Ahmad Ali Al-Mirghani (Lárúbáwá: أحمد الميرغني‎; ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹjọ ọdún 1942 – ọjọ́ kejì oṣù kọkànlá ọdún 2008) jẹ́ olóṣèlú ọmọ orílẹ̀ ède Sudan nígbà ayé rẹ̀, òun ni ẹni kẹta láti gun orí àléfà ipò ààrẹ orílẹ̀ Sudan (láàrin ọdún 1986 sí 1989), ìsèjọba rẹ̀ wá sópin nígbà tí Omar al-Bashir dìtẹ̀ gba ìjọba lọ́wọ́ rẹ̀.[1][2]

Ahmad Al-Mirghani
أحمد الميرغني
Fáìlì:Mirghani.gif
3rd President of Sudan
In office
6 May 1986 – 30 June 1989
DeputyAbd al-Rahman Saeed
AsíwájúAbdel Rahman Swar al-Dahab as Chairman of the Transitional Military Council
Arọ́pòOmar al-Bashir
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí(1942-08-16)Oṣù Kẹjọ 16, 1942
Khartoum North, Anglo-Egyptian Sudan
AláìsíNovember 2, 2008(2008-11-02) (ọmọ ọdún 66)
Alexandria, Egypt
Ẹgbẹ́ olóṣèlúDemocratic Unionist Party
Àwọn ọmọ3
ReligionSunni Islam

Ìpìlẹ̀ rẹ̀

àtúnṣe

Al-Mirghani wá láti ìdílé Mirghani, ọkan lára àwọn ìdílé tí ó níyì ní Sudan, ọkàn lára àwọn baba ńlá rẹ̀ sì ni Al Sayyid Mohammed Uthman al-Mirghani al-Khatim. Ahmad Al-Mirghani di ipò Sayyid mú,[3] èyí tí ó fi hàn pé a kà á gẹ́gẹ́ bi ọkan lára ọmọ ìdílé Wòlí Muhammad. Ó kàwé gboyè ní Yunifásítì London kí ó tó padà sí orílẹ̀ ède Sudan.

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Ahmed al-Mirghani, Ex-Leader of Sudan, Dies at 67" (in en-US). The New York Times. Agence France-Presse. 2008-11-05. ISSN 0362-4331. https://www.nytimes.com/2008/11/05/world/africa/05mirghani.html. 
  2. "Ahmed al Mirghani: Democratic Sudanese President" (in en). The Times. ISSN 0140-0460. https://www.thetimes.co.uk/article/ahmed-al-mirghani-democratic-sudanese-president-ckd9z9w5vtj. 
  3. "Shajara-e-nasab lineages of descendants of Imam Hasan al-Askari r.a.-Shajara.org" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2020-07-03. Retrieved 2020-06-29.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)