Adora Oleh, jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Bírítìṣì olóòtú telifísàn àti olóòtú àkọ́kọ́ tí MTN project fame, èyí tí ó ṣe olóòtú rẹ̀ fún ọdún márùn-ún. Ni ọjọ́ Àìkú 8 oṣù kejìlá ọdún 2013, Adora Oleh ní ó gba àmì ẹ̀yẹ fún olóòtú obìnrin tó gbajúmò ní Nigeria Broadcasters Awards èyí tí ó wáyé ní ìlú Èkó. Ó jé olóòtú fún ètò ìbáni wírọ̀ rẹ "The Adora Oleh show" lóri Vox Africa.[1][2]

Adora Oleh
Ọjọ́ìbíSurrey, England
Orílẹ̀-èdèNigerian
Ẹ̀kọ́London School of Journalism
Iṣẹ́Journalist, TV Presenter, Model
Gbajúmọ̀ fúnHosted Project Fame West Africa
Olólùfẹ́Single
Websitehttp://adoraoleh.com/

A bí Adora Oleh ní Surrey, England ó jẹ́ àkọ́bí nínu àwọn ọmọ mẹta tí òbí rẹ bí. Ó kà ìwé gboyè nínu ìmò òfin ní unifasiti ó sì gba iwe ẹ̀rí ni ìmò òfin ayélujára àti ìgbóhùn sí afẹ́fẹ́ ni London school of journalism.[3]

Ó ṣiṣẹ́ ní MTV Base ní ọdún 2002. Pẹ̀lú Joseph Benjamin, ó ṣe olóòtú fún Project Fame West Africa, èyí tí ó jẹ́ ìdíje orin orí ẹ̀rọ̀ amóhùn-máwòrán fún ọdún márùn-ún. Ní ọdún 2012, Adora farahàn gẹ́gẹ́ bíi olóòtú lórí ètò American TV lóri ìròyìn Fox.

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Ononye, Ifeoma. "Modelling Has Been Steady Part Of My Career – Adora Oleh". DAILY INDEPENDENT. https://www.independent.ng/modelling-has-been-steady-part-of-my-career-adora-oleh/. 
  2. Emea, Agatha. "Nigeria: I Am Living my Dream – Adora Oleh". All Africa. All Africa. Retrieved 10 May 2020. 
  3. Bellanaija.com. "Adora Oleh, Uti Nwachukwu, Karen Igho & Toke Makinwa at the 2013 Nigerian Broadcasters Merit Awards in Lagos". Bellanaija.com. https://www.bellanaija.com/2013/12/adora-oleh-uti-nwachukwu-karen-igho-toke-makinwa-at-the-2013-nigerian-broadcasters-merit-awards-in-lagos-full-list-of-winners/.