Felicial Adetoun Omolara Ogunseye ( ti o je omobibi inu Banjo) ni a bi ni ojo karun un osu kejila odun 1926. Adetoun ni ojogbon obinrin akoko ni orile-ede Nàìjíríà. O je ojogbon onimo ijinle lori ile ikowe pamo si ka (Library and Information Science) ni ile-eko giga ti Yunifasiti ilu Ibadan.[1][2]

Felicia Adetoun Ogunsheye
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí
Felicia Adetowun Omolara Banjo

5 Oṣù Kejìlá 1926 (1926-12-05) (ọmọ ọdún 98)
Ilu Benin, Ipinle Edo
EducationQueen's College, Eko
Yaba College of Technology
Yunifásítì ìlú Ibadan
Yunifásítì ìlú Cambridge
Simmons College
O un tí a mọ̀ ọ́ fúnÒún ni obìnrin àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ dé ipò ọ̀jọ̀gbọ́n

Ibere aye re ati ẹkọ

àtúnṣe

A bi Ogunseye ni ojo karun un osu kejila odun 1926 ni ilu Benin, orile-ede Nàìjíríà. Omo Ipinle Ogun ni awon obi re. O je egbon agba fun ogagun Victor Banjo ati Ademola Banjo. O lo si ile-iwe giga ti Queen ki o to di wipe o lo si koleji ti imo-ero ti o wa ni Yaba (Yaba College of Technology), nibi ti o ti je wipe oun nikan soso ni obinrin ni aarin awon akeko ni odun 1946. Adetoun ni obinrin akoko ti o koko keko gboye dipuloma jade ni ile-eko yi ni odun 1948. O lo si ile-eko giga Yunifasiti ilu ibadan ki o to di wipe o ni anfaani si eko ofe lo si ile-eko giga Newnham ti Yunifasiti ilu Cambridge ni orile-ede Geesi lati lo ko eko lori Geography. O gba oye akoko ti Yunifasiti (Bachellor of Art degree) ni odun 1952 ati oye eleekeji (Masters of Art degree) ni odun 1956 ni sise n tele ni ile-eko giga yi, nibi ti o ti je wipe oun ni obinrin akoko lati orile-ede Naijiria. O gba oye giga ti Yunifasiti eleekeji miran lori imo nipa ikowe pamo si ka lati ile-eko giga ti Simmons, ti o wa ni Massachusetts, USA ni odun 1962.

Adetoun ni o da ile ikawe ti Abadina Media Resources Centre ti o wa ni ile-eko giga Yunifasiti ilu Ibadan sile ni odun 1973. O di ojogbon ni ile-eko giga Yunifasiti ilu Ibadan. Ni Yunifasiti ilu Ibadan yi ni won ti yan an gege bi i oga agba ti eka eko laarin odun 1977 si odun 1979. Oun ni o je obinrin akoko ti won ma a koko yan gege bi oga agba ni ile-eko giga Yunifasiti kankan ni orile-ede Naijiria. O ti sise gege bi i onimoran fun orisirisi ile ise. Lara won ni Ile Ifowopamo ti agbaye (World Bank); International Federation of Library Associations and Institutions (IFLA); UNESCO; International Association of School Librarianship (IASL); International Federation of Documentation (FID) ati British Council.

Awon ola ati iyin ti won bu fun Adetoun

àtúnṣe

Awon ola ati iyin orisirisi ni Adetoun Ogunseye ti gba. Lara won ati odun ti o gba won niwonyi:

  • Ni odun 2000, o gba International Education Hall of Fame ni orile-ede Naijiria.
  • Ni odun 1990, o gba Hon. Doctor of Letters (D.Litt) ti Yinifasiti ilu Maiduguri.
  • Ni odun 1985, o gba iyin ti Nigeria Academic of Education
  • Ni odun 1985, o gba Decade of Women Certificate of Merit for Outstanding Achievement.
  • Ni odun 1982, o je oye Iyalode of Ile-Oluji.
  • Ni odun 1982, o gba Fellow, Nigerian Library Association.
  • Ni odun 1980, o gba Fulbright Fellowship for Senior African Scholars.
  • Ni odun 1979, o gba ami eye ti Simmons College International Alumnus.
  • Ni odun 1969, o gba Hon. D.L.S. of Simmons College.
  • Ni odun 1961, o gba Ford International Fellow.

Ile eko giga Yunifasiti Ibadan tun so gbongan ibugbe kan ti awon omo ile-eko n gbe ni oruko re ni akoko ti ojogbon Abel Idowu Olayinka n se isakoso ile-eko giga Yunifasiti yi.[3]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Sesan (2016-12-07). "Celebrating Prof Ogunsheye at 90". Punch Newspapers. Retrieved 2020-11-04. 
  2. "UI Honours First Female Professor In Nigeria, Names Postgraduate Hall After Her". InsideOyo.com (in Èdè Latini). 2019-08-14. Retrieved 2020-11-04. 
  3. "UI Honours First Female Professor In Nigeria, Names Postgraduate Hall After Her". InsideOyo.com (in Èdè Latini). 2019-08-14. Retrieved 2020-11-04.