Ọjà Kurmi jẹ́ ọjà tí ó tóbi tí ó wà ní ìlú KanoIpinle Kano, orile-èdè Nàìjíríà. Muhammad Rumfa, ẹnití ó jẹ́ Ọba Kano, ni ó dá ọjà yí sílẹ́ ní ọ̀rúndún kẹẹ̀dógún. Ọjà yí ṣì tún wà ní lílò ní ọ̀rúndún kọkánlélógún. Títí di ọdún 2003, Sale Ayagi ní ó jẹ́ alága ẹgbẹ́ àwọn ọlọ́já.

Sandalwood àti àwọn ohun èlò tùràrí ní Ọjà Kurmi.

Orúkọ ẹgbẹ́ àwọn agbá bọ̀ọ̀lù kan ni wọ́n fi ńpe ọjà yí.[1]

Ìtàn nípa Kurmi àtúnṣe

Ọjà Kurmi ni wọ́n ṣe ìdásílẹ̀ rẹ ní ọ̀rúndún kẹẹ̀dógún gégé bíi ibi ìṣòwò àti ilé ìfipamọ́ fún ìdàgbàsókè àwọn iṣẹ́ ìṣòwò ní ìlú, eléyìí ni ó jẹ́ àbájáde ọjà agbègbè àti ti Trans-Saharan tí wọ́n sì ń gbòòrò si. Láàrín agbègbè Jankara ti ìlú náà ni wọ́n kọ́ ọjà yí sí. Ní àkókò tí ọjà yí ń dàgbàsókè, ìlú Kano ti di ibi ọjà agbègbè fún àwọn ǹkan ọ̀gbìn pẹ̀lu ilé-iṣẹ́ tí wọ́n ti ńṣe àwọn iṣẹ́ bíi iṣẹ́ aṣọ híhun, aṣọ rírẹ, awọ ṣíṣe àti ìkòkò mímọ. Eléyìí ni ó fàá tí ìlú náà ṣe ńfà sí àwọn arìnrìn-àjò oníṣòwò láti ìwọ̀-oòrùn Sudan, Tripoli àti Ghadames tí wọ́n ń wá láti ra àwọn ọjà.Ṣáájú àkókò ìjọba amínisìn, wọ́n ṣètò kíkọ́ ọjà yí ní onígun mẹ́rin pẹlú àwọn ọparun tí wọ́n tò sí orí ìlà bíi òpópónà láàrin ọjà tí àwọn agbègbè kan sí wà gẹ́gẹ́ bí ibi tí wọ́n ti ńta àwọn ọjà kan tí wọ́n yàsọ́tọ̀ tí ìsọ̀ ẹran-ọ̀sìn sí wa ní àwọn apákan ìwọ̀-òòrù ní ìgboro ọjà náà. Àwọn ènìyàn tí wọ́n ǹ ṣe àbójútó àwọn agbègbè kan ní pàtó tàbí àwọn ẹ̀ẹ̀ka ọjà kan ní wọn ńṣe ìṣàkóso ọjà yìí. [2]

Àkókò ìjọba amúnisìn àti lẹ̀yìn àkókò ìjọba amúnisìn àtúnṣe

Ní ọdún 1904, wọ́n wó ọjà àtijọ́ palẹ wọ́n sì kọ́ titun láti lè mú ìlọsíwájú bá owó tí wọ́n ńpa wọlé fún àwọn aláṣẹ ìlú kano. Wọ́n ṣí ọjà tuntun yi ní ọdún 1909. Àwọn ìsọ̀ tí ó tó 755 tí wọ́n fi amó ṣe ni wọ́n wà nínú Ọjà yí. Ọjà yí tún ní mọ́ṣáláṣí kan àti ilé-ẹjọ́ kan. Ní àwọn ọdún kan sẹ́yìn, àlékún bá àwọn ìlọsíwájú tí ó fi jẹ́ wípé àwọn òpópónà ń gbòòrò si tí díẹ̀ nínú àwọn tí ń ta ẹran ni wọ́n sọ fún pé kí wọ́n lọ ibòmíràn. Agbègbè ọjà náà, ní pàtàkì agbègbè Jakara tún jẹ̀rí ìdàgbàsókè tí ó gbòòrò síi. Síbẹ̀síbẹ̀, ìlànà kárà-kátà yípadà kúrò ní àwọn agbègbè ìgboro ìlú ní apá àríwá àti kárà-kátà ní Trans-Saharan láti ṣe òwò pẹ̀lú àwọn agbègbè tí ó wà ní Gusu àti àwọn ará ìlú Yírópù.

Ní ọdún 1969, ìṣàkóso ọjà yí bọ́ sí ọwọ́ ìjọba Ìbílẹ̀ Kano. Láti ìgbà náà ni ìjọba Ìbílẹ̀ yí ti mú ìwúrí ba àwọn ọjà pàtàkì láàrin ìlú bíi Yan Kaba fún àwọn ẹ̀fọ́ àti ọjà Kanrin Kwari fún àwọn aṣọ, díẹ̀ nínú àwọn oníṣòwò yí tún kólọ sí àwọn agbègbè tuntun ti ìdàgbàsókè tí ń wáyé ni ìgboro ilu bíi Fagge àti ọjà Sabon Gari. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ọjà yí ti sọ díẹ̀ nù nínú àwọn ìṣesí rẹ gégé bíi ibi kárà-kátà fún àwọn ọjà agbègbè tí ó fi jẹ́ wípé àwọn ànfàní oníbàárà àdúgbò ni ó ń mójú tó.

Àwọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. Ogbuagu, Henry (2006-11-26). "All Stars host Kurmi Market today". Daily Triumph (Triumph Publishing Company). http://www.triumphnewspapers.com/archive/ST26112006/all26112006.htm. 
  2. Naniya 2001, p. 92-96.