Adéyẹyè Ẹnitàn Ògúnwúsì
Ọ́ba Adéyeyè Enitàn Ògúnwúsì jẹ́ Ọba tó gbajúmọ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni Kábíyèsí tó wà lórí ìtẹ́ Oòni ti ìlú Ilé-Ifẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ ní ilẹ̀ Yorùbá. Láti ọduń 2015 ni ó ti gorí ìtẹ́ àwon babańlá rẹ̀.[1]
Ọọ̀ni Adéyẹyè Ẹnitàn Ògúnwúsì Ojaja II | |
---|---|
Ọ̀jájá Kejì | |
Ọọ̀ni ti Ilé-Ifẹ̀ | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga 26 October 2015 | |
Asíwájú | Olúbùse Kejì |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 17 Oṣù Kẹ̀wá 1974 Nigeria |
Ọmọorílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Àwọn ọmọ | Ọmọba Adéọlá Ògúnwúsì |
Àwọn òbí | Ọmọba Adérópò Ògúnwúsì ati Ọmọba Wúràọlá Ogunwusi |
Residence | Ilẹ̀ Oòduà ( Ààfin Ọọ̀ni) |
Occupation | Onímọ̀ Ìsirò Owó, Onímọ̀ Àtò àti Ìdàgbàsókè Ìlú, Ọba Ilé-Ifè |
ÌGBÁSÍAYÉ RẸ̀ NÍ ÌBẸ̀RẸ̀ PẸ̀PẸ̀
àtúnṣeỌba Ògúnwùsì bẹ̀rẹ̀ ilé-ìwé alákọ̀óbẹ̀rẹ̀ ni Ṣubúọ́lá Memorial Nursery and Primary School, Ìbàdàn àti Ìbàdàn District Council, Akobo, Ìbàdàn. Lẹ́yìn èyí, ó lọ sí Loyola College, Ìbàdàn ati St. Peters Secondary School, Ilé-Ifẹ̀ níbi tí ó ti gba sabuké (ìwé-èrí) ẹ̀kọ́ onípèlé kejì. Ó tẹ̀ síwájú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní The Polytechnic, Ìbàdàn, níbi tí ó ti gboyè ẹ̀kó-gíga àkọ́kọ́ nínú ímọ̀ ìṣirò owó.
ÀWỌN IBIṢẸ́ TÍ Ó TI LÀMÌ-LAKA
àtúnṣeÓ jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Institute of Chartered Accountants of Nigeria. Ótún jẹ́ Associate Accounting Technician. Kábíyèsí Ògúnwùsì jẹ́ ògidì The Institute of Directors. Ótún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ the Global Real Estate Institute. Ó gba ópọ̀lọpọ̀ àmìn èyẹ ìdánilólá Dókítà ní Ẹ̀ka-Ẹ̀kọ́ Ìṣètò Àwùjọ (Public Administration) láti the University of Nigeria, Nsukka, baḱan náà irú àmìn èyẹ yìí ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Òfin (Law) ní Igbinedion University.
Ọba Ògúnwùsì jẹ́ Bàbá-ìsàlẹ̀ Ifáfitì (Chancellor) the University of Nigeria, Nsukka.
ÈTÒ YÍYÀN-ÁN SÍPÒ ỌBA ÀTI JÍJÁWÉ OYÈ LÉ E LÓRÍ
àtúnṣeLáàárín ọpọ̀lọpọ̀ ọmọ oyè tí Ọba tọ́ sí ní Ilé-Ifẹ̀ ni a ti yan Ọọ̀ni Adéyẹyè Ògúnwúsì ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọn Oṣù kẹwàá Ọdún 2015. Ó gba Ọ̀pa àṣe ní ọjó keje oṣù kejìlá, ọdún 2015. Ọọ̀ni Ògúnwúsì, gẹ́gé bí a ti júwe rẹ̀ jẹ́ ògbóǹtarìgì olùṣòwò tí ó lè ṣe ohun tí ọpọ̀lọpọ̀ kò lè dojúko. Ó jẹ́ olórí gbogbo ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ tí a fún lágbạra láti ṣe ìrúbo sí Olódùmarè àti àwọn orìṣà lórúko gbogbo ìran Yorùbá ní àgbaye ní ìgbà Ọdún Olójó.[2]
Àwọn Ìtókasí
àtúnṣe- ↑ "Biography Of H.i.m Oba (dr) Adeyeye Babatunde Enitan Ogunwusi (ooni Of Ife)" (in en). Nigerian Voice. https://m.thenigerianvoice.com/news/264735/biography-of-him-oba-dr-adeyeye-babatunde-enitan-ogunwus.html.
- ↑ "Punch Newspapers – The most widely read newspaper in Nigeria". punchng.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2018-03-28.