Ìró aṣèyàtọ̀

(Àtúnjúwe láti ASÈYÀTỌ̀)

Ìró aṣèyàtọ̀ ni ìyàtọ̀ tàbí ìb́tan òun ìbáṣepọ̀ tí ó wá láàrín ìró méjì. [1] Nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀, ìró ni a máa ń pè. Ojú tí a fi ń wo ìró yìí yàtọ̀ sí ara wọn. Nígbà tí onímọ̀ Fónẹ́tíìkì máa ń fúnka mọ́ bí a ṣe ń pe ìró kọ̀ọ̀kan. Onímọ̀ Fonọ́lọ́jì máa ń wo ìbátan tí ó wà láarin ìró kọ̀ọ̀kan. Bí àpẹẹrẹ, ìró wo ni ó fa ìyàtọ̀ ìtumọ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìsàlẹ̀ yìí?:

sẹ́

A ó ṣe àkíyèsí pé ìró fáwẹ́lì ni ó fa ìyàtọ̀ ìtumọ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ òkè yìí. Fáwẹ́lì [á], [ẹ́], [ú] ni ó fa ìyàtọ̀ ìtumọ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìró kọ́nsónáǹtì àti ìró ohùn kán náà ni gbogbo wọn ní. Nítorí náà, àwọn ìró fáwẹ́lì yẹn ni ìró aṣèyàtọ̀.

Ìró aṣèyàtọ̀ ni ó ṣe pàtàkì nínú èdè Yorùbá, àwọn tí kò ṣe pàtàkì ni ìró àìṣèyàtọ̀/aláìṣèyàtọ̀ (ẹ̀dà fóníìmù). Kín wá ni Ìró Aṣeyàtọ̀? Nínú ìmọ̀ Ẹ̀dá-Èdè, ohùn tí a ń pe gbogbo ìró tí à ń pè jáde ni nígbà tí a bá ń fọ̀ ni a mọ̀ sí Fóònù. Ṣùgbọ́n kìí ṣe gbogbo fóòù ni ó máa ń mú ìyàtọ̀ ìtumọ̀ bá ọ̀rọ̀. Àwọn ìró tí ó máa ń fa ìyàtọ̀ ìtumọ̀ ni a mọ̀ sí ìró aṣèyàtọ̀. Owólabí (2013:97) ṣàlàyé pé àwọn fóònù kan jẹ ìró aṣèyàtọ̀ nígbà tí àwọn fóònù mìíràn náà wà tí wọ́n jẹ́ ìró aláìṣeyàtọ̀. Fóònù tí ó máa fa ìyàtọ̀ ìtumọ̀ láàárín ọ̀rọ̀ kan sí òmíràn ni a mọ̀ sí ìró aṣèyàyọ̀ gẹ́gẹ́ bí a ṣe fi hàn lókè. Àmọ́, àwọn fóònù tí kìí fa ìyàtọ̀ ìtumọ̀ láàárín ọ̀rọ̀ kan sí òmíràn ni a mọ̀ sí ìró aláìṣeyàtọ̀.  Láti ṣe ìtúpalẹ̀ èdè kan onímọ̀ ẹ̀dá-èdè gbọ́dọ̀ ṣe àdàkọ fóònù inú èdè ọ̀hún lẹ́yìn náà ni yóó wá ṣe akitiyan láti wá àwọn ìró aṣèyàtọ àti ìró aláìṣeyàtọ̀ rí.

Síṣe àwárí ìró aṣèyàtọ̀

Láti le fi hàn pé ìró kan jẹ́ aṣèyàtọ̀ tàbí aláìṣèyàtọ̀, a ó yẹ ìfọ́nká wò (distribution). Orísìí ìfọ́nká méjì ni ó wà. Ìfọ́nká Aṣèyàtọ̀ àti Àìṣèyàtọ̀. Ìfọ́nká tí à ń wí yìí dúró lórí ipò tí ìró bá ti jẹyọ, bóyá sí iwájú ni, ẹ̀yìn tàbí àárín.

