Adolph Zukor
Adolph Zukor ( /ˈzuːkər/; Àdàkọ:Lang-hu; ọjọ́ keje oṣù kíni ọdún 1873– ọjọ́ Kẹ̀wá oṣù kẹfà ọdún 1976)[1] jẹ́ òṣeré ọmọ orílẹ̀ èdè Hungary mọ́ Amẹ́ríkà tí ó gbajúmò gẹ́gẹ́ bi ọkàn lára àwọn mẹ́ta tí ó dá Paramount Pictures kalẹ̀.[2] Ó ṣe àgbéjáde The Prisoner of Zenda ní ọdún 1913.[3][4]
Adolph Zukor | |
---|---|
Zukor in 1922 | |
Ọjọ́ìbí | Ricse, Kingdom of Hungary, Austria-Hungary | Oṣù Kínní 7, 1873
Aláìsí | June 10, 1976 Los Angeles, California, U.S. | (ọmọ ọdún 103)
Resting place | Temple Israel Cemetery, Hastings-on-Hudson, New York |
Orúkọ míràn | Adolf Zuckery |
Iṣẹ́ | Film producer |
Ìgbà iṣẹ́ | 1903–1959 |
Gbajúmọ̀ fún | One of the three founders of Paramount Pictures |
Olólùfẹ́ | Lottie Kaufman (m. 1897–1956) |
Àwọn ọmọ | 2 |
Ẹbí | Marcus Loew (daughter’s father-in-law) |
Signature | |
Ìpìlẹ̀
àtúnṣeA bí Zukor sínú ìdílé Ashkenazi Júù ní Ricse, nínú Ìjọba Hungary ní oṣù kíní ọdún 1873, Ìjọba Hungary jẹ́ ara ìjọba Austro-Hungarian nígbà náà. Bàbá rẹ̀, Jacob, tí ó ń ṣiṣẹ́ nílé ìkọ́jà sí kan, fi ayé sílẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún kan, Ìyá rẹ̀, Hannah Liebermann, sì fi ayé sílẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún méje. Adolph àti arákùnrin rẹ̀, Arthur kó wọlé pẹ̀lú Kalman Liebermann, arákùnrin bàbá wọn. Liebermann, ẹni tí ó jẹ́ rabbi, ní ìrètí pé Adolph àti arákùnrin rẹ̀ ma di rabbi, ṣùgbọ́n Adolph kọ́ iṣẹ́ ní ilé ìkọ́jà sí kan. Nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún 16, ó pinu láti kó lọ sí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.[3][4] Ó rírìn àjò rẹ̀ láti Hamburg lórí s/s Rugia ní ọjọ́ kíní oṣù kẹta[5] ó sì wọ New York City pẹ̀lú orúkọ Adolf Zuckery ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹta ọdún 1981.[6]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Bernstein, Matthew (February 2000). Zukor, Adolph. Oxford University Press.
- ↑ Obituary Variety (June 16, 1976), p. 76.
- ↑ 3.0 3.1 Krebs, Albin (June 11, 1976). "Obituary: Adolph Zukor Is Dead at 103; Built Paramount Movie Empire". The New York Times. https://www.nytimes.com/learning/general/onthisday/bday/0107.html.
- ↑ 4.0 4.1 Krebs, Albin (June 11, 1976). "Adolph Zukor Is Dead at 103; Built Paramount Movie Empire". The New York Times. https://www.nytimes.com/1976/06/11/archives/adolph-zukor-is-dead-at-103-built-paramount-movie-empire-adolph.html.
- ↑ Passenger list. "Ancestry. Com". Ancestry.com.
- ↑ 1891 passenger list. "Ancestry.com". Ancestry.com.