Ọgbẹ́-inú buruli

(Àtúnjúwe láti Ọgbẹ́-inú Bairnsdale)

Ọgbẹ́-inú Buruli (tí a tún mọ̀ sí Ọgbẹ́-inú Bairnsdale, Ọgbẹ́-inú Searls, tàbí Ọgbẹ́-inú Daintree[1][2][3]) jẹ́ àrùn àkóràn èyítí ó má a nwáyé nípasẹ̀ Mycobacterium ulcerans.[4] Ipele àkọ́kọ́ àkóràn àrùn náà ni a lè dámọ̀ nípasẹ̀ kókó tàbí ibití ó wú lára ẹni.[4] Kókó yìí lè yípadà sí ọgbẹ́-inú.[4] Ọgbẹ́-inú náà lè tóbi nínú ju lórí awọ ara lọ,[5] àyíká rẹ̀ sí lè wú.[5] Bí àrùn náà ti nle síwájú síi, ó lè ran egungun.[4] Ọgbẹ́-inú Buruli a má a sábà mú ni lọ́wọ́ tàbí lẹ́sẹ̀;[4] ibà kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀.[4]

Ọgbẹ́-inú buruli
Ọgbẹ́-inú buruliỌgbẹ-inú Buruli lọ́rùn ẹsẹ̀ ènìyàn kan láti Ghana.
Ọgbẹ́-inú buruliỌgbẹ-inú Buruli lọ́rùn ẹsẹ̀ ènìyàn kan láti Ghana.
Ọgbẹ-inú Buruli lọ́rùn ẹsẹ̀ ènìyàn kan láti Ghana.
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta
ICD/CIM-10A31.1 (ILDS A31.120) A31.1 (ILDS A31.120)
ICD/CIM-9031.1 031.1
DiseasesDB8568

Òkùnfà

àtúnṣe

M. ulcerans a má a pọ oró tí a mọ̀ sí mycolactonejáde, èyí tí ó má a ndín ìlànà iṣẹ́ àtako àrùn kù, tó sì má a nfa ikú.[4] Àwọn kòkòrò àrùn àìlèfojúrí tí ó jẹ́ ẹbí kan náà a má a fa ikọ́ àwúgbẹ àti ẹ̀tẹ̀ (M. tuberculosis àti M. leprae,lọ́kọ̀ọ̀kan).[4] A kò mọ̀ bí àrùn náà ti ntàn káàkiri.[4] Orísun omi lè níí ṣe pẹ̀lú títànkáàkiri.[5] Títí di ọdún 2013 kò sí àjẹsára kankan tó nṣiṣẹ́.[4][6]

Ìtọ́jú

àtúnṣe

Bí a bá tọ́jú ènìyàn lásìkò, àwọn egbògi agbógun ti àkóràn fún ọ̀sẹ̀ mẹ́jọ a má a ní ipa lórí ìwọ̀n ọgọ́rin nínú ọgọrun (80%) ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn náà.[4] Ìtọ́jú a má a wáyé nípasẹ̀ lílo àwọn egbògi bíi rifampicin àti streptomycin.[4] A tún má a nlo Clarithromycin tàbí moxifloxacin dípò streptomycin.[4] Àwọn ìtọ́jú mìíràn tún lè jẹ́ gígé kúrò ọgbẹ́-inú náà.[4][7] Lẹ́yìn tí egbò àkóràn náà bá ti jinà, ojú ibẹ̀ a má a ní àpá.[6]

Àtànká àti Ìṣàkóso àtànká àrùn

àtúnṣe

Ọgbẹ́-inú Buruli a má a sábà wáyé ní ìgbèríko Gúsù Sahara Afirika pàápàá júlọ Cote d'Ivoire, ṣùgbọ́n ó tún lè wáyé ní Eṣia, ìwọ̀-oòrùn pasifiki àti ní àwọn Amẹrika.[4] Ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn náà ti wáyé ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ju 32 lọ.[5] Iye ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn náà tó tó ẹgbẹ̀rún marun sí mẹ́fà ló má a nwáyé lọ́dọọdún.[4] Àrùn náà a tún má a wáyé lára àwọn ẹranko melo kan yàtọ̀ sí lára ọmọ ènìyàn.[4] Albert Ruskin Cook ni ẹni àkọ́kọ́ tó ṣe àpèjúwe ọgbẹ́-inú buruli ní ọdún 1897.[5]

References

àtúnṣe
  1. James, William D.; Berger, Timothy G.; et al. (2006). Andrews' Diseases of the Skin: clinical Dermatology. Saunders Elsevier. pp. 340. ISBN 0-7216-2921-0. 
  2. Rapini, Ronald P.; Bolognia, Jean L.; Jorizzo, Joseph L. (2007). Dermatology: 2-Volume Set. St. Louis: Mosby. Chapter 74. ISBN 1-4160-2999-0. 
  3. Lavender CJ, Senanayake SN, Fyfe JA, et al. (January 2007). "First case of Mycobacterium ulcerans disease (Bairnsdale or Buruli ulcer) acquired in New South Wales". Med. J. Aust. 186 (2): 62–3. PMID 17223764. http://www.mja.com.au/public/issues/186_02_150107/lav10784_fm.html. 
  4. 4.00 4.01 4.02 4.03 4.04 4.05 4.06 4.07 4.08 4.09 4.10 4.11 4.12 4.13 4.14 4.15 4.16 "Buruli ulcer (Mycobacterium ulcerans infection) Fact sheet N°199". World Health Organization. June 2013. Retrieved 23 February 2014. 
  5. 5.0 5.1 5.2 5.3 5.4 Nakanaga, K; Yotsu, RR; Hoshino, Y; Suzuki, K; Makino, M; Ishii, N (2013). "Buruli ulcer and mycolactone-producing mycobacteria.". Japanese journal of infectious diseases 66 (2): 83–8. PMID 23514902. 
  6. 6.0 6.1 Einarsdottir T, Huygen K (November 2011). "Buruli ulcer". Hum Vaccin 7 (11): 1198–203. doi:10.4161/hv.7.11.17751. PMID 22048117. http://www.landesbioscience.com/journals/hv/abstract.php?id=17751. 
  7. Sizaire V, Nackers F, Comte E, Portaels F (2006). "Mycobacterium ulcerans infection: control, diagnosis, and treatment". Lancet Infect Dis 6 (5): 288–296. doi:10.1016/S1473-3099(06)70464-9. PMID 16631549. http://linkinghub.elsevier.com/retrieve/pii/S1473-3099(06)70464-9.