Abdullahi Burja
Abdullahi Dan Kanajeji, tí a mọ̀ sí Abdullahi Burja, jẹ́ ọba ìlú Kano kẹrìndínlógú. Látàri dídá ìbáṣepọ̀ àti ọ̀nọ̀n okòwò tí ó péye sílẹ̀, Butja ni ó yí ìlú Kano kúrò sí ìlú ìṣòwò tí a mọ Kano àti àwọn ará Kano sí lóde òní [1] Ó jẹ́ ọba Hausa àkọ́kọ́ tí ó tẹríba fún ìlu Bornu tí èyi sì jẹ́ kí àjọṣepọ̀ tí ó dánmọ́ran wà láàrin wọn tí èyí sì jẹ́ kí okòwò wọn gbòòrò láti Gwanja sí Bornu. Ó sì tún jẹ́ ọba àkọ́kọ́ tí ó máa kọ́kọ́ ní ràkúnmí ní gbogbo ilẹ̀ Hausa. [2] Èyí sì fa kí ìṣòwò ẹrú gbòòrò lati Kano sí gúùsù sí Bornu.
Abdullahi Burja | |
---|---|
Sarkin Kano
|
Abdullahi Burja nípasẹ̀ Galadima rẹ̀ ṣẹ̀dá àwọn ìleto ẹrú tuntun mọ́kànlélógun, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan tó bí ẹgbẹ̀rún àwọn ẹrú tí ó ipín dọ́gba láàrín àwọn ẹrú ọkùnrin àti obìnrin. Díẹ̀ díẹ̀, ìṣòwò ní Ìlú Kano yípadà sí àwọn òwò mííràn. [3]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Movements, Borders, and Identities in Africa. Boydell & Brewer.
- ↑ The Kano Chronicle. https://zenodo.org/record/2415833.
- ↑ David Henige, Oral Historiography. London: Longman, 1982, 150 pp., £3.95 paperback..