Adaora Onyechere
Adaora Onyechere jẹ́ oniroyin, oníṣòwò, akéwì àti onkọ̀we ni ìlẹ̀ Nàìjíríà. Òun sì ní atọkun ètò tẹ́lẹ̀ fún ètò Kakaaki, lórí Africa Independent Television.[1] Òun sì ní atọkun ètò Talk 2 Adaora lórí Kiss Fm ni gbogbo ọjọ́ ìṣẹ́gun ní ago mẹrin ìrọ̀lẹ́. Òun ni oludasile ẹgbẹ́ Women Enabling Women Everywher (WEWE).[2] Òun náà ni olùdarí signature heels media.
Adaora Onyechere | |
---|---|
CEO Wewe Network Afrique | |
Ọjọ́ìbí | Okigwe, Imo State |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iléẹ̀kọ́ gíga | |
Iṣẹ́ |
|
Gbajúmọ̀ fún | co-anchor of Kakaaki, a daily talk show on Africa Independent Television |
Title |
|
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeWọn bíi sì ilẹ̀ Nàìjíríà, ó sì jẹ ọmọ ìlú Okigwe ni ìpínlè Imo. Adaora jẹ́ àkọ́bí láàrín àwọn ọmọ mẹ́fà tí àwọn òbí rẹ bí.[3] Adaora lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Starland Private School ni ìpínlè èkó fún ẹ̀kọ́ ìbéèrè. Ó lọ sí Owerri Girls Secondary School. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Coventry University níbi tí ó tí ká ìwé imọ òfin. Ó tún lọ sí London Metropolitan University àti Oxford Brooks University.[4]
Ìṣe
àtúnṣeKí ó tó padà sí ilé Nàìjíríà ni ọdún 2009, Adaora sisẹ́ fún World view magazine ni ilé United Kingdom.[5] Adaora ṣe agbóhùnsáfẹ́fẹ́ fún Coventry Student Radio ni ìgbà tí ó sì jẹ akẹ́kọ̀ọ́ ni ilé ẹ̀kọ́ náà kì ó tó padà lọ ṣíṣe ni Channel 4 London. Ó sisẹ́ fun Ben Television ni London gẹ́gẹ́ bíi alatunse àti olootu ètò African Film Review. O ṣiṣẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ fún Confluence Cable Network Limited ni ìpínlè Kogi, Federal Radio Corporation of Nigeria, Vision Fm àti DAAR communications.[6][7] Ó dára pọ̀ òṣèlú ó sì dù òye ọmọ ẹgbẹ́ igbimo asofin tí ipinle Imo ṣùgbọ́n kò wọlé.[8][9] Adaora jẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ fún ètò Talk2Adaora lórí Kiss 99.9 Fm. Adaora jẹ́ onkọ̀we, ó sì tí kọ àwọn iwe bíi Poetry for life, Black Girl with a white heart, Women in the world, Arise àti Fear.[10]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Kakaaki. "Adaora Onyechere". Africa Independent Television. Retrieved 15 August 2015.
- ↑ "WEWE NETWORK AFRIQUE". Archived from the original on 1 November 2020. Retrieved 9 April 2020.
- ↑ Yomi Odunuga, Grace Obike (16 May 2015). "Life as a single mother-TV gal Adaora Onyechere". The Nation Newspaper. Retrieved 15 August 2015.
- ↑ Fwangshak Guyit, Naomi Tetteh (29 November 2013). ""I had a speech defect growing up" – AIT’S Ada Onyechere". Garki Gazette. Archived from the original on 5 March 2016. https://web.archive.org/web/20160305144235/http://www.garkigazetteonline.com/content.php?cat_id=5465456576&c_id=30783389&fb_comment_id=388870104580214_2079274#f17bc693a8a9db. Retrieved 15 August 2015.
- ↑ "Adaora Onyechere.". Nigerian Biography. Retrieved 15 August 2015.
- ↑ "‘Kaakaki’ host Adaora Onyechere leaves AIT to Pursue a career in politics". PER SECOND NEWS. 28 August 2018.
- ↑ ENWONGO, ATING (28 August 2018). "Television Queen, Adaora Onyechere Bows Out Of AIT". The Whistler NG.
- ↑ Erunke, Joseph (6 October 2018). "Imo 2019: I'll redesign South East educational curriculum-Onyechere". Vanguard News Nigeria.
- ↑ "Gov. Ihedioha makes more appointments". Daily Post. Retrieved 31 July 2019.
- ↑ "LAUNCH OF ADAORA ONYECHERE’S ‘CHANGE SMITTEN’ IN ABUJA". Photo News. Archived from the original on 2 April 2015. Retrieved 16 March 2015.