Adebáyò Faleti
Adébáyọ̀ Àkàndé Fálétí (wọ́n bí i ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá 1930) jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Akéwì , Olùkọ̀tàn, àti eléré orí-Ìtàgé, bákan náà ni ó tún jẹ́ oǹgbufọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì sí èdè Yorùbá, ó sì tún jẹ́ oníròyìn orí ẹ̀rọ asọ̀rọ̀-má-gbèsì Radio, Olóòtú ètò orí ẹ̀rọ agbóhùngbójìjí TV, àti Olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ ẹ̀rọ agbóhùngbójìjí àkọ́kọ́ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ Afíríkà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Western Nigeria Television (WNTV). [1][2]
Adebayo Faleti | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 26 Oṣù Kejìlá 1930 Kasmo, Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Ibadan, Nigeria |
Iṣẹ́ | Osere, Akewi, Onkowe |
Iṣẹ́ tó yàn láàyò
àtúnṣeFaleti tí kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ fíìmù tí ó sì tún ṣàgbéjáde wọn pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ sì ni ó kópa nínú àwọn fíìmù náà.[3] Bákan náà, ó gbajúmọ̀ fún àwọn ewì rẹ̀. Òun ni olùkọ́ àkọ́kọ́ ní Ife Odan, tó wà nítòsí ìlú Ejigbo ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.[4] Ó fìgbà kan jẹ́ Alákòóso Àgbà ní Broadcasting Corporation of Oyo State (BCOS), èyí tí ó tún ń jẹ́ Radio OYO, Ibadan.[4] Ní ọdún 1959, ó ṣiṣ́ẹ ní Western Nigerian Television (WNTV), èyí tí ó ti wá di NTA Ibadan, gẹ́gẹ́ bí i olùdarí fíìmù àti alákòóso yàrá ìyáwèé-kàwé.[4]
Àwọn iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeFaleti ti kópa nínú eré orí-ìtàgé pẹ̀lú fíìmù àgbéléwò, bẹ́ẹ̀ sì ní ó ti kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ fíìmù tí ó sì tún ṣàgbéjáde wọn pẹ̀lú, lára àwọn fíìmù bẹ́ẹ̀ ni: Thunderbolt: Magun (2001), Afonja (1 & 2) (2002), Basorun Gaa (2004), àti Sawo-Sogberi (2005).[5][6]
Adébáyọ̀ Fálétí náà ló ṣe ògbufọ̀ orin àmúyẹ orílẹ́-èdè Nigeria National Anthem láti èdè Gẹ̀ẹ́sì sí èdè abínibí Yorùbá. Bákan náà ni ó ṣe iṣẹ́ oǹgbufọ̀ fún Ààrẹ orílẹ́-èdè Nàìjíríà nígbà kan rí lásìkò ìṣèjọba àwọn ológun, ìyẹn Ibrahim Babangida bẹ́ẹ̀ ni fún ẹni tí ó ti fi ìgbà kan jẹ́ Ààrẹ-fìdíhẹ Chief Ernest Shonekan nígbà ìṣèjọba àwọn ológun, nípa lílo èdè Yorùbá tó gbámúṣé. Fálétí ti tẹ Ìwé-Atúmọ èdè Dictionary Yorùbá ní èyí tí ó ní àbùdá ògidì Yorùbá nínú. Adébáyọ̀ Fálétí ti gba onírúurú àmì-ẹ̀yẹ ìdánilọ́lá oríṣiríṣi nílẹ̀ yìí àti lókè Òkun pẹ̀lú. [7] [8]
Ọ̀kan lára àwọn ewì rẹ̀
àtúnṣeObìin mẹ́ìndínlógún
N ní ń bẹ́ lọ́ọ̀dẹ̀ẹ Ṣàngó
Ńbi ká sánpá
Ńbi ká yan
LỌyá fi gbọkọ lọ́wọ́ọ gbogbo wọn 5
Ńbii ká sọ̀rọ̀, ká fa kòmóòkun yọ
N la ṣe ń perúu yín léléwì pàtàkì
Fohùn òkè ta ko tìsàlẹ̀ nìkan
Kọ́ là ń pè léwì
Yàtọ̀ sáfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ àti tààrà 10
Òwe tún ń bẹ rẹrẹrẹ
Wọn a sọ̀rọ̀ tó gbayì létè
Wọn a fi wíwúni lórí lé e
Èyún-ùn nìkan kọ́, kò sẹ́ni tí ò mọ̀yún-ùn
Àní níbii ká máṣà ìṣẹ̀nbáyé 15
Kí gbogbo rẹ̀ tún kú dùn-ún-ùn bí ojú afọ́jú
N la ṣe ń peruu wọn ní baba
Ẹni tó mọ̀Bàdàn tán tó tún mọ Láyípo pẹ̀lú ẹ̀
Tó gbégùn tó gbọ́ wọ́yọ̀wọ́yọ̀
Iwájú lọ̀pá ẹ̀bìtì ó kúkú máá ré sí 20
A kò ní í sàìmáa rí yín bá
Àwọn ìwé rẹ̀
àtúnṣe- Basorun Gaa
- Adebayo Faleti (1985) Ogun Àwítélè Ibadan; University Press Limited, ISBN 0-19-575073-X Ojú-iwé 48.
- Adebayo Faleti (1993) Omo Olókùn Esin Heinemann Educational Books (Nigeria) PLC. ISBN 978-129-231-8
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "7 things you probably didn't know about late actor". Entertainment. 2017-07-23. Retrieved 2019-12-15.
- ↑ "Adebayo Faleti: The Passing of a Cultural Icon, By Akin Adesokan". Premium Times Opinion. 2017-09-27. Retrieved 2019-12-15.
- ↑ "Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn Adebayo Faleti, ìran Yorùbá ń ṣe ilédè rẹ!". BBC News Yorùbá. 2020-07-25. Retrieved 2021-09-15.
- ↑ 4.0 4.1 4.2 Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs nameddailynewswatch
- ↑ "Adebayo Faleti". IMDb. 2014. Retrieved 20 June 2014.
- ↑ "Adebayo Faleti". Victola Videos. 2014. Archived from the original on April 7, 2014. Retrieved 20 June 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ PeoplePill (1930-12-26). "Biography, Life, Family, Career, Facts, Information". PeoplePill. Retrieved 2019-12-15.
- ↑ "Ewi Adebayo Faleti-Iwe Kinni By Olatunde O. Olatunji". Sunshine Bookseller. Archived from the original on 2019-12-15. Retrieved 2019-12-15.