Ọdún Egúngún

jẹ́ ọdún tí àwọn Yorùbá ma ń ṣe nígba tí àwọn ará ọ̀run bá wá sáyé

Ayẹyẹ ọdún Egúngún jẹ́ ayẹyẹ àjọyọ̀ ilẹ̀ Yorùbá, bákan náà ni ó jẹ́ ohun àṣà àdáyé bá àtìran-díran àqọn Yorùbá. Wọ́n nígbàgbọ́ wípé ọdún yí ma ń mú ìdàgbàsókè, ìrẹ́pọ̀, ìfẹ́ àti ìrú gọ́gọ́ ètò ọrọ̀ ajé si ní àwùjọ. Gbogo ilẹ̀ Yorùbá ni wọ́n si ma ń ṣayẹyẹ ọdún Egúngún, láì fi tẹ̀sìn òun ẹ̀yà kan kan ṣe. [1][2][3]Egúngún jẹ́ awo àṣírí láàrín àwọn Ọ̀jẹ̀ (Masqurade custodians), ní ilẹ̀ Yorùbá. Ó sì jẹ́ ohun àjogúnbá ní ìdílé Ọlọ́jẹ̀. Ṣíṣọdún Egúngún jẹ́ ohun pàtàkì lásìkò rẹ̀, iyì ibẹ̀ ni ijọó, ìlú, àti ìwúre nígbà tí àwọn ọmọ Ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́ yóò kó pàṣán lọ́wọ́ láti fi kó patiẹ lẹ̀yín èyí kéyìí Egúngún tí wọ́n bá tẹ̀lé. [4][5]

Eégún Onídán nílú Ọ̀tà

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "International art festival of photography in Nigeria". LagosPhoto. 2019-11-15. Retrieved 2019-11-19. 
  2. "Egungun Festival". TheFreeDictionary.com. Retrieved 2019-11-19. 
  3. Chinasa, Hannah (2017-03-08). "7 facts about Egungun festival in Yorubaland". Legit.ng - Nigeria news. Retrieved 2019-11-19. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  4. "Ogun State Government Official Website". Ogun State Government Official Website. 2017-05-04. Archived from the original on 2019-11-02. Retrieved 2019-11-19. 
  5. "Colour, culture and community of Nigerian festival". BBC News. 2017-08-23. Retrieved 2019-11-19.