Àlọ́ oooo

Àlọ́ ọọọọ

Àlọ́ yìí dá lórí Ẹkùn àti Ikùn

Ní ìlú àwọn ẹranko, kìnnìún ni Ọba wọn. Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, Ọba ẹranko pe gbogbo àwọn ẹranko jọ, ó sọ fún wọn pé òun fẹ́ dá ọjọ́ tí àwọn ẹranko yóò wa ṣe eré fún òun. Ó sọ pé ẹni tí ó bá lu ìlù dáadáa òun yóò da lọ́lá. Nítorí ìdí èyí ó ní kí ẹranko kọ̀ọ̀kan lọ kan ìlù. Gbogbo àwọn ẹranko gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọba, wọ́n dárí lọ sí ilé wọn[1].

Ẹni kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ẹranko ń gbìyànjú à ti kan ìlù. Ṣùgbọ́n dípò kí ẹranko kan tí orúkọ rẹ ń jẹ ikún ó kan ìlù tie, ní ṣe ni ó lọ gbé ìlú ẹkùn níbi tí ẹkùn gbé e sí. Ẹkùn bẹ̀rẹ̀ sí wa ìlú rẹ, ó wàá títí kò ri. Nígbà tí ó di ọjọ́ aré, ẹkùn jí ni kùtùkùtù ó lọ dúró ní ọ̀nà tí ó lọ sí ilé kìnnìún ọba ẹranko. Bí ẹranko kọ̀ọ̀kan bá ti fe kọjá ni ẹkún yóò yọ sí i tí yóò sì sọ pé kí ó lu ìlù rẹ̀ kí òun gbọ́[2]. Orin ni ẹkún fi ń sọ eléyìí fún wọn tí orin náà sì lọ báyì:

Ẹkùn________ Ríkíríkijàn

Agberin_____ Àríkijàn

Ẹkùn________Ríkíríkijàn

Agberin_____Àríkijàn

Ẹkùn________ Ọba ló dájọ́ aré

Agberin_____ Àríkijàn

Ẹkùn________ Ọba ló dájọ́ ayò

Agberin_____Àríkijàn

Ẹkùn________Wọ́n ní á kànlù, mo kànlù

Agberin_____Àríkijàn

Ẹkùn________ Mo gbé ìlú mi s'àgbàlá

Agberin_____ Àríkijàn

Ẹkùn________ Ọmọ ẹranko gbé e lọ

Agberin_____Àríkijàn

Ẹkùn________ Lùlù rẹ kí n gbọ́

Agberin_____Àríkijàn

Ẹkùn________Lùlù rẹ kí n mọ

Agberin_____Àríkijàn

Ẹkùn________ Papakúkú rangbọndan

Agberin_____ Àríkijàn

Ẹkùn________ Papakùkù rangbọndan

Agberin_____ Àríkijàn

Ẹkùn________Ìlù mi kọ́ùn ni

Agberin_____Àríkijàn

Ẹkùn________ Rékọjá o máa lọ

Agberin_____Àríkijàn

Báyìí ni ẹranko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọjá tí ẹkùn sì ń kọ orin bákan náà. Nígbà tí ó kan ikùn láti kọjá, ẹ̀rù ti bẹ̀rẹ̀ sí bàa. Ẹkùn tún bẹ̀rẹ̀ orin rẹ̀ :

Ẹkùn________ Ríkíríkijàn

Agberin_____ Àríkijàn

Ẹkùn________Ríkíríkijàn

Agberin_____Àríkijàn

Ẹkùn________ Ọba ló dájọ́ aré

Agberin_____ Àríkijàn

Ẹkùn________ Ọba ló dájọ́ ayò

Agberin_____Àríkijàn

Ẹkùn________Wọ́n ní á kànlù, mo kànlù

Agberin_____Àríkijàn

Ẹkùn________ Mo gbé ìlú mi s'àgbàlá

Agberin_____ Àríkijàn

Ẹkùn________ Ọmọ ẹranko gbé e lọ

Agberin_____Àríkijàn

Ẹkùn________ Lùlù rẹ kí n gbọ́

Agberin_____Àríkijàn

Ẹkùn________Lùlù rẹ kí n mọ

Agberin_____Àríkijàn

Ẹkùn________ Papakúkú rangbọndan

Agberin_____ Àríkijàn

Ẹkùn________ Papakùkù rangbọndan

Agberin_____ Àríkijàn

Ẹkùn________ ìlù mi nùnun nì

Agberin_____ Àríkijàn

Bí ikùn tí gbọ́ pé ìlù ẹkùn ni òun gbé lọ́wọ́, pẹ̀ẹ̀ lójú ìlù sílè tí ó bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ. Ẹkùn gbá tẹ́lẹ̀e,ṣùgbọ́n bí ẹkùn ṣe ni kí òun ó ki ikùn mọ́lẹ̀ ni ó ṣá wọ inú ihò lọ. Ikùn kò lọ láì f'arapa, èékánná ẹkùn ha ikùn ní ẹ̀gbẹ̀ méjèèjì. Bí ènìyàn bá rí ikùn lónìí, yóò rí pé ilà funfun wà ní ẹ̀gbẹ̀ méjèèjì ikùn di òní olónìí yìí[3].

Ẹ̀KỌ́ INÚ ÀÀLỌ́ àtúnṣe

Ààló yìí kọ wa kí a má maa ja, nítorí pé kì í bí ọmọ rere.

ÀWỌN ÌTỌ́KASÍ àtúnṣe

  1. https://ng.loozap.com/ads/akojopo-alo-ijapa-apa-kini/19079098.html[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  2. https://www.scribd.com/book/325976572/Yoruba-Folk-Tales
  3. https://yorubafolktales.wordpress.com/