Zekiros Adanech ni a bini ọjọ kẹrin dinlọgbọn, óṣu kẹta ni ọdun 1982 jẹ elere sisa ti ọna jinjin órilẹ ede Ethiopia[1][2][3][4]. Lori iṣẹ rẹ gẹgẹbi elere sisa, awọn ibi to ti gbegba oroke julọ ni:31:59.37 ninu 10,000 metres to waye ni Sollentuna ni ọjọ keji dinlọgbọn, óṣu June ni ọdun 2005, 1:12.06 ninu idaji marathon ni Addis Ababa to waye ni ọjọ keji dinlọgbọn, óṣu August ni ọdun 2005 ati 2:27.32 ninu marathon to waye ni Rotterdam ni ọjọ kẹtala, óṣu April ni ọdun 2008[5].

Zekiros Adanech
Òrọ̀ ẹni
Ọmọorílẹ̀-èdè Ethiópíà
Ọjọ́ìbí26 Oṣù Kẹta 1982 (1982-03-26) (ọmọ ọdún 42)
Ethiopia
Sport
Erẹ́ìdárayáRunning
Event(s)Marathon

Àṣèyọri

àtúnṣe

Ni ọdun 2004 ti idije IAAF agbaye idaji marathon, Adanech pari pẹlu ipó kẹrin dinlogun ni 1:13:50. Lẹyin ti arabinrin naa fojusi ere sisa ti 10,000 metres ati idaji marathon fun igba ibẹẹrẹ iṣẹ rẹ, Adanech foju si marathon odidi ni ọdun 2005. Ni ọdun 2006, Adanesh pari pẹlu ipo kẹjọ ni marathon ti Berlin ni 2:36:48 ati ipo kẹta ni marathon ti Rome to waye ni ọdun 2006 ni 2:27:38[6]. Ere sisa to ṣè pataki ti Adanech kopa ninu rẹ ni Marathon ti Rotterdam ti ọdun 2008 to si pari pẹlu ipo keji[6].

Itọkasi

àtúnṣe
  1. Adanech Zekiros of Ethiopia repeated as the women's champion in a course-record 2:31:14.
  2. Adanech Zekiros
  3. Ethiopia’s Adanech Zekiros wins the Arizona Marathon
  4. Adenech ZEKIROS Profile
  5. Women's Half Marathon
  6. 6.0 6.1 Marathon Records