Bí àjàkálẹ̀ àrùn ẹ̀rankòrónà 2019 (COVID-19) ṣe n yára gbèrú si i ni gbogbo àgbáyé ti mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ ajé ma a dẹnu kọlẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn sì ti ti ipasẹ̀ yí di aláìsàn àti olóògbé. ọ̀pọ̀lọpọ̀ akitiyan ni ó ti n wáyé láti le dènà ìtànkálẹ̀ àrùn kòrónà yí áti láti mú kí iye àwọn ènìyàn míràn ti yio fi ara kó àrùn COVID-19 yí dínkù.

Àwòrán ẹnìkan tí ó ńfọ ọwọ́

Ní ìwọn ìgbàtí àwọn tí nṣe àkóso ètò ìlera ńtẹ̀ síwájú láti lo àwon irinṣẹ́ Sciensi ìgbàlódé láti bójútó ìtànkálẹ̀ àrùn yí, tí àwọn òṣìṣẹ́ ìlera si nṣẹ ìtọ́jú àwọn tí ó ti fi ara ko o àti bí wọ́n tí nṣẹ orísirísi àgbéǹde àwọn àtúnṣe, àwọn òògùn àti àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára láti le dènà àrùn yí, a ní láti mọ̀ wípé gbogbo wa ni a lè dènà ìtànkálẹ̀ àrùn yí fúnrara wa. A lè dènà ìtànkálẹ̀ àrùn yí lá ì ṣe ìnáwó tí ó pọ̀ tàbí kí á má tilẹ̀ ná owó rárá. Oun tí a nílò láti ṣe ni pé kí a yí àwọn ìhùwàsí wa tí ó lè fa ìgbésẹ̀ láti pé kí àwa, àwọn ìdílé wa àti àwọn ará agbègbè wa má lè ní ìkọlù pẹ̀lú ẹ̀rankòrónà afikú pani yi padà.

Nínú àkọsílẹ̀ yí i a má a wo bí ọwọ́ fífọ̀ àti àwọn ànà ìmọ́tótó míràn, àwọn èyí tí a bá ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, ṣe lè dènà àrùn ìkóràn pẹ̀lú àwọn kòkòrò tí ó lè ṣe ìpalára fún wa. A tún má wo àwọn ìdojúkọ tí àwọn agbègbè kan ma ńdojúkọ láti gbé ìgbésẹ̀ lórí àmúṣẹ ètò ìlera tí ó múnádóko àti bí a ṣe lè borí àwọn ìdojúkọ wọ̀nyí.


Ìgbàwo ni a lè fọ ọwọ́ àtúnṣe

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwádì ìjìnlẹ̀ ni wọ́n ti fi ìdi rẹ̀ múlẹ̀ pé ọ̀nà kan tí ó ṣe pàtàkì jùlọ, tí kò sì na wa ní owó láti fi dènà ìtànkálẹ̀ àwọn àrùn ìkóràn bi i àrùn ẹ̀rankòrónà 2019 (COVID-19), ni kí á ma fọ ọwọ́ wa nígbàgbogbo pẹ̀lú ọṣẹ àti omi mímọ́ tí ó nṣàn.[1] [2][3] ni "fífọ ọwọ́ nígbàgbogbo" túnmọ̀ sí? Àwọn tí ó ní òyé nípa ìlera ara àti àìsàn sọ wípé ní gbogbo ìgbà ni kí á ma fọ ọwọ́ wa:

  • Lẹ́hìn ìgbà tí a bá ti lo ilé ìgbọ̀nsẹ̀ tán
  • Lẹ́hìn ìgbà tí a bá ti fi ọwọ́ wa fọ ìdí fún àwọn ọmọ kékeré
  • Ṣáájú fífún àwọn ọmọdé ní oun jíjẹ
  • Ṣáájú síse ohun jíjẹ àti lẹ́hìn tí a bá ti fi ọwọ́ kó ẹran, ẹja, tàbí ẹyẹ abìyẹ́ ti ko i ti di sísè.
  • Lẹ́hìn ìgbà tí a bá ti ṣe ìtọ́jú egbó tán.
  • Lẹ́hìn ìgbà tí a bá sín, wúkọ́ tàbí fọn ikun imú tán
  • Lẹ́hìn ìgbà tí a bá ti fi ọwọ́ kó àwọn ẹranko tàbí ìyàgbẹ́ wọn.
  • Lẹ́hìn ìgbà tí a bá ti fi ọwọ́ kó ìdọ̀tí dànù
  • Lẹ́hìn ìbgà tí a bá ti fi ọwọ́ kan àwọn oríṣiríṣi ǹkan ní gbangba nítorí ó ṣe é ṣe kí àwọn ẹlòmíràn ti fi ọwọ́ kàn wón.[4]


