Ọ̀ra Ìgbómínà

Agbègbè Ìlá-Ọ̀ràngún ni Ọ̀ra-Ìgbómìnà wà. Ìlú Ọ̀ra-Ìgbómìnà ló dúró bí afárá tí a lè gùn kọjá sí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ípínlẹ̀ Ondó, àti ìpínlẹ́ Kwara. Ìkóríta ìpínlẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni Ọ̀ra-ìgbómìnà wà, ṣùgbọ́n ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní wọ́ ṣírò rẹ̀ mọ́. Kilómítà mẹ́tàlá ni Ọ̀ra-Ìgbómìnà sí Ìlá-Ọ̀ràngún tó wá ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Kílómítà mẹ́ta péré ni Ọ̀ra sí Àránọ̀rin tó wà ní ìpínlẹ́ Kwara, ó sì jẹ́ Kìlómítà kan péré sí Ọ̀sàn Èkìtì tó wà ní ìpínlẹ̀ Oǹdó.

Ilé-Ifẹ̀ ni àwọm Ọ̀ra ti wá ní òórọ̀ ọjọ́. Ìtàn àtẹnudẹ́nu fi yẹ́ ni pé kì í ṣe Ọ̀ra àkọ́kọ́ ni wọ́n wà báyìí. Ní ǹkan bí ọ̀rìnlé-lẹ́ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún sẹ́hìn ni wọ́n tẹ ibi tí wọ́n wà báyìí dó. Ọra-Ìgbómìnà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìlú tí ogun dààmú-púpọ̀ ní ayé àtijọ́. Nínú àwọn ogun tí ìtàn sọ fún ni pọ́ dààmú Ọ̀ra ni – ogun Ìyápọ̀ (ìyàápọ̀), ogun Jálumi, Èkìtì Parapọ̀, àti ògun Ògbórí-ẹfọ̀n. Ní àkókò náà, àwọn akọni pọ́ ní Ọ̀ra lábẹ́ àkóso Akẹsin ọba wọn. Àwọn ògbógi olórí ogun nígbà náà ni ‘Eésinkin Ajagunmọ́rùkú àti Eníkọ̀tún Lámọdi ti Òkè-Ópó àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ológun mìíràn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló fí ìbẹ̀rù-bójo sá kúrò ní ìlú ní àkókò ogun. Nígbà tí ogun rọlẹ̀, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ nínú àwọn to ti ságun ló pádá wá sí Ọ̀ra ṣùgbọ́n àwọn mìíràn kò padà mọ́ títí di òní olónìí. Àwọn Òkèèwù tó jẹ́ aládùúgbò Ọra náà ṣí kúrò ní Kèságbé ìlú wọn, wọ́n sì wá sí Ọ̀ra. Nínú àwọn tí kò pádà sí Ọ̀ra mọ́, a rí àwọ́n tọ́ wá ní Rorẹ́, Òmù-àrán, Ìlọfà àti Ibàdàn. Àwọn ìran wọn wà níbẹ́ títí dì òní olónìí. Ní àkókò tí mo ń kọ ìwé yìí, ìlú méjì ló papọ̀ tí a ń pè ní Ọ̀ra-Ìgbómìnà - Ọ̀ra àti Òkèèwù, ìlú ọlọ́ba sin i méjèèjì.

B. ÌṢẸ̀DÁ ÌLÚ Ọ̀RA-ÌGBÓMÌNÀ

Nítorí pẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtàn ìṣẹ̀dá àwọn ìlú Yorùbá jẹ́ àtẹnudẹ́nu, ó máa ń sòro láti sọ ní pàtó pé báyìí-báyìí ni ìlú kan ṣe ṣẹ̀. Nígbà míràn a lè gbọ́ tọ́ bí ìtàn méjì, mẹ́ta, tàbí ju bẹ́ẹ̀ lọ nípa bí ìlú kan ṣe ṣẹ́. Báyìí gan-an nit i ìṣẹ̀dá ìlú Ọ̀ra-Ìgbómìnà rí. Ohun tí a gbọ́ ni a kọ sílẹ̀ ní éréfẹ̀ẹ́ nítorí kì í kúkú ṣe orí ìtàn ìlú Ọ̀ra-Ìgbómìnà gan-an ni mo ń kọ ìwé lé, ṣùgbọ́n bí òǹkàwé bá mọ díẹ̀ nínú ìtàn tó jẹ mọ́ ìṣẹ̀dá ìlú Ọ̀ra-Ìgbómìnà, yóò lè gbádùn gbogbo ohún tí a bá sọ nípa Ọdún Òrìṣà Ẹlẹ́fọ̀n ní Ọ̀ra-Ìgbómìnà tí mo ń kọ Ìwé nípa rẹ̀.

