Ọdún Papa Nantwi
Ọdún Papa Nantwi jẹ́ ọdún ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún tí àwọn ènìyàn Kumawu máa ń ṣe àjọ̀dún rẹ̀ ní ẹkùn ìlà-oòrùn Sekyere ní Ashanti Region ti Ghana, nínú oṣù kẹta ní ọdọọdún. [1] Ó jẹ́ ọdún ìbílẹ̀ láti fi ṣe ìrántí gbogbo Ashantis bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayẹyẹ náà máa ń wáyé ní Kumawu. Ọdún náà máa di lílò láti fi bu ọlá kún ìgboyà àti ẹ̀mí ìfiaraẹnisrúbọ ti àwọn babańlá wọn, Nana Tweneboa Kodua (I) ẹni tí ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ sílẹ̀ láti fi rúbọ láti ṣe ìrànwọ́ fún àwọn Ashantis láti lè borí Denkyiras, àwọn tí ó jẹ́ adarí wọn.
Ìtàn ìsẹ̀dálẹ̀
àtúnṣeỌdún náà máa di ṣíṣe láti sàmì ìṣẹ̀lẹ̀ ìtàn tí ó ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé àwọn Ashanti Kingdom ní àkókò Otumfuo Osei Tutu I.[2] Ìṣe àtẹnudẹ́nu láàárín àwọn ènìyàn Kumawu ní pé àwọn Denkyiras, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn Ashantis, ń fi ìyà jẹ wọ́n, fífi ipá gba ilẹ̀, oko, ìyàwó àti àwọn ohun ìní mìíràn. Fún ìdí èyí, ọba àkọ́kọ́ ti Ashanti, Otumfuo Osei Tutu I se ìgbìyànjú ńlá láti so àwọn ìran Akan méjèèje papọ̀ láti jà fún òmìnira wọn kúrò lọ́wọ́ àwọn Denkyiras. Lẹ́yìn bíbi àwọn ònilẹ̀ àti àwọn babańlá Akan léèrè láti ọwọ́ ògbóni ìgbà náà àti olùbádámọ̀ràn fún Otumfuo Osei Tutu I, Okomfo Anokye, Ó di fífi hàn pé àwọn Ashantis lè jáwé olúborí lórí àwọn Denkyiras lẹ́yìn tí ọ̀kan nínú àwọn olóyè bá fi ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ètùtù. Láti bí ìfarajìn àti ìgboyà, Nana Tweneboa Kodua I tìka alára rẹ̀ dìde ó sì sọ fún ọba Ashanti pé òun setán láti kú láti ṣe ìrànwọ́ fún ààfin Ashanti tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ láti lè gba òmìnira kúrò lọ́wọ́ àwọn Denkyiras.[3]
Lẹ́yìn ìfirúbọ Nana Tweneboa Kodua I, àwọn ọmọ ogun Ashanti jáwé olúborí lé àwọn Denkyiras, gẹ́gẹ́ bí ó ti di sísọ àsọtẹ́lẹ̀ láti ọwọ́ Okomfo Anokye. Ikú rẹ̀, tí wọ́n kà sí okun fún gbígba òmìnira ìlú Ashanti lọ́wọ́ àwọn Denkyiras, ni ó gún ọba Ashanti, Otumfuo Osei Tutu I ní kẹ́sẹ́ láti pa àṣẹ ìyẹn ní ọdọọdún,ọdún gbọ́dọ̀ di ṣíṣe àjọyọ̀ láti ṣe ìrántí iṣẹ́ ńlá ti Nana Tweneboa Kodua I.[4] Ní pàtàkì jù lọ, ọdún náà máa ń di lílò láti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ènìyàn àwùjọ ìdí tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe fi ìnífẹ̀ẹ́ ìlú, ìgboyà àti ẹ̀mí àìníkànjọpọ́n hàn tí ó nílò fún ìlọsíwájú àwùjọ Ghanaian.[4]
Ìwòye
àtúnṣeNíbi ọdún náà, eré ńlá máa ń di ṣíṣe lórí àpótí dúdú tí wọ́n gbàgbọ́ pé ó dúró fún ẹ̀mí gbogbo ọba Ashanti tí ó ti wàjà tí ó wà ní Nkonyafie. Àti pé, ètùtù máa ń di ṣíṣe ní ààyè kan pàtó ní aginjù mímọ́ Bomfobiri àti omi níbi tí wọ́n gbàgbọ́ pé àwọn babańlá Kumawu wà.[5] Àwọn ètùtù yìí máa ń di ṣíṣe láti fi tó àwọn babańlá létí ọdún láti fi bu iyì àti ní pàtàkì jù lọ láti bèèrè fún ìtọ́sọ́nà wọn, ìrànlọ́wọ́, àti wíwá wọn fún ìwòye àṣeyọrí ọdún. Lẹ́yìn ìpẹ̀tù àti àwọn ètùtù sí àwọn babańlá ti di ṣíṣe, ìdíje ìgboyà máa wáyé ní ààfin olóyè tàbí ààyèkáàyè tí ọdún náà bá ti wáyé. Màálù ńlá máa ń di pípa. Òkú màálù náà máa ń di gbígbé sí gbangba níbi tí ọdún náà ti ń wáyé láàárín ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ àwọn olùgbé Kumawu, àwọn ènìyàn láti agbègbè ìlú Ashanti àti abúlé àti àwọn àlejò pẹ̀lú. Ojú ọ̀nà kan máa di ṣíṣe tí ó já sí ibi tí màlúù tí wọ́n pa wà níbí tí àwọn akọni ènìyàn máa gbà láti gé èkìrí kan lára ẹran náà tí wọn yóò sì sáré pẹ̀lú rẹ̀ lọ sí ààyè kan láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ lílù láti ọwọ́ àwọn èrò tí wọ́n mú ẹgba dání. Tí ènìyàn bá lè gé èkìrí kan lára màálù náà tí ó sì mú un de ààyè náà pẹ̀lú gbogbo lílù náà, wọ́n máa sọ pé ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ́ akíkanjú àti onígboyà. Ó máa mú ẹran màálù tí ó gé náà yóò sì di fífún lẹ́bùn láti ọwọ́ olóyè Kumawu.[6]
Àwọn ìdíje mìíràn gẹ́gẹ́ bí ìdíje oúnjẹ, ijó, àti ìdíje orin, ìdíje ẹwà àti ilẹ̀ títúnse àti igi gbíngbìn máa ń di ṣíṣe ní àkókò ọdún náà. [7]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "tiaskipin.tk". tiaskipin.tk. Retrieved 2019-06-13.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "biodiversity and sustainable development". moe.gov.lr. Retrieved 2019-06-13.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs namedauto2
- ↑ 4.0 4.1 Adom, Dickson (2018). "Traditional cosmology and nature conservation at the Bomfobiri Wildlife Sanctuary of Ghana". Nature Conservation Research 3 (1). doi:10.24189/ncr.2018.005. ISSN 2500-008X.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs namedauto12
- ↑ "Kokofu festival of books". quest2ans.review. Retrieved 2019-06-13.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ Adom, Dickson (2018-06-18). "Traditional Biodiversity Conservation Strategy As A Complement to the Existing Scientific Biodiversity Conservation Models in Ghana". Environment and Natural Resources Research 8 (3): 1. doi:10.5539/enrr.v8n3p1. ISSN 1927-0496.