i ní ìlú Ọ̀gbàgì níbi tó jẹ́ pé púpọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtijọ́ ni ilẹ̀ Yorùbá ni wọn ń ṣe. Iṣẹ́ àgbẹ̀ tó jẹ́ pàtàkì iṣẹ́ àwọn Yorùbá ló rí àwọn oríṣìíríṣìí iṣẹ́ mìíràn. Iṣẹ́ àwọn ọkùnrin ni ẹmu-dídá tó tún ṣe pàtàkì tẹ̀lé iṣẹ́ àgbẹ̀. Òwò ṣíṣe, oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà tàbí iṣẹ́ ọwọ́ bí i agbọ̀n híhun, irun gígẹ̀, iṣẹ́ alágbẹ̀dẹ, ilé mímọ àti iṣẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà. Iṣẹ́ àwọn obìrin sì ni aṣọ híhun, irun dídì, òwò ṣíṣe àti àwọn oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ìjọba ti ọkùnrin àti obìnrin ń ṣe.
Nípa iṣẹ́ àgbẹ̀ tí wọn ń ṣe, púpọ̀ nínú oúnjẹ wọn ló wá láti ìlú yìí tí ó sì jẹ́ ìwọ̀nba díẹ̀ ni oúnjẹ tí a ń kó wọ̀lú. Iṣẹ́ ẹmu-dídá pàápàá ti fẹ́ ẹ̀ borí iṣẹ́ mìíràn gbogbo nítorí èrè púpọ̀ ni àwọn tó ń dá a ń rí lórí rẹ̀ tí ó sì jẹ́ pé àwọn àgbẹ̀ oníkòkó kò lè fọwọ́ rọ́ àwọn adẹ́mu sẹ́hìn nítorí ẹmu-dídá kò ní àsìkò kan pàtó, yípo ọdún ni wọ́n ń dá a.
Iṣẹ́ ẹmu-dídá yìí ṣe pàtàkì nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi ògùrọ̀ ni a lè rí ní ìlú yìí àti ní gbogbo oko wọn. Àwọn adẹ́mu wọ̀nyí máa ń gbin igi ògùrọ̀ sí àwọn bèbè odò bí àwọn àgbẹ̀ oníkòkó ṣe máa ń gbin kòkó wọn. Èyí ló sì mú kí àwọn tó ń ta ẹmu ní Ìkàrẹ́, Arigidi, Ugbẹ̀, Ìrùn àti Ìkáràm máa wá sí ìlú Ọ̀gbàgì wá ra ẹmu ní ojoojúmọ́.
Bí a ti rí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọna ti iṣẹ́ ń gbé wá sí ìlú Ọ̀gbàgì náà ni a rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Ọ̀gbàgì tí iṣẹ́ ìjọba gbé lọ sí ibòmíràn, nítorí náà ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí ìbá wà láàárín ìlú yìí ni wọ́n wà lẹ́hìn odi. Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tí a lè rí ní àárín ìlú náà ni àwọn olùkọ́ àwọn ọlọ́pàá, ọ̀sìṣẹ́ ilé ìfowópamọ́, òṣìṣẹ́ ilé ìfìwéránṣẹ́ àti àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀.
Idí tí a fir í àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba wọ̀nyí ni àwọn àǹfààní tí ìjọba mú dé ìlú yìí bí i kíkọ́ ilé ìgbẹ̀bí àti ìgboògùn, ilé ìdájọ́ ìbílẹ̀, ilé ìfìwéránṣẹ́, ilé ìfowópamọ́, ọjà kíkọ́, ilé ọlọ́pàá àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé-ẹ̀kọ́ gíga àti ilé-ẹ̀kọ́ kéékèèkéé.
Nípa ti ẹ̀sìn, àwọn oríṣìí ẹ̀sìn mẹ́ta pàtàkì tí a lè rí lóde òní ní ilẹ̀ Yorùbá náà ló wà ní Ọ̀gbàgì. Fún àpẹẹrẹ, a lè rí ẹ̀sìn ìbílẹ̀ àti àwọn ẹ̀sìn ìgbàlódé tó jẹ́ ẹ̀sìn kirisitẹẹni àti ẹ̀sìn mùsùlùmí. Nínú ẹ̀sìn ìbílẹ̀ ni a ti rí oríṣìíríṣìí àwọn òrìṣà tí wọn ń sìn, èyí tí òrìṣà òkè Ọ̀gbàgì jẹ́ ọ̀kan pàtàkì tó wà fún gbogbo ìlú Ọ̀gbàgì. Bí a ti rí àwọn tó jẹ́ pé wọn kò ní ẹ̀sìn méjì ju ẹ̀sìn ìbílẹ̀ ni a rí àwọn mìíràn tó wà nínú àwọn ẹ̀sìn ìgbàlódé wọ̀nyí síbẹ̀ tí wọn tún ń nípa nínú bíbọ àwọn òrìṣà inú ẹ̀sìn ìbílẹ̀. Eléyìí lè jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn ìdílé tàbí àwọn àwòrò òrìṣà tó jẹ́ dandan fún wọn láti jẹ oyè àwòrò bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́sìn mìíràn ni wọ́n nítorí ìdílé wọn ló ń jẹ oyè náà. Ẹ̀sìn ìbílẹ̀ kò jẹ́ alátakò fún ẹ̀sìnkẹsìn ni wọ̀ngbà tí ẹ̀sìn náà bá lé mú ire bá àwọn olùsìn.