Ìtàn kan sọ pé àwọn ènìyàn ìlú Ọ̀ra Ìgbómìnà kì í ṣe ọ̀kan náà láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ wá. Irú wá, ògìrì wá ni ọ̀rọ̀ ìlú Ọ̀ra. Àwọn ọmọ alápà wá láti Ilé-Ifẹ̀. Àwọn Ìjásíọ̀ wá látio Ifọ́n. Awọn Òkè-Òpó àti Okè kanga wá láti Ọ̀yọ́ Ilé, àwọn mìíràn sí wá láti Ẹpẹ̀ àti ilẹ̀ Tápà. Kò sí ẹni tó lè sọ pé àwọn ilé báyìí-báyìí ló kọ́kọ́ dé ṣùgbọ́n gbogbo àwọn agbolé náà parapọ̀ sábẹ́ àkóso Akẹsìn tó jẹ́ ọmọ Alápà-merì láti Ilé Ọ̀rámifẹ̀ ní Ilé-Ifẹ̀. Orúkọ ibi tí àwọn ọmọ Alápà ti ṣí wá sí Ọ̀ra-Ìgbómìnà náà ni wọ́n fi sọ ìlú Ọ̀ra títí di Òní-Ọ̀ra Oríjà ni wọ́n ti ṣí wá, wọ́n sì sọ íbi tí wọn dó sí ní Ọ̀ra. (Èdè Ìgbómìnà tí wọ́n ń sọ ni wọ́n ṣe ń pe ìlú wọn ní Ọra-Ìgbómìnà).

Àkókò ogun jíjà ni àkókò náà, gbogbo wọn sì máa ń pa ra pọ̀ jagún ni Àwọn-jagunjagun pọ̀ nínú wọn. Jagúnjagun gan-an sì ni Akẹsin tó jẹ́ olórí wọn. Àwọn méjì nínú àwọn olórí ogun wọn ni Eésinkin Ajagun-má-rùkú àti Eníkọ̀tún tí wọ́n pe àpèjà rẹ̀ ní Lámọdi. Eésinkin Ajagun-má-rùkú ló wa yàrà yí gbogbo ìlú Ọ̀ra po. Eníkọ̀tún Lámọdi ló lé ogun Èkìtì-Parapọ̀ títí dé òdò kan tí wọn ń pè ní Àrìgbárá. Àwọn tí ọwọ rẹ̀ sì tẹ̀, wọ́n mọ wọ́n mọ́ odi láàyè ni ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń ki àwọn ọmọ Òkè-Òpó ní oríkì-

“Ọmọ Eníkọ̀tún ṣàbi

Ọmọ Lámọdi

Ọmọ Àyánwọ́nyanwọ̀n

- ọkùnrin

Ọmọ Àràpo ni ti

ìbẹ̀tẹ́

Ọ́mọ́ Álẹ́kàn d’Arìghárá

Ọmọ Alégun dé Sanmọr

Baba yín ló pè èjì

Ẹ̀kàn Lọ́jọ́ Ọjọ́ra Kọ́la.”