Báwo ni à ṣé le fọ ọwọ́ àtúnṣe

Ati jẹ kí ó yé wa pé fífọ ọwọ́ wà nígbàgbogbo pẹ̀lu ọṣẹ àti omi mímọ́ tí ó ńṣàn jẹ́ ìwà ìmọ́tótó tí ó ṣe pàtàkì. Síbẹ̀síbẹ̀, kí ọwọ́ fífọ̀ tó lè múnádóko, a gbọ́dọ̀ fọ ọwọ́ dáradára. Fífọ ọwọ́ dáradára ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ìlànà wọ̀nyí:

A ní láti má a fọ ọwọ́ wa nígbàgbogbo pẹ̀lú ọṣẹ àti omi mímọ́ tí ó ńṣàn. Àwọn ọṣẹ lásán nà múnádóko bí i àwọn ọṣẹ tí ńpa kòkòrò ti se múnádóko sùgbọ́n tí kò bá sí ọṣẹ, a lè lo éérú dípò ọṣẹ.

Ọ̀nà pàtàkì míràn tí a tún lé fì fọ ọwọ́ wa, kí a sì tún ṣọ́ omi lò, ni kí á lo òògùn apakòkòrò tí a fi ńpa ọwọ́ (hand Sanitizer) èyí tí ó ní ti ó kéré ju òdìwọ̀n ìdá ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn ún (60%) èròjà ọtí. Bí ọtí yi bá ṣe pọ̀ sí tàbí lágbára sí ni yíò ṣe sọ bí òògùn apakòkòrò yí ṣe ma a ṣe iṣẹ́ sí. A lè ra àwọn òògùn apakòkòrò tí a fi ńpa ọwọ́ yi ni ilé ìtajà òògùn tàbí ilé ìtajà ńlá ṣùgbọ́n tí kò bá sí òògùn apakòkòrò tí a fi ńpa ọwọ́ ní ìtòsí, a lè lo ọṣẹ àti omi mímọ́ tí ó ńṣàn nítorí eleyi na múnádóko bakanna.

Ra àtẹ́lẹwọ́ rẹ méjèèjì papọ̀ daada, ó kéré tán fún bí i ogún ìṣẹ́jú kí o sí fi ìka kínrìn àárín àwọn ìka ọwọ́ rẹ, ẹ̀yìn ọwọ́ rẹ àti abẹ́ àwọn èékáná rẹ.

Fi omi ṣan ọwọ́ rẹ méjèèjì daada pẹ̀lú omi mímọ́ tí ó ńṣàn

Nu ọwọ́ rẹ daada pẹ̀lú towẹli tí ó mọ́.[5]

A ti ri wípé omi tí ó mọ́ ṣe pàtàkì láti fi fọ ọwọ́ wa daada kí a ba lè ní ìdáàbòbò lórí àwọn kòkòrò àìfojúrí sùgbọ́n àwọn agbègbè kan kò ní anfaani sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi mímọ́ tí ó ńṣàn. Ní abala tí ó kàn, a má a lọ wo àwọn ǹkan tí a lè ṣe nígbàtí kò bá sí omi mímọ́ tí ó ńṣàn láti lè fi fọ ọwọ́ wa.

