Ọdún isu Ashanti
Ọdún Iṣu Ashanti jẹ́ àjọ̀dún ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ti àwọn ènìyàn ti Ashanti. Ó máa ń sàmì sí ìkórè isu àkọ́kọ́ ní àkókò autumn season, lẹ́yìn àkókò monsoon. Isu náà ni ohun ọ̀gbìn tí wọ́n máa ń gbìn jù ní Ashanti àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú ní Africa.
Ashanti Yam Festival | |
---|---|
Ashanti yam ceremony, Asanteman. A painting of a yam ceremony from 1817. | |
Observed by | Ashantis of Asanteman |
Type | Ashanti festival |
Significance | Festival of Purification |
Date | Between September and December |
Celebrations | To celebrate Yam Harvest |
Ìwòye
àtúnṣeỌdún náà, ìsinmi orílẹ̀-èdè, máa ń di ṣíṣe fún ọjọ́ márùn-ún tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ Ìsẹ́gun, gẹ́gẹ́ bí olúwo ti pa á láṣẹ. Ó máa ń dúró ìkórè isu àkọ́kọ́ ní àkókò autumnal, ní àìpẹ́ sí àkókò monsoon. Ọdún náà ní pàtàkì ẹ̀sìn àti ọ̀rọ̀ ajé.[1] Ní tẹ̀sìn, ọdún náà máa ń di lílò láti dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ònilẹ̀ àti àwọn babańlá fún ìkórè tuntun àti láti fi isu tuntun náà ṣe ìtọrẹ ní ti ìbílẹ̀.
Ìse
àtúnṣeÌrúbọ àkọ́kọ́ ohun ọ̀gbìn náà máa ń di ṣíṣe sí àwọn ònilẹ̀ láti ọwọ́ olúwo Ashanti; àwọn ètò ìrúbọ náà ni gbígbé isu ní ọjọ́ kejì ọdún náà lọ sí ikẹ̀ àwọn ònilẹ̀. Orin àti ijó jẹ́ ara ọdún ní gbogbo ọjọ́ márààrún.[1][2] Ọdún náà tún gbajúmọ̀ nítorí pé ọba ní ó máa ṣàkóso ìṣeré ayẹyẹ ablution nípa nínu gbogbo àga àwọn babańlá Stools (àga). Ìṣe mìíràn ní àkókò ọdún yìí ni yíyọ ohun ọ̀sọ́ góòlù, iṣẹ́ ọ̀nà ìgbà ìwáṣẹ̀, àti pẹ̀lú àṣẹ ìjọba, láti sọ wọ́n di ohun ọ̀sọ́ tuntun. Ní àkókò ọdún yìí, ọba kò fi ààyè gba fífi ènìyàn rúbọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìlù ikú kò di fífi ààyè gba láti di lílù gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé ayẹyẹ tí ó mọ́ ni.[2]
Ètùtù
àtúnṣeSíwájú kí àjọ̀dún ọdún náà ó tó bẹ̀rẹ̀, ọba máa ṣàkóso ìhun Dampan èyí tí ó di nínàró fún ìgbà díẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ ìlú.[2] Ní ọjọ́ àkọ́kọ́ ọdún náà, ojú ọ̀nà sí itẹ́ òkú àwọn olóyè Ashantis máa ń di gbígbá mọ́. Ní ọjọ́ kejì, àwọn olúwo á gbé isu náà ní ọ̀nà àwọ̀ fún ìrúbọ sí àwọn babańlá tí wọ́n sin sí itẹ́ òkú. Lẹ́yìn tí ìrúbọ yìí bá parí nìkan ni àwọn ènìyàn di gbígbà láàyè láti jẹ iṣu tuntun náà. Ọjọ́ kẹta máa ń di ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìdárò fún àwọn babańlá àti láti gba àwẹ̀. Ní ọjọ́ kẹrin, olóyè máa ṣe oúnjẹ alẹ́ fún gbogbo ènìyàn ní ilé rẹ̀. Ní alẹ́ ọjọ́ kẹrin, àwọn ènìyàn máa wà ní inú ilé láti má ba à lè fojú rí fífọ ìtẹ́ olóyè, àmì ẹ̀mí àwọn ènìyàn tí ó ti kú, ní odò Draa River ní Kumasi. Ní ọjọ́ karùn-ún, ìwọ́de ńlá ti olóyè àti àwọn ẹbí rẹ̀, àti àwọn òṣìṣẹ́ ní ààfin, tí gbogbo wọn yóò múra dáadáa, tí wọn yóò sì bọ́ sí ojú ọ̀nà láti lọ bọ̀wọ̀ fún olóyè ìbílẹ̀ àgbà ní ibùgbé rẹ̀. Níbi ìwọ́de náà, àwọn ènìyàn kan á di gbígbé nínú ọkọ̀ agbééyàn palanquins tí wọ́n ṣe lọ́jọ̀ tí wọ́n fi agbòòrùnlà ṣe ibòji fún.[1]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 1.2 Macdonald 2000, p. 207.
- ↑ 2.0 2.1 2.2 "Asante History, Culture, Religion, Economy, Judicial Process, Human Sacrifice: Ama, A Story of the Atlantic Slave Trade". 8. The King and the Yam Festival Celebration. Ama.Africatoday.com. Retrieved 25 November 2012.