Àdúgbò Èkó, Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà

Eko

+EKO-LAGOS

àtúnṣe
  1. .1Adúgbò: Fastac Town

Ìtumò: Agbègbè yí jé ibi tí àwon ará ìlú orísirísi latí orílè èdè káàkiri gbé ní gbà a ayeye yí ní 1977 (Festival of Arts and culture).

  1. .2Adúgbò:Iyana-Iba

Ìtumò: Ibí yí jé agbègbè tí àown Ìbàrì bà ńgbé, nítorínáà ni wón fi pèé ní Ìyànà-Ibà.

  1. .3Adúgbò:Abule-Ijesha

Ìtumò: Abúlé –Ìjèsà ni apá ibi tí àwon ìjèsà kókó pò sí ní èkó, èyí ni ìdí tí ó fi ńjé Abúlé-Ìjàshà.

  1. .4Adúgbò:Mile 2

Ìtumò: Ìdí tí a fí só ní mile 2 nìípé máìlì méjì ni ókù láti ibè sí ìbi tó ńjé Tincan-Island.

  1. .5Adúgbò:Kosoko-Road

Ìtumò: Ibí ni ówà nínú Èkó, orúko yí ni orúko Oba Èkó níìgbà tó tipé, sùgbó orúko rè ni wón fi so agbègbè yí tí ó ńjé kòsókó road.

  1. .6Adúgbò:Tafa Balewa square

Ìtumò: Orúko ènìyàn Tàfá Bàléwà, eni náà jé lára àwon tí ó ti jé ààre orílè wa, lé yìn ikú rè ni wón fi so ibè ní Tàfá Bàléwà “Square”.

  1. .7Adúgbò:Technology Road

Ìtumò: Technology Road, ìdí tí wón fi só ní oruko yi nípé, Yaba Technology kò jìnà sí ibè rárá, ìdí náà ni wón fi soóní Technology Road.

  1. .8Adúgbò:Kéke

Ìtumò: Ní agbègbè yí enìkan péré ni óní kéké sùgbón nítorí èyí ni won fi so ibè ní kèké, sùgbón ní ìgbà tí àwon òyìnbó fid é ní wón só di kéké.

  1. .9Adúgbò:Herbert Macanlay way:

Ìtumò: Orúko èyàn ni óún jé Herbert macanlay, eni yì jé okan lára àwon òyìbó tí wón wá sí orílè èdè yí, nítorí èyí ni wón fi só ní Herbert macaulay way.

  1. .10Adúgbò:Maryland

Ìtumò: Ní ìlú Èkó ìdí tí wón fi só ní Maryland nipé, orúko aya oba ìlú òyinbó ni Mary, ìdí èyí ni a fi só ní Maryland.

  1. .11.Adúgbò:Masamasa

Ìtumò: Èdè yí ni èdè àwon haúsá, ìtumò rè sì ni kíá-kíá, àwon Haúsá ni wón pò sí ibí yìí jù, ní-ìgbà tí wón tèdó tí bè wón kò mò bí wón áse bá àwon èèyàn sòrò, sùgbón nínú ìwònba ìgbà tí wón ń tajà èdè won ni másámásá, ìdí ètí ni wón fi só ní másámásá-kíá-kíá.

  1. 12.Adúgbò:Cocoanut Village

Ìtumò: Ìdí tí wón fi só ní “coconut village” niípé omi pò ní ibè gan, àti cocoanut (àgbon). O wa ni agbègbè Ajégúnlè.

  1. 13.Adúgbò:Ajegunle

Ìtumò: Ajégúnlè jé ibi tí wón ti ń ra jà àti ta jà ní Èkó, àti wípé ibè jé lára ibi tìí àwon èèyàn pòsí ní ìlú Èkó, ojà títà sì ń lo déédéé tí aje ati owó dè tińwolé nígbà náà, ìdí náà ni ófinjé Ajégúnlè.

