Oyún Ṣíṣẹ́ ní Albania
Oyún Ṣíṣẹ́ ní Albania ((English: Abortion in Albania) di òfin ní Ọjọ́ keje Oṣù kejìlá Ọdún 1995.[1] Oyún lè di ṣíṣẹ́ tí wọ́n bá bèrè fún ṣiṣẹ́ rẹ̀ kí ó tó pé ọ̀sè mẹ́fà ti oyún ti dé ara.[2] Obìnrin tí ó fẹ́ ṣéyún gbọ́dọ̀ gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ olùgbaninímọ̀ràn fún ọ̀sè kan gbáko kí ṣẹ́ oyún náà fún, tí ilé ìwòsàn tí ó ń ṣẹ́ oyún kò gbọgọ̀ jẹ́ kí àwọn ará ìlú ó mọ arábìrin tí wọ́n ṣẹ́ oyún fún.[2]
Ní àkókò ìjọba ti Enver Hoxha, Albania ń tẹ̀lé ìlànà ìbímọ rẹpẹtẹ,[2] tí ó sì maa ń jẹ́ kí àwọn obìrin ṣẹ́ oyún lọ́nà àìtọ́ tàbí kí wọ́n lo nkan láti ṣẹ́ oyún yìí fúnra wọn. Lákótán, orílẹ̀ èdè yìí jẹ́ ìkejì tí ikú aláboyún ti pọ̀ jùlọ ní gbogbo Europe, tí 50% gbogbo oyún maa ń bọ́sí ṣíṣẹ́.[2] Àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú Communist party maa ń fi obìnrin tí ó bá jẹ̀bi oyún ṣíṣẹ́ ṣẹ̀sín tàbí kí wọ́n ran lóko iṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìdánilẹ́kọ́.[2]
Ní ọdún 1989, wọ́n gba oyún ṣíṣẹ́ láyè tí ó bá jẹ́ ìbáṣepọ̀ ìbatan, ìfipá bánilò tàbí tí ẹni tó lóyún bá wà lábẹ́ ọjọ́ orí mẹ́rìndínlógún.[2] Ní ọdún 1991, wọ́n gba obìnrin láyè lati ṣẹ́ oyún fún ara wọn fún ìdí oríṣiríṣi tí àwọn àjọ oníwòsàn bá ti fọwọ́ si pé ìgbésẹ̀ tó dára ni.[2] Òfin1995 fagi lé àwọn ofin tàtẹ̀yìnwá.[1]
Ní bíi ọdún 2010, ìwọ̀n oyún ṣíṣẹ́ jẹ́ 9.2 fún ẹgbẹ̀rún kan obìrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọdú[update].[3]
Tún wo
àtúnṣeÀwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 Aborti – vrasje e fëmijës së palindur (in Albanian) Nr. 8045, data 07. 12. 1995, që është mbështetje e nenit të ligjit nr. 7491, të vitit 1991 "Për dispozitat kryesore kushtetuese" me propozimin e Këshillit të Ministrive, miratuar në Kuvendin Popullor të Shqipërisë.
- ↑ 2.0 2.1 2.2 2.3 2.4 2.5 2.6 Albania – ABORTION POLICY – United Nations
- ↑ "World Abortion Policies 2013".