Àpèjúwe mi yìí kò ní kún tó tí mo bá fẹnu ba gbogbo nǹkan láìsọ ẹ̀yà èdè tí ìlú Ọ̀gbàgì ń sọ. Ní agbègbè Àkókó, oríṣìíríṣìí èdè àdùgbò tó jẹ́ ara ẹ̀yà èdè Yorùbá ni a lè rí, nítorí ìdí èyí, ó ṣe é ṣe kí ọmọ ìlú kan máà gbọ́ èdè ìlú kejì tí kò ju kìlómítà méjì sí ara wọn. Nítorí náà, ó dàbí ẹni pé iye ìlú tí a lẹ̀ rí ní agbègbè àríwá Àkókó tàbí ní Àkókó ní àpapọ̀ ní iye ẹ̀yà èdè tí a lè rí. Ṣùgbọ́n a rí àwọn ìlú díẹ̀ tí wọn gbọ́ èdè ara wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyàtọ̀ wà díẹ̀díẹ̀ nínú wọn. Ó ṣe é ṣe kí irú ìyàtọ̀-sára èdè yìí ṣẹlẹ̀ nípa oríṣìíríṣìí ogun abẹ́lé tí ó ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá láyé àtijọ́ nítorí èyí mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti oríṣìíríṣìí ẹ̀yà tẹ̀dó sí agbègbè yìí tí ó sì fa sísọ oníruurú èdè tó yàtọ̀ sí ara wọn nítorí agbègbè yìí jẹ́ ààlà láàárín Ìpínlẹ̀ Oǹdó, Kwara àti Bendel lóde òní.
Nítorí ìdí èyí, èdè Ọ̀gbàgì jẹ́ àdàpọ̀ èdè Èkìtì àti ti Àkókó ṣùgbọ́n èdè Èkìtì ló fara mọ́ jùlọ nítorí ìwọ̀nba ni àwọn ìyàtọ̀ tó wà nínú èdè Ọ̀gbàgì àti ti Èkìtì gẹ́gẹ́ bí ó ti hàn nínú àwọn orin àti ewì tí mo gbà sílẹ̀. Fún ìdí èyí, kò ní ṣòro rárá fún ẹni tó wá láti Èkìtì láti gbọ́ èdè Ọ̀gbàgì tàbí láti sọ èdè Ọ̀gbàgì ṣùgbọ́n ìṣòro ni fún ẹni tó wá láti ìlú mìíràn ní Àkókó láti gbọ́ èdè Ọ̀gbàgì tàbí láti sọ ọ́ yàtọ̀ sí àwọn ìlú díẹ̀ ní àkókó tí wọn tún ń sọ ẹ̀yà èdè Èkìtì bẹ́ẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ọmọ ìlú Ìrùn, Àfìn, Eṣé àti Ìrọ̀ ti wọn wà ní agbègbè kan náà pẹ̀lú Ọ̀gbàgì lè sọ tàbí gbọ́ èdè Ọ̀gbàgì pẹ̀lú ìrọ̀rùn.
Bí ó ti wù kí ìṣòro gbígbọ́ èdè yìí pọ̀ tó, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun fún àǹfààní tí mo ní láti ṣiṣẹ́ láàárín àwọn ará ìlú yìí fún ọdún márùn ún tí ó mú kí ń lè gbọ́ díẹ̀ nínú èdè Ọ̀gbàgì bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lè sọ ọ́ ṣùgbọ́n mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Olóyè Odù tó jẹ́ olùtọ́nisọ́nà àti olùrànlọ́wọ́ mi tó jẹ́ ọmọ Ọ̀gbàgì tó sì gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Yorùbá láti ṣe àlàyé lórí àwọn nǹkan tó ta kókó èyí tí ó sì mú kí iṣẹ́ ìwádìí yìí rọrùn láti ṣe.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Ẹ lè ka siwájú si
àtúnṣe- L.A. Adúlójú (1981), ‘Ìlú Ògbàgì’, láti inú ‘Ọdún Òrìṣà Òkè Ògbàgì ní Ìlú Ọ̀gbàgì Àkókó’, Àpilẹ̀kọ fún Oyè Bíeè, Dall OUA, Ife, Ojú-ìwé 1-5.