Àalọ́ yìí dá lórí Ilẹ̀ àti ọlọ́run.

Ààlọ́ oooo

Ààlọ́

Ní ayé àtijó, ọ̀rẹ́ ni ilẹ̀ àti ọlọ́run. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ibùgbé wọn jìnà sí ara wọn, àwọn méjèèjì a máa wá ara wọn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni ọlọ́run máa ń sọ̀kalẹ̀ láti wá bá ilẹ̀ ṣeré.

Ní ọjọ́ kan, àwọn méjèèjì pinnu láti dẹ̀'gbẹ́ lọ kí àwon lè pa ẹran. Wọ́n dẹ ìgbẹ́ títí, eku ẹmọ́ kan ni wọ́n rí pa. Ọlọ́run sọ wípé òun l'ẹ̀gbọ́n, nítorí ìdí èyí, òun ni òun yó mú èyí tó pọ̀ níbẹ̀. Ilẹ̀ náà fàáké kọ́rí ó ní òun ni àgbà tí ó gbọ́dọ̀ mú èyí tí ó pọ̀. Ìjà yìí pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ọlọ́run fi bínú lọ sí ọ̀run tí ilẹ̀ náà sì bínú lọ.

Lẹyin ti olukuluku ti fariga ti o si pada lọ si aaye rẹ̀ ki ló wá ṣẹlẹ̀? Oun to ṣẹlẹ ni pé òjò kọ̀ kò rọ̀, àgbàdo pọ̀n'gbẹ́, kò gb'ọ́mọ pòn, ọmọge lóyún oyún gbẹ mọ́ wọn lára, akérémọdọ̀ w'ẹ̀wù ìràwé. Iyán yìí mú títí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn bẹ̀rẹ̀ síí kú. Nígbà tí ó ṣe, ọba ìlú wá eéjì kún ẹẹ́ta, ó lọ oko aláwò. Babaláwo wa sọ fún un pé wọn gbọdọ̀ ṣe ètùtù. Ohun tí wọn yíò ṣe náà ni kí wọn gbé ẹbọ ló sí ọ̀run. Kò sí ẹni tí ó yọjú láti gbé ẹbọ yìí bí kò ṣe ẹyẹ Igún. Igún gbé ẹbọ ó di ọ̀nà ọ̀run. Ṣùgbọ́n bí ó ti ń lọ ní ó bẹ̀rẹ̀ sí kọrin báyìí pé:[1][2]

Orin Ààlọ́

àtúnṣe

Igún:_________Olúnréte

Elégbè:_______Àjànréte jàà

Igún:_________Olúnréte

Elégbè:_______Àjànréte jàà

Igún:_________Ilé ohun Ọlorun

Elégbè:_______Àjànréte jàà

Igún:_________ Wọ́n p'eku ẹmọ́ kan

Elégbè:_______Àjànréte jàà

Igún:_________Ọlọ́run L'óun l'ẹ̀gbọ́n

Elégbè:_______Àjànréte jàà

Igún:_________Ilé L'óun l'àgbà

Elégbè:_______Àjànréte jàà

Igún:_________Ọlọ́run bínú ó lọ

Elégbè:_______Àjànréte jàà

Igún:_________Ilé bínú ó lọ

Elégbè:_______Àjànréte jàà

Igún:_________ Àgbàdo pọ̀n'pẹ́ kò gbó

Elégbè:_______Àjànréte jàà

Igún:_________ọmọge lóyún oyún gbẹ

Elégbè:_______Àjànréte jàà

Igún:_________Olúnréte

Elégbè:_______Àjànréte jàà[3]

Bí igún ti gbé ẹbọ dé ọ̀run ni ọlọ́run gba ẹbọ náà. Èyí jásí pé ẹbọ fín, ẹbọ dà. Bí igún tí gbé ẹbọ ṣílẹ̀ tán tí ó ń bọ̀ wá sí ilé ayé ni òjò bá bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀. Òjò yìí l'ágbára púpọ̀ tí ó fi jẹ́ pé gbogbo àwọn ẹyẹ ni wọ́n ti ilẹ̀kùn ilé wọn mọ́ orí. Nígbà tí igún dé, òjò ti gbé ilé rẹ, kò sì rí ibi tí yíò yà sí tàbí f'arapamọ́ si. Ohun tí ó tún wá burú ni pé bí ó bá ti fẹ́ yà sí ilé ẹyẹ kan ni ẹyẹ yìí ó saajẹ ní orí. Àwọn ẹyẹ ṣe eléyìí títí orí igún fi pá títí di òní yìí[4].

Ẹ̀kọ́ Inú Ààlọ́

àtúnṣe
  1. Ọkanjuwa ko dara. Ko si oun ti o kere ju fun ọpọlọpọ eniyan lati pin bi itẹlọrun ba wa.
  2. Àlọ́ yìí kọ́ wa wípé kò yẹ kí a fi ibi san oore. Oore ni igún ṣe, ibi ni wọ́n fi ṣan fún un.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. https://www.scribd.com/book/325976572/Yoruba-Folk-Tales
  2. https://yorubafolktales.wordpress.com/
  3. https://ng.loozap.com/ads/akojopo-alo-ijapa-apa-kini/19079098.html[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  4. "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2023-05-02. Retrieved 2023-05-02.