Aderemi Adesoji

Olóṣèlú

Adésojí Adérèmí (15 November 18897 July 1980) Titus Martins Adesoji Aderemi Tadenikawo jẹ́ olóṣèlú tó lààmìlaka àti olórí ìlú tíì ṣe Ọọ̀ni Ìlú Ilé-Ifẹ̀ láàárín ọdún 1930 sí 1980. Bákan náà ló ṣe gómìnà apá ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà láàárín ọdún 1960 sí 1962.

Adesoji Tadeniawo Aderemi
size
Governor of Western Region
In office
1960–1967
AsíwájúObafemi Awolowo
Arọ́pòSamuel Ladoke Akintola
Oba of Ife
In office
1930 – 7 July 1980
AsíwájúAdemiluyi Ajagun
Arọ́pòOkunade Sijuwade
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí15 November 1889
Aláìsí7 July 1980

Gbajúmọ̀ Onílé ọlọ́nà ni Adesoji Aderemi tí ó sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyàwó àti ọmọ. Ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ̀ ni òṣìṣẹ́ ìjọba tíì ṣe Tẹjúmádé Alákijà.

Lásìkò sáà ìjọba Ìmúnisìn, Ọba Ọ̀ọ̀ni ní agbára látàrí ètò ajẹmọ́ Ìmúnisìn ìșèjọbà lọ́nà ẹ̀bùrú, tí wọ́n sì ṣà á làmí gẹ́gẹ́ bíi Ọba ààyè onípò pàtàkì láàárín àwọn olórí ìlú ìbílẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá. Ètò ìșèjọbà lọ́nà ẹ̀bùrú wà fún ìtanijí ìbílẹ̀ àti ájùmọ̀sọ̀ nípa àwọn ètò ajẹmọ́ ìmúnisìn tí ó ń ṣe àkóbá fún àwọn agbègbè. Àwọn Bìrìtìkó gùn lé àwọn ihun àti ìpele agbékà ìbílẹ̀ ajẹmọ́ṣèlú tí ó ti wà tẹ́lẹ̀, pàápàá fún àwọn olórí ìlú ìbílẹ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, fún ájùmọ̀sọ̀ ajẹmọ́ṣèlú àti gbígba owó orí. Nígbà tí ó yà, Ọ̀ọ̀ni pẹ̀lú àṣẹ àwọn olórí olóṣèlú aṣáájú ilẹ̀ Yorùbá fi ipò rẹ̀ di àlàfo ìrẹ́jẹ tí ìyapa onípìn-ín láàárin àwọn Yorùbá ó sì gbìyànjú láti mú ìdàgbàsókè bá Yorùbá fún èròngbà kan náà. Ní ọdún 1962, ọba náà gẹ́gẹ́ bí gómìnà wòsọ̀dèmí ló agbára rẹ̀ láti yọ olórí àgbègbè náà, nígbà tí ó kẹ́ẹ́fín pé kò ní àtìlẹ́hìn ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ilé Ìgbìmọ̀ aṣòfin. Ìṣẹ̀lẹ̀ náà padà finá sí orogún ajẹmọ́ṣèlú ní agbègbè náà.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìgbé ayé rẹ̀

àtúnṣe

Ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù Bélú, ọdún 1988 lásìkò rògbòdìyàn ogún Abẹ́lé ilẹ̀ Yorùbá. Ọmọba Osundeyi Gbadebo tí ìdílé ọlọ́ba tí Ilé Ifẹ̀ àti Arábìnrin Adekunbi Itiola tí Ìpetumodù (tí ó jẹ́ ìyàwó kékeré Kọkàndínlógún tí ó kéré jù lọ) ni àwọn òbí rẹ̀. Bàbá rẹ̀ tí kò sí nílé, tí ó wà lójú ogun, ni wọ́n ṣe sọ ọ́ ní Aderemi Adesoji.

Nígbà tí Ọmọba Gbádébọ̀ darí dé, wọ́n ni láti fa Ìbíyẹ̀mí tíì ṣe ẹ̀gbọ́nbìnrin Adésọjí tí kò lè pa  ayọ̀ náà mọ́ra sẹ́yìn kí ó má baà lùgbàdì oògùn aṣààbò ara bàbá rẹ̀. Ìgbà tí bọ̀ gbogbo aṣọ oògùn aṣààbò tí ó sì ṣe ètùtù sí àwọn irúnmọlẹ̀ nígbà náà ni ó tó lè dìmọ́ àwọn ẹbí rẹ̀ láì sí ewu. Ọmọba Gbádébọ̀ tí ó jẹ́ olúáwo gbé ọmọ tuntun lọ sí ìdí ifá láti wo ẹ̀sẹ̀ntáyé ìkókó tíì ṣe Adérẹ̀mí. Wọ́n sọ pé kí bàbá tẹríba fún ọmọ rẹ̀. Ifá sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Adérẹ̀mí yóò dé adé àwọn bàbá ńlá rẹ̀ tí ìgbà rẹ̀ yóò sì gbalé gboko, yóò sì ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn àjèjì láti ọ̀nà jínjìn. Ọmọba Gbádébọ̀ sọ fún ìyàwó rẹ̀ kí ó wá iyùn láti fi múra fùn ọmọ náà torí pé èyí jẹ́mọ àmì ọba. Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú ifá, Adekunbi tíì ṣe ìyá rẹ̀ ń dáàbò bo ọmọ rẹ̀ nípa wíwẹ̀ ẹ́ nínú àgbo títí tí ó fi dàgbà. Bàbá rẹ̀ kú ní 1897 nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́jọ. Torí pé bàbá rẹ̀ tètè kú, ìyá rẹ̀ ló tọ dàgbà.

