Ọdẹ ni orúkọ tí a ń pe àwọn àkàndá ènìyàn kan tí wọ́n yan iṣẹ́ pípa ẹranko ìgbẹ́ ,dídẹ Odò, pípa ẹyẹ oríṣiríṣi lọ́pọ̀ ìgbà.

Ọdẹ ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́

àtúnṣe

Ní àwùjọ Yorùbá láyé àtijọ́, Ọdẹ ṣiṣẹ́ jẹ́ iṣẹ́ abiyì láàrín tí ọ̀pọ̀ àwọn Òbí ma ń fẹ́ kí àwọn ọmọ wọn ó kọ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ àti iṣẹ́ òòjọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ Yorùbá, wípé iṣẹ́ ni oògùn ìṣẹ́, wọ́n ma ń pọọ́n ní dandan fún ara wọn láti ní iṣẹ́ lọ́wọ́. Ọdẹ ṣíṣe tún jẹ́ iṣẹ́ ìdílé àwọn ẹbí kan tí wọ́n si ma ń jẹ́ orúkọ tí ó jọ mọ́ iṣẹ́ yí. Wọn a máa jẹ́ Ọdẹ́jìnmí,Ọdẹ́wálé, Ọdẹ́gbèmí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹ̀wẹ̀, àwọn Ọdẹ náà tún ma ń ṣọ́de òru léte àti dáàbò bo ìlú, ẹ̀mí, àti dúkìá pátá. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ògbójú Ọdẹ ni wọ́n ma ń lọ sójú ogun láti dábò bo ìlú wọn.[1][2]

Ọ̀nà tí iṣẹ́ Ọdẹ pin sí

àtúnṣe

Lára àwọn ọ̀nà tí iṣẹ́ Ọdẹ pin sí ni:

  • Ọdẹ Apẹran. Àwọn irúfẹ́ Ọdẹ tí ó wà ní ọ̀wọ́ yí ni wọ́n ma ń dẹ̀gbẹ́, dẹ tàkúté láti pẹran wẹ́wẹ́ àti ẹran abìjàwàrà nínú igbó tàbí aginjù yálà fún títà tàbí jíjẹ.
    • Ọdẹ Adẹdò. Irúfẹ́ àwọn wọ̀yí ni wọ́n ma ń ṣíṣe dẹdò, dẹ̀gèrè sórí alagba-lúgbú omi láti pa ẹja oríṣiríṣi yálà fún títà tàbí tàbí fún jíjẹ nínú Ilé.[3]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe

[4]

  1. Utilisateur, Super (2018-03-02). "Present Day Hunter’s Festival in Yorubaland and Their Music". IFRA Nigeria. Archived from the original on 2019-12-15. Retrieved 2019-12-15. 
  2. Temidayo, Mustapha (2017-01-17). "Spiritual, moral lives of hunters". The Nation Newspaper. Retrieved 2019-12-15. 
  3. "ÒGBÓJÚ ỌDẸ - THE GREAT HUNTER". YO'BA MO'ODUA: ÒGBÓJÚ ỌDẸ (in Èdè Latini). 2013-01-10. Retrieved 2019-12-15. 
  4. "Spiritual, moral lives of hunters". The Nation Newspaper (in Èdè Latini). 2017-01-17. Retrieved 2019-12-15.