Nínú ìmọ̀ sáyẹ́nsì nípa ilẹ̀, Ọ̀gbàrá jẹ́ wíwọ́ omi àrọ̀dá òjò tí ṣẹ̀ṣẹ̀ rọ̀ tán tí ó sì nń wọ́ yanrìn tàbí iyẹ̀pẹ̀ orí ilẹ̀ lọ bí òun náà ṣe ń wọ́ ruru láti ibìkan sí òmíràn.[1] Àkíyèsí: Ọ̀gbàrá yàtọ̀ sí fífọ́n òjò (kí a má ṣìí gbé síra wọn, torí fífọ́n òjò kìí ṣàngbàrá). Ṣíṣàn ọ̀gbàrá tún jẹ́ ìṣe àdámọ́ ítí láé láé, àwọn ohun tí ó sì ń fa àkóyawọ́ rẹ̀ ni ìṣesí àwùjọ bíi omi, yìnyín, ìdarí afẹ́fẹ́ tàbí atẹ́gùn, àwọn igi, àwọn ẹranko àti ìwà òun ìṣesí àwọn ọmọ ènìyàn.

Omíyalé ọ̀gbàrá yàgboro ni agbègbè Lafenwa-Itele, Ogun State

Ìpínsísọ̀rí ọ̀gbàrá

àtúnṣe

Látarí àwọn ìṣesí tí a ti mẹ́nu bà lókè yí ni ó ń fà ìpínsísọ̀rí ọ̀gbará sí :

  1. Ọ̀gbàrá omi,
  2. Ọ̀gbàrá atẹ́gùn,
  3. Ọ̀gbàrá yìnyín lásán,
  4. Ọ̀gbàrá yìnyín tó dodò (glacial),
  5. Ọ̀gbàrá zoogenic, àti
  6. Ọ̀gbàrá anthropogenic.[2]

[3][4][5] Lóòtọ́ ni wípé ọ̀gbàrá jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ àdámọ́ ilẹ̀, àmọ́ ìhùwàsí àti ìṣesí ọmọnìyàn náà ń dá kún bí ọ̀gbàrá ṣe ń b nkan jẹ́ ní ìdá 10-40% lágbàáyé.[6] Bí àpẹẹrẹ, oko tí wọn fi ń ṣe nkan ọ̀gbìn ti ó wà ní Appalachian Mountains, ti di ojú odo ọ̀gbará látàrí àkọtúnkọ ikẹ̀ oko náà ti mú kí wíwọ́ ruru ọ̀gbarà lágbègbè yí pẹ̀lú eré tí ó tó ọgọ́rùn ún (100×), tí ó sì ti mú kí ilẹ̀ oko naa jin kòtò gìrìwò.[7]

Àwọn ìpalára tí ọ̀gbàrá ń mú dání

àtúnṣe

Wíwọ́ ruru ọ̀gbàrá láwọ̀ọ́jù lórí iẹ̀ ti mú ìjanbá tó lágbára bá àwọn ilẹ̀, yálà ilẹ̀ ilé tàbí ilẹ̀ oko. Lára àwọn ìpalára yí ni mímú àdínkù bá ohun ọ̀gbìn àti irè oko,

  • Jíjìn ilẹ̀ látọwọ́ ọ̀gbàrá ńlá,
  • Bíba àwọn èròjà àti ọ̀rá inú ilẹ̀ jẹ́ náà kò gbẹ́yìn. Lọ́pọ̀ ìgbà, ilẹ̀ tí ọ̀gbará bá ti bàjẹ́ ma ń di kíkọ̀sílẹ̀ nítorí ìbẹ̀rù omiyalé.[8]:2[9]:1

Dídá oko lójú kan ládàá-jù (intensive farming) àti ìgégi lulẹ̀ lábaadì (deforestration), kíkọ́ ojú ọ̀nà àti àwọn ìṣesí ọmọnìyàn míìràn tó lààmì-laaka lórí ilẹ̀ náà ma ń ṣokùnfà bí ọ̀gbàrá ṣe ń ṣọṣẹ́ káàkiri àgbáyé.[10] Àmóṣá, oríṣríṣi ọ̀na ni àwọn ènìyàn ń gba lágbáyé láti mú adínkù bá ọṣẹ́ ọ̀gbará tàbí láti dẹ́kun rẹ̀ pátá pátá.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Erosion". Encyclopædia Britannica. 2015-12-03. Archived from the original on 2015-12-21. Retrieved 2015-12-06.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. Apollo, M., Andreychouk, V., Bhattarai, S.S. (2018-03-24). "Short-Term Impacts of Livestock Grazing on Vegetation and Track Formation in a High Mountain Environment: A Case Study from the Himalayan Miyar Valley (India)". Sustainability 10 (4): 951. doi:10.3390/su10040951. ISSN 2071-1050. 
  3. Cheraghi, M.; Jomaa, S.; Sander, G.C.; Barry, D.A. (2016). "Hysteretic sediment fluxes in rainfall-driven soil erosion: Particle size effects". Water Resour. Res.. doi:10.1002/2016WR019314. https://infoscience.epfl.ch/record/222767/files/Cheraghi%20ET%20AL.%202016WR019314_MANS.pdf. 
  4. Hallet, Bernard (1981). "Glacial Abrasion and Sliding: Their Dependence on the Debris Concentration In Basal Ice". Annals of Glaciology 2 (1): 23–28. Bibcode 1981AnGla...2...23H. doi:10.3189/172756481794352487. ISSN 0260-3055. https://www.researchgate.net/publication/233496971. 
  5. Sklar, Leonard S.; Dietrich, William E. (2004). "A mechanistic model for river incision into bedrock by saltating bed load". Water Resources Research 40 (6): W06301. Bibcode 2004WRR....40.6301S. doi:10.1029/2003WR002496. ISSN 0043-1397. Archived from the original on 2016-10-11. https://web.archive.org/web/20161011172333/http://eps.berkeley.edu/~bill/papers/sklaranddietrich20042003WR002496_121.pdf. Retrieved 2016-06-18. 
  6. Dotterweich, Markus (2013-11-01). "The history of human-induced soil erosion: Geomorphic legacies, early descriptions and research, and the development of soil conservation – A global synopsis". Geomorphology 201: 1–34. Bibcode 2013Geomo.201....1D. doi:10.1016/j.geomorph.2013.07.021. 
  7. Reusser, L.; Bierman, P.; Rood, D. (2015). "Quantifying human impacts on rates of erosion and sediment transport at a landscape scale". Geology 43 (2): 171–174. Bibcode 2015Geo....43..171R. doi:10.1130/g36272.1. 
  8. Blanco-Canqui, Humberto; Rattan, Lal (2008). "Soil and water conservation". Principles of soil conservation and management. Dordrecht: Springer. pp. 1–20. ISBN 978-1-4020-8709-7. 
  9. Toy, Terrence J.; Foster, George R.; Renard, Kenneth G. (2002). Soil erosion : processes, prediction, measurement, and control. New York: Wiley. ISBN 978-0-471-38369-7. 
  10. Julien, Pierre Y. (2010). Erosion and Sedimentation. Cambridge University Press. p. 1. ISBN 978-0-521-53737-7. https://books.google.com/books?id=Gv72uiVmWEYC&pg=PA1.