Lẹ́hìn ogun ìyápọ̀ àti ogun ògbórí-ẹfọ̀n, àwọn aládùúgbò wọn kan tó ti wà ní Kèságbé lábẹ́ àkóso ọba wọn Aṣáọ̀ni bá Akẹsìn sọ ọ́ kí ó lè fún òun nílẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ (Akẹsìn) kí wọn lè jọ máa parapọ̀ jagun bí ogun bá tún dé. Akẹsìn bá àwọn ìjòyè rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n sì gbà. Wọ́n fún Aṣáọ̀ni àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ilẹ̀ ní Ọ̀ra. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn náà tí lọ, obìnrin kan tó ṣe àtakò pé kí wọn má fún àwọn ọmọ Aṣáọ̀ni tí wọ́n ń pe ní Òkèèwù láàyè, wọ́n dá a dọ̀ọ̀bálẹ̀ wọ́n sì tẹ́ ẹ́ pa lẹ́ẹ̀kẹsẹ̀. Báyìí ni ọba ṣe di méjì ní ìlú Ọ̀ra-Ìgbómìnà. Ṣùgbọ́n wọ́n jọ ní àdéhùn, wọ́n sì gbà pé Akẹsìn ló nilẹ̀. Ìyáàfin Bojúwoyè (Òkè-Òpó) ẹni àádọ́rin ọdún àti ìyáàgba Dégbénlé (Ìjásíọ̀) ẹni àádọ́rùnún ọdún ó lé mẹ́fà tí wọ́n sọ itàn yìí fún mi kò ta ko ara wọn rárá, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe àkókò kan náà ni mo ṣe ìwádìí ìtàn lẹ́nu àwọn méjèèjì. Àwọn méjèèjì ló wà láyé ní àkókò tí mo ń kọ ìwé yìí. Ìran Lámọdi ọmọ Òpómúléró tó wá láti ilé Alápínni ní Ọ̀yọ́ ilé ni ìyáàfin Bojúwoye ìran Enífọ́n sì ni ìyáàgbà Dégbénlé. Àwọn méjèèjì ló wà láyé ní àkókò tí mo ń kọ ìwé yìí.

Ìtàn kejì tí mo gbà sílẹ̀ lẹnu ìyá àgbà Adégbénlé (Iyá-Ìlá) ti ìjásíọ̀ sọ fún wa pé ìlú méjì ló parapọ̀ di Ọ̀ra bí a ti mọ̀ ọ́n lónìí. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn náà ti lọ, ìlú Ọ̀ra ti wà tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ kí ogun ‘iyápọ̀’ ati ogun ‘Èkìtìparapọ̀’ tó dé. Ìlú kan sí wà létí Ọ̀ra tó ń jẹ́ Òkèwù. Àwọn ìlú méjèèjì yí pààlà ni. Igi ìrókò méjì ló dúró bí ààlà ìlú méjèèjì. Igi ìrokò kan ń bẹ ní ìgberí Ọ̀ra, ìyẹn ni wọ́n ń pè ní ìrókò Agóló, ọ̀kan sì ń bẹ ní ìgberí Òkẹ̀wù, ìyẹn ni wọn ń pè ní irókò Mọ́jápa (Èmi pàápàá gbọ́njú mọ igi ìrókò mejèèjì; ìrókò mọ́jápa nìkan ni wọ́n ti gé ní àkókò tí mo ń kọ̀wé yìí; ìrókò Agólò sì wà níbẹ̀) Nítorí àwọn igi ìrókò méjèèjì tó1 Ọ́ra àti òkèwù láàárín yìí, àwọn òkèwù tí ìlú tiwọn ń jẹ́ Kò-sá-gbé’ máa ń ki ara wọn ní oríkì-orílẹ̀ báyìí:

“Ọmọ ìrókò kan tẹ́ẹ́rẹ́ tí ń bẹ nígbèrí Ọ̀ra

Ọmọ ìrókò kan gàǹgà tí ń bẹ nígberí Òkèwù

Wọn è ẹ́ jóhun ún ṣè ‘ọn Ọ̀ra

Wọn è ẹ́ jóhun ún ṣe ‘ọn Òkèwù

Wọn è ẹ́ jóhun ún ṣe ‘ọn Àtẹ́-ńlẹ́-ọdẹ́

Ọmọ Ọ́dẹ́-mojì, ma a sin’mọ gágá relé ọkọ

Àpè-joògùn má bì l’Okèwù”.


