Ọ̀rọ̀:Samuel Adeleye Adenle

Latest comment: 24 Oṣù Bélú 2024 by Agbalagba in topic Ohun tí ẹ lè ṣe

Àkíyèsí pàtàkì

àtúnṣe

Mo kí yín níbẹ̀un @Royalesignature, ẹ kú iṣẹ́ takun takun. Mo ṣàkíyèsí wípé ẹ ń gbìyànjú láti ṣe akọọ́lẹ̀ àwọn orúkọ Yorùbá àti ìtumọ̀ won sí orí Wíkì yí, èyí dára púpọ̀. Àmọ́, mo fẹ́ pè yín sí àkíyèsí pàtàkì kan wípé kí ẹ tún àwọn àyọkà orúkọ tuntun tí ẹ dá sílẹ̀ láìpẹ́ yí ṣe nítorí wọn kò bójú mu. Ẹ jẹ́ kí n mẹ́nu ba díẹ̀ lára ìṣòro tí àwọn àyọkà náà ní:

Àwọn ìṣọ̀ro tí mo rí

àtúnṣe
  • Àgbékalẹ̀ púpọ̀ nínú àwọn àyọkà náà kò bá ìlànà àkọtọ́ èdè Yorùbá mu.
  • Àwọn àyọkà náà kò ní ìtọ́kasí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀. Mo sì tún ri wípé àyọkà Wikipedia èdè Gẹ̀ẹ́sì ni ẹ fi ń ṣe ìtọ́kasí (èyí lòdì sí ìlànà òfin ìtọ́kasí Wikipedia).
  • Àwọn àyọkà náà ti kúrú jù láti jẹ́ ojú-ìwé tó lè dá dúró fúnra wọn lórí Wikipedia (Stub articles).

Ohun tí ẹ lè ṣe

àtúnṣe
  1. Ẹ tún àwọn àyọkà náà kọ pẹ̀lú èdè Yorùbá gidi (pẹ̀lu kí ẹ kàwọ́n dára dára kí ẹ sì fi Yorùbá ọkàn àti ẹnu yín gbe kalẹ̀ ní kíkọ.
  2. Ẹ lo ìtọ́kasí bí: ISBN ìwé tí ẹ ń lò láti fi kọ àyọkà náà sí orí Wíkì yí, tàbí kí ẹ wo orí ẹ̀rọ ayélujára fún ìrànlọ́wọ́.
  3. Ẹ gbíyànjú láti ṣe àfikún àti àkọkún gbogbo àyọkà náà nítorí wọ́n ti kúrú jù, èyí kò sì bá ìlànà ohun tí a ń pè ní encylopeadia mu.
Return to "Samuel Adeleye Adenle" page.