Àgbọ́wá-Ìkòsì jẹ́ ìlú ìṣẹ̀mbáyé kan ní ìpínlẹ̀ Èkó ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Lára ohun tó ṣe iyebíye nípa ìlú yìí ni pé; ojú-ọ̀nà wọn ló jẹ́ èkejì nínú àwọn ojú pópó tí wọ́n lo ọ̀dà tó dára jù láti fi tẹ́ ẹ.

Agbègbè kan ti wọ́n ń pè ní Egunbaṣewo ní Àgbọ́wá-Ìkòsì ti ṣẹ̀ wá. A pín ìlú náà sí àwọn agbègbè tó pọ̀, bíi;(Itún); Aledo, Oríwù, Àgbọ́wá, Kòsómi ati Ẹhindi. Olórí Itún ló n ṣàkóso ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn agbègbè wọ̀nyí, àti pé Olórí Ìlú gan-an ni agbègbè kọ̀ọ̀kan maá ń pe adarí wọn. Ìgbà tó yá ni wọ́n sọ ipò aṣáájú yìí di Baálẹ̀ àti Ọba.

Lọ́dún 1956, Aláyélúwà, Ọba Edward Aláúsá Thomas OLÚFUWÀ ni wọ́n gbé adé lé lórí, gẹ́gẹ́ bíi ọba àkọ́kọ́ nílùú Àgbọ́wá-Ìkòsì, láti agboolé Ògúntólú-Olúfuwà. Àwọn agboolé márùn-ún ni wọ́n ṣàdéhùn pé áwọn yóò máa jọba nílùú ọ̀hún. Ṣùgbọ́n Baálẹ̀ ló n ṣàkóóso àwọn ìgbèríko tó yí i ká, bíi; Ìkòsì, IGBENE, Oko-Ito, Òkè-Olisa, Gbẹ̀rígbẹ̀ àtàwọn yóokù. Gbogbo àwọn baálẹ̀ náà ni wọ́n maá n waá jábọ̀ fún Ọba Àgbọ́wá-Ìkòsì, (ìyẹn Abọ́wá tìlúu Àgbọ́wá-Ìkòsì). Àwọn olóyè kan náà wà tí wọn n ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Abọ́wá, ṣùgbọ́n ìpele-ìpele la tò wọ́n sí. Fún àpẹẹrẹ, Olóyè Olísà, oùn ni igbákejì Ọba. Bẹ́ẹ̀ ni Olóyè Àró, Olúwo, Ọ̀dọ̀fin àti Balógun.

Lásìkò ogun, ìlú Àgbọ́wá-Ìkòsì ni olú agbègbè ìjọba Ìkòsì, èyí tí wọ́n pè ní Ìkòsì District Council. Ibẹ̀ ni ibùdó tí àwọn eèyàn n farapamọ́ sí, pàápàá lati Ìmọ̀ta, Ìbẹ̀fun, Ọ̀tà ati Òwu. Àgọ́-Ìmọ̀ta làwọn ará Ìmọ̀ta farapamọ́ sí ní tiwọn, àwọn ará Ìbẹ̀fun farapamọ́ sí Àgọ́-Ìbẹ̀fun, àwọn ti Ọ̀tà farapamọ́ sí Àgọ́-Ọ̀tà bẹ́ẹ̀ làwọn ara Òwu farapamọ́ sí Àgọ́-Òwu. Gbogbo àwọn ogúnléendé yìí ló padà sí ìgbèríko wọn lẹ́yìn ogun. Ṣùgbọ́n àwọn kan dúró, wọn kò padà, àfi àwọn ará Òwu (Jagun-jagun ni ọ̀pọ̀ wọn), ṣùgbọ́n wọ́n ṣèlérí fún àwọn ará Agbọ́wá-Ìkòsì pé àwọn kò ní yọ wọ́n lẹ́nu rárá.

Nípa ìlú náà

àtúnṣe

Kilómítà márùndínlógójì, ni ìhà àríwá agbègbè Ẹ̀pẹ́ ní ìlú Àgbọ́wá-Ìkòsì wa, ó tún wà ní àríwá lẹ́bàá odò títí dé ibi tó fi lọọ fi ẹ̀gbẹ́ k'ẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú odò ọ̀sà l'Ékòó àti odò Ìkòròdú, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ìlú àtàwọn àlejò ni wọ́n jọ n gbé pọ̀ nínú ìlú Àgbọ́wá-Ìkòsì.   

Lára àwọn ìlú tó súnmọ́ Àgbọ́wá-Ìkòsì ni: Ọ̀tà-Ìkòsì, Òkun Ìkòsì, Òrúgbó-Ìddó, Ìgbálú, ÌGBẸ́NẸ́, Òkè-Olísà, Gbẹ̀rígbẹ̀, Òkò-Ito, Ìmọ̀pé, Ìmọ̀ta, Odò Àyándelú Adó-Ìkòsì, Òwu, Ìgánké àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Àwọn ayẹyẹ

àtúnṣe

Àgbọ́wá-Ìkòsì ni àkọ́kọ́ nínú àwọn ìlú tó wà lágbègbè Ẹ̀pẹ́ àti ilẹ̀ Ìjẹ̀bú tó ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ lati máa ṣayẹyẹ ìlú náà ati ọjọ́ tí wọ́n fi n rántí àwọn ọmọ ìlú. Ọjọ́ náà ni wọ́n n pè ní Ọjọ́ Àgbọ́wá, ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ìlú tí wọ̀n pé ní Àgbọ́wá Development Association (ADA)ló n ṣagbátẹrù rẹ̀.

Ohun tó yẹ ká mọ̀ nípa ìlú náà

àtúnṣe

Àwọn mẹ́rin ló ti jọba ìlú Àgbọ́wá-Ìkòsì:


Ọba Eeward Aláúsá Thomas OLÚFUWÀ wà lórí ìtẹ́ láti ọdún 1956 sí 1972

Ọba Ahmed Kọ́láwọlé Hassan wà lórí ìtẹ́ láti ọdún 1973 sí 2006

Ọba Akinlolú Bọ́lájí Joseph Odùmẹ́ẹ́rù náà wà lórí ìtẹ́ láti ọdún  2007 sí 2012

Olóyè Shakirudeen Odùfowórà, Oùn ni adelé láti ọdún 2012 títí di àkókò yìí

Ọrọ̀ ajé

àtúnṣe

Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ìlú Àgbọ́wá-Ìkòsì ni wọ́n jẹ́ àgbẹ̀ tí àwọn kan sì n ṣiṣẹ́ apẹja, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n tún fi àwọn òwò pẹ́pẹ̀pẹ́ mi in kún un.

Ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn

àtúnṣe

Ẹ̀sìn Krìstẹ́nì, mùsùlùmí àti tí àbáláyé làwọn ọmọ́ Àgbọ́wá-Ìkòsì maá n ṣe jù.

Atóka sí

àtúnṣe