Ìtàn kẹta jẹ́ èyí tí baba mí gan-an sọ fún mi kí títán tó dé sí i ní dún 1966. Ẹni ọgọ́fa ọdún ni baba mi Olóyè Fabiyi Àyàndá Òpó, mọjàlekan, Aláànì Akẹsìn, nígbà tó tẹ́rí gbaṣọ. Bába mi fi yé mi pé àwọn ojúlé tí wa ní Ọ̀ra nígbà òun gbọ́njú ni Ìperin, Ìjásíọ̀, Òkè-Òpọ́, Òkèágbalá, ilé atè, Odò àbàtà, Òkè-akànangi, Okèkàngá, Òkèọ́jà, odìda, odòò mìjá, Òkèwugbó, Ilé Ásánlú, ilé Akòoyi, ilé sansanran, odònóíṣà ilé ọba-jòkò, ilé Eésinkin-Ọ̀ra ilé ìyá Ọ̀ra, ilẹ́ ọ̀dogun, ilé ọ̀gbara, ilé Olúpo, kereèjà, àti ilé Jégbádò . Gbogbo àwọn ojúlé wọ̀nyí ló wà lábẹ́ àkóso ọba Akẹsìn ṣùgbọ́n àwọn ìwàrẹ̀fà àti àwọn Ẹtalà2 ló ń pàṣẹ ìlú. Ìdí nìyẹn tí wọn ṣe máa ń we pé –

“Péú lAkẹ́sìn ń wỌ̀ra”.

Akẹsìn kàn jẹ́ ọba Ọ̀ra ni ohun tí àwọn ògbóni tó wà nínú ìgbìmọ̀ - Ìwàrẹ̀fa àti Ẹ̀tàlá bá fi ọ́wọ́ sí ni òun náà yóò fi ọwọ́ sí. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn náà ti lọ, àwọn ojúlé wọ̀nyí ni àwọn tí kò parun bí ogun ti dààmú ìlú Ọ̀ra tó. Baba mi tún sọ síwájú sí i pé Òrùlé tó ń bẹ ní Ọ̀ra nígba tí òun gbonjú kò ju ọgbọ̀n lọ, àti pé ṣe ni wọn fa àgbàlá láti Òkè-Òpó dé Òkèkàngá. Bí eégún bá sì jáde ní Òkèòpó, títí yóò fi dé Òkèkàngá ẹnì kan kan lè má rí i bí kò bá fẹ́ kí ènìyàn rí òun. Baba mi wá ṣàlayé pé Aláfà baba ti òun pa á nítàn pé àwọn Okèwù tọrọ ilẹ̀ lọ́wọ́ Ọ̀ra, Ọ̀ra sì fún wọn láàyè lórí ìlẹ̀ àwọn ìjásíọ̀ àti Òkè Akànangi. Nígbà tí ibi tí a fún wọ́n kò gba wọ́n, wọ́n tọrọ ilẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹbí Aláfa ní Òkè-Òpó.

Nígbà tí awọ́n Òkèwú wá jòkó pẹ̀sẹ̀ tán, àwọn ọmọ íyá wọn tó wà ní Òró àti Agbọnda wá ṣí bá wọ́n. Oníṣòwò ni àwọn tó wá láti Òró wọ̀nyí. Iṣu ànamọ́ li wọn máa ń rù wá sí Ọ̀ra fún tità. Ọ̀nà Àránọ̀rin ni wọ́n máa ń gbà wọ ìlú. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn náà ti lọ, obìnrin kan tí ara rẹ̀ kò dá máa ń jòkó ní abẹ́ igi kan ní ẹ̀bá ọ̀nà. Ibi tí igi náà wà nígbà náà ni a ń pè ní Arárọ̀mí lónìí. Baba mi so pàtó pé òun mọ obìnrin tí a ń wí yìí àti pé Àdidì ni wọ́n ń pè é. Ìgbà-kìgbà tí àwọn oníṣòwò wọ̀nyí bá ti ń ru iṣu ànàmọ́ ti Ọ̀ró bọ̀, tí wọn bá sì ti dé ọ̀dọ̀ Àdìdì, wọn a sọ ẹrù wọn kalẹ̀, wọn sì sinmi tẹ́rùn. Kí wọn tó kúrò ní ọ̀dọ̀ Àdìdì, wọn á ju iṣu ànàmọ́ kọ̀ọ̀kan sílẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀. Báyìí ni àwọn Òkèwù bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i ní Ọ̀ra-Ìgbómínà. Nígbà tó yá, Arójọ̀yójè tó jẹ Aṣáọ̀ni (Ọba ti àwọn okèwú) nígbà náà tọrọ ilẹ̀ díẹ̀ sí i lọ́wọ́ Aláfà òkè-òkó (baba mi àgbà) Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ sí ọ̀rẹ́, Aláfà fún un ní ilẹ̀ nítorí àwọn Òke-òpó ní ilẹ̀ ilé púpọ̀. Ilẹ̀ oko nikan ni wọn kò ní ní ọ̀nà.

