Iṣẹ́ Àgbẹ̀

(Àtúnjúwe láti Ọ̀rọ̀ Àgbẹ̀)


Iṣẹ́ àgbẹ̀ jẹ́ iṣẹ́ kan tí a ń ṣe láti fi gbin ohun ọ̀gbìn tàbí irè oko tàbí sísìn ohun ọ̀sìn láti fi bọ́ ènìyàn àti ẹranko.[1]

Yorùbá gbágbọ̀ pé, iṣẹ́ àgbẹ̀ jẹ́ iṣẹ́ ilẹ̀ wa, ṣùgbọ́n ju èyí lọ, iṣẹ́ àgbé ti wà láti ìgbà tí ayé ti wà. Bí a bá sì ń sọ nípa ọ̀rọ̀ àgbẹ̀, kìí ṣe iṣẹ́ oko nìkan là ń sọ. Iṣẹ́ àgbẹ̀ pín sí oríṣirísi ọ̀nà bíi: àgbẹ̀ aroko bọ́dúndé, àgbẹ̀ ọlọ́sìn, àgbẹ̀ ẹlẹ́ja, àgbẹ̀ Olóyin, àgbẹ̀ oní-fúláwà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Kò sì sí ọ̀kan nínú ìsọ̀rí iṣẹ́ àgbẹ̀ yí tí kò ní èrè tàbí àǹfààní fún Olórí-kò-jorí, fún àwùjọ, fún àwọn ilé-iṣẹ́ àti fún orílẹ̀-èdè lápapọ̀. Kí a kúkú sọ pé, láìsí iṣẹ́ àgbẹ̀, kò lé sí ènìyàn nítorí pé oúnjẹ ni ọ̀rẹ́ àwọ̀. Ilẹ̀ Yorùbá ló dára jù lọ l'afrika.

Àwọn ọ̀nà tí a ń gbà ṣiṣẹ́ àgbẹ̀

àtúnṣe

Ní ayé àtijọ́ àwọn àgbẹ̀ aláròojẹ nìkan ni ó wà, ṣùgbọ́n láyé òde òní iṣẹ́ àgbẹ̀ ti gbounjẹ fẹ́gbẹ́ ó sì ti gbàwò bọ̀. Lónìí ati rí àgbẹ̀ aládà-ńlá, alápapò se, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ[2]

Pàtàkì àti ìwúlò iṣẹ́ àgbẹ̀

àtúnṣe

Ní ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú àti ní àgbáyé lápapọ̀, ára àwọn pàtàkì iṣẹ́ àgbẹ̀ ni pé, nípa iṣẹ́ àgbẹ̀ ni ati máa ń mú oúnjẹ jade fún gbogbo ènìyàn àti fún àwọn ẹranko pẹ̀lú. Yorúbà a máa pòwe pe: bí óunjẹ bá ti kúrò nínú ìṣẹ́, ìṣẹ́ bùṣe. Láìsí óunjẹ yoo ṣòro fún ènìyàn lati máa gbé ní àlàáfíà, nítorí pé okun tinú la fi ń gbé tìta. Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni ń mú oúnjẹ wá; óunjẹ ní sì ń mú ìlera wá, ara-líle sì ni ogùn ọrọ̀. Ó túnmọ̀ sí pé, láìsí iṣẹ́ àgbẹ̀ tó jẹ́ orísun ìpèsè fún ohun àmúlò ilé-iṣẹ́ ńlá àti kékeré, láìsí àwọn ohun àmúlò wọ̀nyí kò le ṣe é ṣe fún ilé iṣẹ́ lati máa ṣiṣẹ́. Bí kò bá sí ilé iṣẹ́, kò ní sí iṣẹ́ fún àwọn ènìyàn lati se. Èyí tí ó tún túmọ̀ sí pé, iṣẹ́ àgbẹ̀ jẹ́ ọ̀nà sí ìpèsè iṣẹ́ fún àwọn ènìyàn. Nínú àbájádèe àwọn aláyẹ̀wò nípa iṣẹ́ àgbẹ̀, wọ́n sọ pé, ó tó ìpín bi ọgọ́ọ̀rin ènìyàn tí wọ́n n ṣiṣẹ ni ọ̀nà kan tàbí òmíran nípa iṣẹ́ àgbẹ̀. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú àwọn ànfàní tí ó kóra jọpọ̀ sínú iṣẹ̀ àgbẹ̀ yí, àwọn ènìyàn sì kóòríra iṣẹ́ àgbẹ̀ síbẹ̀.[3]

Kí ni ìdí tí àwọn ènìyàn fi yan iṣẹ́ àgbẹ̀ ní pọ̀sìn

àtúnṣe

Lára àwọn ìdí ti àwọn ènìyàn fi ní ikóòrírà si iṣẹ́ àgbẹ̀ nipé, ó jẹ́ iṣẹ́ tí o nira láti se. Láì fi igbá bọ̀ kan nínú rárá, iṣẹ́ àgbẹ̀ jẹ́ iṣẹ́ tí ó nira, ìdí nìyí tí àwọn ènìyàn fi ń sá fún iṣẹ́ yi nítorí pé kò sẹ́ni tí ó fẹ́ ṣiṣẹ́ tó nira rárá, a fi iṣẹ́ ìrọ̀rùn nìkan, bí iṣẹ́ ófíìsì. Àwọn ohun èlò tí wọ́n ń lò, bíi àdá àti ọkọ́ tún ń ba àwọn ènìyàn lẹ́rù lati fi ṣiṣẹ́ àgbẹ̀. Ṣúgbọ̀n nígbà tí ọ̀làjú dé, ni àwọn onímọ̀ ìjinlẹ̀ ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ohun èlò amáyédẹrùn fún iṣẹ́ àgbẹ̀. Èyí ló wá mú kí iṣẹ́ àgbẹ̀ wá wu ọ̀pọ̀lọpọ̀ lati ṣẹ, nítorí pé kò wá sí àṣekú ni iṣẹ́ àgbẹ̀ nítorí ìrànlọ́wọ̀ kẹ́míkà tí a fi ń pa oko àti àwọn ohun èlò ìgbàlódè míràn bí èyí tí wọ́n fi ń kọko, èyí tí wọ́n fi ń kórè àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Pẹ̀lú ìdàgbàsókè tí ó ti bá iṣẹ́ àgbẹ̀ ni àwùjọ wa lónìí yìí, ó yẹ kí ẹni kọ̀ọ̀kan wa mú iṣẹ́ àgbẹ̀ yi lọ́kùnkúndún-ùn nítorí nípa iṣẹ́ àgbẹ̀ ni óunjẹ fi lè pọ̀ yanturu ni àwùjọ wa. Kìí ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ ọ̀ná láti tán òṣì àti ìṣẹ́ nípa pípèsè iṣẹ́ fún àwọn tí kò rí iṣẹ́, yó sì tún mú ìdàgbàsókè ba ọrọ̀ ajẹ́ wa ni orílẹ̀-èdè wa, Nàíjíríà àti àgáyé lápapọ̀.

Àwọn Itọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Definition of AGRICULTURE". Definition of Agriculture by Merriam-Webster. 2021-02-21. Retrieved 2021-03-09. 
  2. "Farming Types: 12 Major Types of Farming". Your Article Library. 2016-03-09. Retrieved 2021-03-09. 
  3. "The Importance of Agriculture [15 Reasons]". IMPOFF. 2019-02-14. Archived from the original on 2021-02-27. Retrieved 2021-03-09.