Ado-Awaye
Ado-Awaye jẹ́ ìletò tàbí agbègbè kan èyí tí ó wà ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Oyo State, ní orílẹ́-èdè Nàìjíríà Nigeria. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó mọ ìlú yìí káàkiri àgbáyé látàrí àpáta tí ó ń bẹ níbẹ̀ èyí tí ó ní omi adágún. Wọn a máa pe omi adágún inú àpáta yìí ni omi adágún Iyake Iyake lake, èyí tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn omi adágún inú àpáta Suspended lake méjì tí a ní káàkiri gbogbo ayé. Gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó bá jẹ́ arìnrìn-àjò tí ó nífẹ̀ẹ́ láti ṣe ìrìnàjò káàkiri gbogbo àwọn ibi ìyanu, Ado-Awaye jẹ́ ibìkan tí ẹ le fi ṣe àfojúsùn láti mọ̀ nípa ìtàn, àṣà àti ẹwà tí ó sodo sínú ìlú yìí. [1]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "The seven wonders of the mysterious town in Oyo". www.pulse.ng. July 23, 2019.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]