Ní ibi tí Aláfà yọ̀ọ̀da fún Arójòjoyè yìí, akọ-iṣu àtí tábà ni àwọn Òkè-òpó ti máa ń gbìn síbẹ̀ rí. Ibẹ̀ náà ni olọ́ọ̀gbẹ́ Ìgè kọ́ ilẹ́ rẹ̀ sí. Ilẹ́ náà wà níbẹ̀ ní àkókò tí mo ń kọ ìwé yìí. Bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Òkèwù tó rí ààyè kólé sí ṣe ń ránṣẹ́ sí àwọn ọmọ ìyá wọn tó wà ní ẹkùn Òrò àti Agbọndà nìyẹn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn ló tún wá láti Èsìẹ́, Ílúdùn, Ìpetu (Kwara), Rorẹ́ àti Òmu-àrán.

Báyìí, àwọn ìtàn mìíràn tí àwọn baba ńlá wa kò pa rí ti ń dìde. Nígba tí ọ̀rọ̀ adé gbé ìjà sílẹ̀ ní Ọ̀ra-Ìgbómìnà láìpẹ́ yìí, ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ gbé ìgbìmọ̀ kan dìde láti wádìí ìtàn Ọ̀ra. Àbájáde ìwádìí ìgbìmọ̀ náa wà nínú ìwé ìkéde Gómìná ìpinlẹ̀ Ọ̀yọ́, Olóyè Bọ́lá Ìge tí ní orí ẹrọ asọ̀rọ mágbesí nínú oṣu kẹwàá ọdún 1980 a tún gbọ́ nínú ìkẹ́de yẹn ni pé Òkèwù ló tẹ ìlú Ọ̀ra-Ìgbómìnà dó àti pé àwọn ló sọ orúkọ ìlú náà ní Ọ̀ra (A ó ra tán) Ohun tó da àwa lójú ni pẹ́ ìlú méjì ló papọ̀ tí wọn so Ọ̀ra-Ìgbómìnà ró báyìí. Ìlú ọba Aládé sì ni ìlú méjèèjì Ọ̀ra àti Òkèwù.

D. ÀWỌN ÈNÌYÀN ÌLÚ Ọ̀RA, IṢẸ́ OÚNJẸ ÀTI ÈDÈ WỌN

Ẹ̀yà Yorùbá kan náà ni gbogbo àwọn ènìyàn ìlú Ọ̀ra-Ìgbómìnà àti Òkèwù. Ṣùgbọ́n kì í ṣe ọ̀kan náà ni wọ́n ní òórọ̀ ọjọ́ bí a ti sọ ṣáájú. Àwọn ará Ọ̀yọ́ wà ní Ọ̀ra, àwọn árá Ilé-Ifẹ̀ sì wà ní Ọ̀ra pẹ̀lú. Àwọn kan tán sí Èkìtì, àwọn mìíràn si tan sí ìpínlẹ̀ Kwárà. Àwọn tó ti ilẹ̀ Tápà wá ń bẹ ní Ọ̀ra, àwọn tó ti Kàbbà wá sì ń bẹ níbẹ̀ báyìí- àwọn ni ọmọ, Olújùmú. Àwọn Hausá pàápàá wà ní ìlú Ọ̀ra báyìí, ṣùgbọ́n èdè Ìgbómìnà ni èdè tí ó gbégbá oróke láàrin wọn.

Iṣẹ́ àgbẹ̀ aroko-jẹun ni iṣẹ Ọ̀ra láti ilẹ̀ wà. Wọ́n ń gbin iṣu, àgbado, àti ẹ̀gẹ́. Àwọn ohun ọ̀gbìn tí wọ́n fi ń ṣowó ni tábà ọ̀pẹ, áko, erèé òwú, obì àbàtà àti ìgbá tí wọ́n fi ń ṣe ìyere fún irú tí wọ́n fi ń ṣe ọbẹ̀.


  • J.A. A. Fabiyi (1981), ‘Ọ̀ra-Ìgbómìnà’, láti inú ‘Ọdún Òrìṣà Ẹlẹ́fọ̀n ní ‘Òra-Ìgbómìnà.’, Àpilẹ̀kọ fún Oyè Bíeè, DALL, OAU, Ifẹ̀, Nigeria, ojú-ìwé 2-9