Àwọn ọ̀nà míràn sí omi mímọ́ tí ó ńṣ̀an àtúnṣe

Tí a kò bá rí omi tí ó mọ́, a lè ṣe ìtọ́jú omi tí a bá rí pọn nínú odò tí kò fi ní sí àwọn kòkòrò àìfojúrí ninu rẹ. Ní kúkúrú, ìtọ́jú omi gbọ́dọ̀ ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ǹkan wọ̀nyí:

(a) Kí omi wa ni títòòrò: eleyi ní í ṣe pẹ̀lú yíyọ àwọn pátíkùlù ńlá àti àwọn kòkòrò tí ó ju ìdá àádọ́ta nínú ọgọ́rùn ún (50%) lọ kúrò nínú omi.

(b) Sísẹ́ omi: eléèyí ní í ṣe pẹ̀lú yíyọ àwọn pátíkùlù kéékèké kúrò nínú omi tí ó dọ̀tí àti omi tí ó ní ìda àádọ́rùn nínú ọgọ́rùn ún (90%) kòkòrò àìfojúrí.

(c) Lílo òògùn apa kòkòrò sínú omi tí ó dọ̀tí gégé bí i ìgbésè tí ó kéhìn nínú àwọn ìlànà ìtọ́jú omi tí yíò pa àwọn kòkòrò tí ó bá kù nínú omi.[6]

Àjọ ètò ìlera kan tí wọ́n ń pè ní Centre for Alternative Water and Sanitation Technology ti ṣe àgbékalẹ̀ ẹ̀rọ kan ti a npe ni "Biosand Filter" tí yíò ma mú kí omi tòòrò, láti má a sẹ́ omi àti láti má a pa àwọn kòkòrò inú omi tí ó dọ̀tí. Ẹ̀rọ yi rọrùn láti ṣe àgbékalẹ̀ rẹ. Láti ṣe ìgbàsílẹ̀ àgbékalẹ̀ àfọwọ́kọ, ẹ lọ sí ibi àdírẹ́sì yí: resources.cawst.org/package/biosand-filter-instruction-manual-en

Ní ìwọ̀n ìgbàtí omi bá ti jẹ́ mímọ́, ó gbọ́dọ̀ ma a ṣe iṣẹ́ daada tí a bá ńfọ ọwọ́ wa. a lè ṣe àwọn àgbékalẹ̀ ẹ̀rọ tí ó rọrùn, èyí tí wọ́n ti fi àwọn ohun èèlò tí ó rọrùn ṣe. Arákùnrin Peter Morgan ti ṣe àkójọpọ̀ àfọwọ́kọ èyí tí o da lórí ìrírí rẹ ní orílẹ̀ èdè Zimbabwe. A lè rí í lórí àdírẹ́sì ẹ̀rọ ayélujára yi: https://www.aquamor.info

Ìparí àtúnṣe

Fífọ ọwọ́ wa dáradára nígbàgbogbo pẹ̀lú ọṣẹ tàbí éérú àti omi tí ó mọ́ jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì tí kò ná wa lówó láti ṣe ìdíwọ́ fún ìtànkálẹ̀ àwọn àrùn. Bí àjàkálẹ̀-àrùn àgbáyé (World Pandemic) bi i àjàkálẹ̀ àrùn ẹ̀rankòrónà 2019 ti ṣe n dẹ́rùbà wá lórí ìwàláyé wa, a nílò láti ṣe àfikún lórí ìyípadà ìhùwàsí wa gẹ́gẹ́ bi ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ àti lílo ìbòmú bo ẹnu (facial masks) nígbàtí a bá wa ní àárín àwùjọ jẹ àwọn ǹkan tí ó ṣe pàtàkì.

Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "Show Me the Science - Why Wash Your Hands? - Handwashing". CDC. 2018-09-17. Retrieved 2020-07-16. 
  2. "Advice for the public on COVID-19 – World Health Organization". WHO. 2020-06-04. Retrieved 2020-07-16. 
  3. Publishing, Harvard Health (2020-07-14). "Preventing the spread of the coronavirus". Harvard Health. Retrieved 2020-07-16. 
  4. "When and How to Wash Your Hands - Handwashing". CDC. 2020-04-02. Retrieved 2020-07-10. 
  5. "The right way to wash your hands". Mayo Clinic. 2020-04-01. Retrieved 2020-07-10. 
  6. "WASH Education and Training Resources". WASH Education and Training Resources. Retrieved 2020-07-10.