Ìfọ́nká Aṣèyàtọ̀

Bí ìró méjì bá jẹyọ ní sàkání kan náà tí ó sì jẹ́ pé bí a bá fi ọ̀kan rọ́pò èkejì, tí irú ìrọ́pò bẹ́ẹ̀ mú ìyípadà bá ìtumọ̀ ọ̀rọ̀, nínú ìmọ̀ ẹ̀dá èdè tí a tún pè ní Lìngúísíìkì, a máa ń sọ pé àwọn ìró bẹ́ẹ̀ ṣe ìyàtọ̀. Bí àpẹẹrẹ wo ìró [b], [d]; [m], [n]; [a], [ᴐ] nínú ọ̀rọ̀ ìsàlẹ̀ yìí

bɛ àti dɛ

in҄ú àti im҄ú

rɛ́ àti rᴐ́

Wà á sàkíyèsí pé nínú (i) ìró [b] àti [d] ni wọ́n fa ìyàtọ̀ nínú ìtumọ̀ bí a bá fi ọ̀kan rọ́pò èkejì. Ní sàkáni wo ni wọ́n ti jẹyọ? wà á rí i pé iwájú ni wọ́n wà. Ní ti (ii) àárín ni ìró [n] & [m] wà, àwọn ni wọ́n sì mú ìyàtọ̀ ìtumọ̀ bá ọ̀rọ̀ náà bí a bá lo ọkan nínú wọ́n láti rọ́pò èkèjì. Ìró [ɛ] & [ᴐ] tí ó gbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ (iii) ni ó mú ìyàtọ̀ bá ìtumọ̀ bí a bá ṣe ìrọ́pò gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe sọ sáajú. Sàkání tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìró yìí tí ó mú ìtumọ̀ bá àwọn ọ̀rọ̀ òkè yẹn ni à ń pè ní ìfọ́nka aṣèyàtọ̀, nítorí náà, ìró aṣètàtọ̀ ni wọ́n.

Ìfọ́nká Aláìṣèyàtọ̀

Bí ìró kan bá yọ ní sàkání ìró mìíràn ṣùgbọ́n tí kò mú ìyàtọ̀ ìtumọ̀ dáni, sàkání tí wọ́n ti jẹyọ ni ìfọ́nká aláìṣèyàtọ̀, nítorí náà, wọ́n jẹ́ ìró aláìṣèyàtọ̀. Bí àpẹẹrẹ, [l] àti [n] jẹ́ ìró aláìṣèyàtọ̀. Fún ìdí èyí àwọn méjéèjì ni ẹ̀dà fún /l/

Bí àpẹẹrẹ wo ọ̀rọ̀ bí i

Oní +ilé  = onílé

Oní + aṣọ  = aláṣọ

Wà á kíyèsí pé sàkání tí kọ́nsónáǹtì [n] àti [l] ti jẹyọ jọ ọ̀kan-ùn ṣùgbọ́n kìí ṣe ọ̀kan náà. Ní ìgbà tí kọ́nsónáǹtì [n] jẹyọ ní agbègbè ìránmú, kọ́nsónáǹtì [l] jẹyọ ní agbègbè àìránmú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò kan náà ni wọ́n ti jẹyọ. Ìyẹn já sí pé ìfọ́nká aláìṣèyàtọ̀ ní àwọn ìró méjéèjì ti jẹyọ nítorí náà ìró aláìṣèyàtọ̀ ni wọ́n. Wọn kìí ṣe fóníìmù, ẹ̀dà fóníìmù ni wọ́n.

Àwọn àtúnṣe

àtúnṣe
  1. Okeke, Samuel Emeka (2022-09-06). "FONOLOJI EDE YORUBA". Acadlly Education. Retrieved 2024-08-01.