Aalo obìnrin kan àti ọmọ rẹ meta

Ààlọ́ obìnrin kan àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta
àtúnṣe

ÀÀLỌ́ OOOO

ÀÀLỌ́

Àalọ́ yí dá fìrìgbagbo, ó dá lórí obìnrin kan àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta.[1]

Ni ìlú kan orúkọ ìlú náà ni olówó, obìnrin kan wà tí ó bí ọmọ mẹ́ta. Orúkọ àwọn ọmọ náà ni, Wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ laá ṣẹ́gi, àràwàrà làá wọ̀gbẹ́ àti Ọmọniyùn tí ó jẹ́ àbígbẹ̀yìn. Obìnrin yìí wá fẹ́ràn Ọmọniyun ju àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ, kò sì fi ìfẹ́ yìí pamọ́ fún àwọn ẹ̀gbọ́n Ọmọniyùn.

Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, àwọn ọmọ mẹ́tẹ́ẹ́ta jáde nílé, wọn kò sì mọ ọ̀nà ilé mọ́. Obìnrin yìí wá àwọn ọmọ rẹ̀ títí kò rí wọn. Nígbà tí ó ṣe, obìnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí wá àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú orin àti omijé lójú. Obìnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin báyìí pé:[2]

Orin Ààlọ́
àtúnṣe

Obìnrin             Èrò ọjà olówó

Agberin            Jàlòlò jàlòlò

Obìnrin             Taa ló bá mi rọ́mọ mi,

Agberin            Jàlòlò jàlòlò, Kíni orúkọ t'ọ́mọ rẹ máa ń jẹ? Jàlòlò jàlòlò

Obìnrin             Ọ̀kan wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ laá ṣẹ́gi

Agberin            Jàlòlò jàlòlò

Obìnrin             Ọ̀kan wàràwàrà làá wọ̀gbẹ́

Agberin            Jàlòlò jàlòlò

Obìnrin            Ọ̀kan Ọmọniyun kékeré, ọ̀rọ̀ Ọmọniyun ló dùn mí jọjọ

Agberin           Jàlòlò jàlòlò

Obìnrin           Èrò ọjà olówó

Agberin          Jàlòlò jàlòlò

Bí ó ṣe ń kọ orin yìí, obìnrin yìí kò mọ̀ pé wọ́n tí gbé àwọn ọmọ òun pamọ́ lati fi eyi dá obìnrin yìí lára wípé kò yẹ kí á máa fẹ́ràn ọmọ kan ju èkejì lọ nítorí Olódùmarè ló fi àwọn ọmọ yìí ta wá lọ́re.

Obìnrin yìí tún bẹ̀rẹ̀ orin bí tí ìṣáájú. Nígbà tí ó ṣe, wọ́n taari méjì nínú àwọn ọmọ obìnrin yìí síta. Inú obìnrin yìí kò dùn torí pé kò rí Ọmọniyun tííṣe àbígbèyìn ọmọ rẹ̀. Àwọn ènìyàn sì gbìmọ̀ pọ̀ láti dá obìnrin yìí lójú. Ohun tí wọ́n sì ṣe ní wípé wọ́n pa Ọmọniyùn. Bí obìnrin yìí tí ríi ni ó bú sí ẹkún ni ó tún bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin. Kò pẹ́ ni wọn ju òkùtù Ọmọniyùn sí ìyá rẹ̀. Inú ìyá Ọmọniyùn bàjé gidigidi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún lọ sí ilé[3][4].

Ẹ̀kọ Inú Ààlọ́
àtúnṣe

Àlọ́ yìí kọ́ wa wípé kí á máa fẹ́ràn ọmọ kan ju ọmọ èkejì lọ torí a kò mọ irú ohun tí àwọn ọmọ yìí leè dà ní ọjọ́ ọ̀la. Òkúta tí ọ̀mọ̀lé kọ̀ tún lè padà wá di igun ilé ni ọjọ́ ọ̀la.

Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe
  1. https://yorubafolktales.wordpress.com/
  2. https://www.scribd.com/book/325976572/Yoruba-Folk-Tales
  3. https://ng.loozap.com/ads/akojopo-alo-ijapa-apa-kini/19079098.html[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  4. "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2023-05-03. Retrieved 2023-05-03.