Ìgbédìde ẹ̀sìn Kìrìsìtíẹ̀nì yí ìyá rẹ̀ lọ́kàn padà kúrò ní ẹ̀sìn ìbílẹ̀ ifá, torí náà ni wọ́n ṣe lọ forúkọsílẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Kìrìsìtíẹ̀nì ìbílẹ̀ tuntun tí St Phillips, Ilé Ifẹ̀, gẹgẹ bí ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àkọ́kọ́ tí yóò lọ sí Iléẹ̀kọ́ ìbílẹ̀ ní 1901.

Ọọ̀ni Ilé-Ifẹ̀ láti ọdún 1930 - 1980

àtúnṣe

Ọmọba náà ní àfojúsùn. títakò tí ó takò láti lọ ṣisẹ́ àgbẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àgbà Ọmọba Adeyemo ló ṣokùnfà ìforúkọ̀sílẹ̀ rẹ̀ ní Iléẹ̀kọ́ Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Anglican ní Ayétòrò Ilé Ifẹ̀. Lábẹ́ ìtọ́ni àti ìlóyetó Revd. Canon J. Adéjùmọ̀ tí wọ́n mọ̀ sí bàbá Ayétòrò tí ó padà di àna rẹ̀. Ó fẹ́ràn iṣẹ́ amòfin, kò bá sì ti rìn ìrìnàjò pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ nígbà náà Bashiru Augusto. Ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ torí pé òun àti àyànmọ́ ní ọ̀rọ̀ ásọtì - Adé Ilé-Ifẹ̀. Pẹ̀lú pé ó tètè pàdánù bàbá rẹ̀, ó mú ìfẹ́ ohun tí ó fé ṣe ní ọ̀kúnkúndùn, kí a dúpẹ́ lọ́wọ́ ìyá rẹ̀ Adekunbi tí kò gbàgbé àsọtẹ́lẹ̀ Ifá.

Ìrírí àti ọlá Ọmọba Adérẹ̀mí ṣọ ọ́ di ọmọ oyè láì sí kọnú-u-kọ́họ lèyí gorí ìtẹ́ ní Ilé Ifẹ̀. Lẹ́hìn tí Ọba Adémìlúyì wàjà, ó di olùdipò  tí ó peregedé láti gorí ìtẹ́.

Lọ́jọ́ kejì, Oṣù Ọ̀wẹ̀wẹ̀, ó di Ọ̀ọ̀ni Ilé - Ifẹ̀ Kọkàndínláàdọ́ta. Òun ni Ọ̀ọ̀ni àkọ́kọ́ tí ó jẹ́ alákọ̀wé. Ọba Adérẹ̀mí tètè faramọlé, ní ọmọ ogójì ọdún, òun ní ọba tí ó kéré jù nínú àwọn ọba ilẹ̀ Yorùbá nígbà náà. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn àgbà ìbílẹ̀ Ifẹ̀(Obalufe, Obajio, Ọbàlọràn, Wasin, Ọbalúayé, Akọgun, Jagunọsìn, Ejesi) wọ́n dá Ìgbìmọ̀ ajẹmọ́ṣàkóso sílẹ̀ tí ó yí ìlú àtijọ́ náà padà ní ọdún mẹ́wàá tó ń bọ̀. Ọba Adérẹ̀mí ṣe agbátẹ̀rù ètò ẹ̀kọ́ lásìkò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọ̀ọ̀ni tí ó sì yọrísí ìdásílẹ̀ Kọ́lẹ́jì Odùduwà ní Oṣù Ṣẹ́ẹ́rẹ́ 1932.[1]

Ọba Adérẹ̀mí ló dá ṣe agbáterù bí wọn ṣe kọ́ Iléẹ̀kọ́ náà, Iléẹ̀kọ́ àwòṣe ni pẹ̀lú nígbà náà; Ìgbàgbọ́ Ọba Adérẹ̀mí ni pé ètò ẹ̀kọ́ ni ọ̀nà kan tí ó dájú láti ṣe ìsọlọ́jọ̀ nǹkan ajẹmọ́-ìgbàlódé.

Lára ìṣẹ̀lẹ̀ gbòógì tó rinlẹ̀ lásìkò rẹ̀ ní ìdásílẹ̀ Yunifásitì Ilé - Ifẹ̀, èyí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ so àṣeyọrí náà mọ̀ ipò Ọba Adérẹ̀mí ni ilé ìjọba. Ọba Adérẹ̀mí jẹ́ Alága Ìgbìmọ̀ àwọn ọba láti ọdún 1966 - 1980.

Àlàáfíà jọba lásìkò tó wà lórí ìtẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀tun èrò tí ó ṣe atọ́nà ọlá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ìlú, pàápàá àwọn tí wọ́n wà ní ẹ̀ka iṣẹ́ àgbẹ̀, níbi tí òhun alára ti jẹ́ olórí okoòwò

Emó kú ojú òpó dí. Afèèbòjò kú, enu isà ń sòfò Ohun Ekùn ti lo. Oba nÍfè Onòni. Ikú ò meni à á pa, òjò ò mẹni ọ̀wọ̀. Òjò ìbá meni òwò ni, Ìbá tí poníSàngó, Ìbá tí POlóya.

Kááábíyèsí!...

  1. Richardson, Derin. Nigeria in Transition: Biography of Sir Adesoji Aderemi, The Oni of Ife(1930-1980). Witherbys. p. 59-62.