Aalo ìrókò àti Olúróhunbí

Olúróhunbí àti Iroko

àtúnṣe

Àlọ́ oo ,

Àlọ́ ọọ,

Àlọ́ yìí dá lórí Olurohunbi àti Olúwéré[1]

Ní ayé àtijó, obìnrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúróhunbí. Obìnrin yìí kò sì fi inú soyún, bẹ́ẹ̀ ni kò fẹ̀yin gbọ́mọ pọ̀n, èyí jásí pé ó yàgàn. Ó wá ọmọ títí ṣùgbọ́n pàbó ló ń já sí. Dípò kí ó dúró de iṣẹ́ Olódùmarè, ó gba ọ̀dọ̀ olúwéré lọ. Ó ṣe eléyìí nígbà tí ó rí àwọn tí wọ́n jọ wà nínú ipò báyìí tí wọ́n ń gbọ́mọ pọ̀n. Olúróhunbí gbéra ó lọ sí ọ̀dọ̀ olúwéré. Pẹ̀lú ìtara ni Olúróhunbí fi jẹ́ ẹ̀jẹ́ pé bí olúwéré bá fún òun lómọ, òun yíò sì fún un ní ọmọ náà. Ẹ̀jẹ́ yìí jẹ́ ọ̀tun nítorí pé, ewúrẹ́ àgùntàn ni àwọn obìnrin ń padà wá fún olúwéré gẹ́gẹ́ bí ẹ̀jẹ́.

Lóòótọ́, Olúróhunbí lóyún, ó sì bí ọmọbìnrin kan tí ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Apọ́nbiepo. Apọ́nbiepo ń dàgbà, ìyá rẹ̀ kò sì rántí ẹ̀jẹ́ tí ó bá olúwéré dá.

Nígbà tí olúwéré retí Olúróhunbí kí ó wá mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣe tí kò ríi ni òun gan-an bá gbéra ni ọjọ́ kan ó gba ilé Olúróhunbí lọ. Bí ó ṣe dé'bẹ̀ tí ó f'ojú kan Apọ́nbiepo ni ó bá lé lọ́wọ́ mú tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mú lọ. Ọmọ yìí bẹ̀rẹ̀ si sunkún títí tí ìyá rẹ̀ Olúróhunbí bẹ̀rẹ̀ sí sáré tẹ́lẹ̀ olúwéré títí olúwéré fi padà wọ inú igi lọ pẹ̀lú Apọ́nbiepo.[2]

Olúróhunbí bẹ̀rẹ̀ si bẹ olúwéré pẹ̀lú omijé lójú, ṣùgbọ́n dípò kí olúwéré dá ọmọ padà, orin ni ó bẹ̀rẹ̀ sí fi dáa lóhùn báyìí pé :

ORIN ÀÀLÓ

àtúnṣe

Olúwéré                  oníkálukú ń jẹ̀jẹ́ ewúrẹ́,

                               Ewúré ewúrẹ́,

                               oníkálukú ń jẹ̀jẹ́ àgùntàn,

                                Àgùntàn bọ̀lọ̀jọ̀,

                               Olúróhunbí ń jẹ̀jẹ́ ọmọ rẹ̀,

                               ọmọ rẹ Apọ́nbiepo            

                               Olúróhunbí oo

Agbeorin              janin-janin, ìrókò janin-janin

Olúwéré :              Olúróhunbí oo

Agbeorin               janin-janin, ìrókò janin-janin

Báyìí ni Olúróhunbí ṣe pàdánù ọmọ rẹ̀

Ẹ̀kọ́ INÚ ÀÀLỌ́

àtúnṣe

Ẹ̀kọ́ tí Àlọ́ yìí kọ́ wa wípé bí a bá jẹ́jẹ̀ẹ́ kí á rí wí pé ẹ̀jẹ́ tí a lè san ni a jẹ́, kí á má máa fi ìwànwara jẹ́ ẹ̀jẹ́. Ní èkejì ó yẹ kí á máa kó gbogbo àníyàn wà tí Olódùmarè. Kí á má máa fi ìwànwara wá nǹkan torí ọba ọ̀kẹ́ t'óṣe fún Táyé kò gbàgbé Kẹ́hìndé, ẹ jẹ́ kí á sọ́ra.

ÀWỌN ÌTỌ́KASÍ

àtúnṣe
  1. https://yorubafolktales.wordpress.com/
  2. https://www.scribd.com/book/325976572/Yoruba-Folk-Tales