  1. 14.Adúgbò:Pen-Cinema

Ìtumò: Èyí jé orúko agbègbè kan ní ìlú Agége cinema ńlá kan ní ó wà ní ibè, tí wón pè ní PEN-CINEMA.

  1. 15.Adúgbò:Ìdúmotà

Ìtumò: Ibí ni won sin àwon Ológun tí wón ti won ti kú, wón sìn o àre ńlá kan sí bè tí ó je sójà ológun.

  1. 16.Adúgbò:Ilú-ńlá

Ìtumò: Ilú yíì wà ní agbègbè Àpápá ní Èkó, ìlú ńkí jé ibi tí àwon èèyàn pò si, tí àwon sì gbèrò sí gan.

  1. 17.Adúgbò:Tincan-Island

Ìtumò: Ibì jé agbègbè tí àwon custom pò sí, ibè sì ni ibi tí àwon erù sì pò sí àti àwon kòntánà idí èyí ni wón fi pèéní Tincay-Island.

  1. 18.Adúgbò:Volkswagen

Ìtumò: Agbègbè èyí ní Èkó ni ilé-isé ibi tí wón ti ń se àwon Okò Volkswagen.

  1. 19.Adúgbò:Aluminum Village

Ìtumò: Agbègbè yí ni ówà ní Dòpèmú ní ìlú Èkó, ibè ni àwon ohun ìkólé yìí pò sí (aluminum) ìdí náà ni wón fi ń pèé ní aluminum

  1. 20.Adúgbò:Port Way

Ìtumò: Agbègbè yí ni wón ti má n já erù tí óún bò láti òkè-ògun àti èyí tí wón bá fé gbé jáde, ìdí èyí ni a fi ń pèé ní “port’

  1. 21.Adúgbò:Lekki

Ìtumò: Lékki jé ibi tí wón kó àwon eléwòn sí ìdí yìí ni wón fi ń pèéní Lékkí.

  1. 22.Adúgbò: Abule-Osun

Ìtumò: Abúlé òsun jé lára ibi tí àwon abò-òrìsà òsun pó sí ní ìlú Èkó èyí ni wón fi só ní Abúlé-òsu, àti pé omí pò ní bè lópòlópò.

  1. 23.Adúgbò:Kirikiri

Ìtumò: Kiríkirì ni ibi tí àwon eléwòn má n gbéé kiríkirì sì jé lára, ilé èwèn tí ó tóbí jù, nítorí è ni wón fi ń péè agbègbè náà ní kiríkirì.

  1. 24.Adúgbò:Abule-Ado

Ìtumò: Abílé-Àdó jé lara ibi ti awon àlàdó pos i ni aiye atijo ni ilu Eko opolopo ni ko mo ibe nitori ise ti won nse ni ibe.


  1. 25.Adúgbò:Satellite Town

Ìtumò: Eyi je ibi ti nkan alaworan yip o sin i ilu Eko, nkan ti ounje “satellite” nitori náà ni won fi pee ni “Satellite Town”.

  1. 26.Adúgbò:Saw-Mill

Ìtumò: saw mill jé lára àwon agbègbè tí ó tóbi jù tí wón ti máa n se ìtójú igi tí a fin kólé ìdí náà ni ó finjé saw-mill.

  1. 27.Adúgbò: Sabo

Ìtumò: Ibi agbègbè ni ibi tí a ti má n rí àwon Haúsá tí wón pò sí jù ní agbègbè tàbí ìlú.

  1. 28.Adúgbò:Salvation Avenue

Ìtumò: “Salvation Avenue” je ibi ti awon elesin Christi posi “choistians”, ibi ti awon elesin bas i posi igbala ni won ma n pariwo (salvation) idi ti won fi n pe ni “salvation Avenue”

  1. 29.Adúgbò:Idi-Araba

Ìtumò: Idi-Ararba yi je ibi ti idi araba po si lopolopo, agbegbe náà ko jina si mushin ni ìlu Eko. adugb bariga