Ọmọlúàbí
Ọmọlúàbí jẹ́ gbólóhùn tí ó fi ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àṣà àti ìṣe àwọn baba ńlá baba Yorùbá hàn nípa ọgbọ́n inú àti inọ̀ ikùn láti fi ṣàpèjúwe iwa rere tí ó tọ́ kí ènìyàn ó ma hù láwùjọ. Ẹ̀wẹ̀, gbólóhùn yí fi iwa akin, ìjáramọ́ṣẹ́ , ìwà ìrẹ̀ ìrẹ̀lẹ̀ àti àpọ́nlé, tí ń bẹ lára àwọn Yorùbá. Ẹni tí a è pè lọ́mọlúàbí ni ẹni iyì, tí ó gbàgbọ́ nípa ìjáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ ẹni, tí ó ń bọ̀wọ̀ bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ ọmọlàkejì rẹ̀, tí ó sì ń ṣojúṣe rẹ̀ láwùjọ níbi ìfarajìn àti ìnọwọ́sí. Lákòó tán, ẹni tí ó bá jẹ́ ọmọlúàbí yóò jẹ́ tí ó yàgò tàbí sá fún iwa èérí.[1] Ọmọlúàbí tún jẹ́ gbólóhùn àpónlé tí àwọn Yorùbá tò papọ̀ láti àwọn ẹyọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: "Ọmọ + tí + Olú-ìwà it + bí" . Ládàáyanrí, ìwà ni ó jẹ́ ọmọ tí Olú (Olódùmarè) bí .
Ẹni tí ó bá jẹ́ Ọmọlúàbí yóò hùwà tí ó dára jùlọ tí ẹlòmíràn lè kọ́ṣe nínú ìwà pẹ̀lẹ́. ìwà pẹ̀lẹ́ ni gbòngbò tí a fi ṣẹ̀dá àṣà àti ìṣe Yorùbá , tí ó sì ń orígun kan nínú ìwà ọmọlúàbí. Àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ tí ó sì tún jẹ́ ìpìlẹ̀ ìwà ọmọlúàbí nìwọ̀nyí:
- Ọ̀rọ̀ sísọ (Spoken word), àwọn Yorùbá ma ń Sábà ń gbọ́lá fún ọlọ́pọlọ pípé tí ó mọ èdè í lò, tí ó sì tún mọ ààgbékalẹ̀̀ ọ̀rọ̀.
- Ìtẹríba(Respect)
- Inú rere (Good will, Having a good mind towards others)
- Òtítọ́ inú (Truth)
- Ìwà rere (Good Character)
- Akíakannjú (Bravery)
- Títẹpá mọ́ Iṣẹ́ (Hardwork)
- Ọpọlọ pípé (Intelligence)
ò sẹ́ni tí a kò le pè lọ́mọlúàbí láì kò fi ti ẹsìn kan ṣe. Èyí túmọ̀ sí wípé ìwà ọmọlúàbí jẹ́ ohun pàtàkì tí àwọn ẹlẹ́sìn mú ní ọ̀kúnkúndùn tí wọ́n sì ń kọ́ àwọn olùkópa nínú ẹ̀sìn wọn, nípa kí jíjẹ́ olótìítọ́, oníwà ìrẹ̀lẹ̀, kí á sì ma sòtítọ́ nígbà gbogbo esin wọn yálà nínú ẹ̀sìn Kristẹ́nì tàbí ẹ̀sin and Mùsùlùmí. [2]
Àwọn Ìtọ́ka sí
àtúnṣe- ↑ Adebowale, Bosede Adefiola (2019-02-27). "(PDF) omoluabi". ResearchGate. Retrieved 2019-09-29.
- ↑ "Lost concept of Omoluabi in our society". GongNews. 2018-12-28. Archived from the original on 2019-07-04. Retrieved 2019-09-29.