Akínwùmí Iṣọ̀lá
Ọ̀jọ̀gbọ́n Akínwùnmí Ìṣọ̀lá ni a bí ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣùkejìlá, ọdún 1939 tí ó sì tẹ́rí gbaṣọ ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejì, ọdún 2018.(24 December 1939[1][2] – 17 February 2018) ni ó jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èd̀e Nàìjíríà, ó sì tún jẹ́ olùkọ̀tàn, òṣèré-orí-ìtàgé, olùgbáṣà lárugẹ àti onímọ̀ ìjìnlẹ̀. Ó di ìlú-mọ̀ọ́ká jákè jádò àgbáyé fún ìmọ̀ ìṣowọ́ kọ̀wé rè àti bí ó ṣe ń gbé àṣà pàá ̀paá Yorùbá lárugẹ.[3]
Ìtàn ayé rẹ̀ àti àwọn iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣewòn bí Ìṣọ̀lá ní ìgboro ìlú Ìbàdàn Ibadan, Oyo State ní ọdún 1939, ó sì lọ sí ilé ìwé alákọ̀ọ́-bẹ̀̀rẹ̀ Lábọ̀dé Methodist School àti ilé ìwé gíga ti Wesley College. Bákan náà ló tún lọ sí ilé ẹ̀kọ́ àgbà ti ìlú Ìbàdàn University of Ibadan, níbi tí ó ti gba oyè B.A. nínú ìmọ́ èdè Faranse French. Bákan náà lo tún kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú lítíŕeṣ̀ọ èdè Yorùbá ní ilé ẹ̀kọ́ àgbà ti ìlú Èkó University of Lagos ní ọdún 1978 ṣáájú kí ó tó bẹ̀rẹ̀ iṣé gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ti Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ University ní Ilé-Ifẹ̀. [4]
Wọ́n fun ọ̀jọ̀gbọ́n Akínwùmí Ìṣ̀ọlá ní oyè ọ̀jọ̀gbọ́n ní Ilé-ifẹ̀ bákan náà ní ọdún 1991 gẹ́gẹ́ bí àmì ìdánimọ̀ fún iṣẹ́ rẹ̀ kan eré ónise ońitàn kan tí ó kọ́kọ́ kọ ní ọdún 1961 sí 1962 ìyẹn Ẹfúnṣetán Aníwùrà,[5] nígbà tí ó wà ní akẹ́kọ̣̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ àgbà ti Ìbàdàn. Lẹ́yìn èyí ni ó kọ ìwé eré oníṣe Ó Lekú ní ọdún 1986, òun ni ó tún kọ orin ìwúrí ilé-ẹ̀kọ́ ná̀a tí wọ́n ń kọ nilé ẹ̀kọ́ náà títí dòní ni Fásitì Ìbàdàn.
Lẹ́yìn àwọn ìwé ̀itàn àr̀osọ òkè wọ̀nyí, ó tún tẹ̀ síwájú láti kọ onírúurú àwọn ìwé eré onítàn, eré oníṣe, ìtàn ọlọ́rọ̀ geere àti oríṣiríṣi àwọn ìtàn akọni ìgbà ìwáṣẹ̀. Bákan náà lótún pẹ̀ka dé ilé iṣé ìwé ìròyìn tí ó sì tún ní ilé iṣẹ́ tí ó ń gbé onírúurú àwọn ìtàn eré oníṣe tí ó ti kọ jáde sí sinimá àgbéléwò. Ẹ̀wẹ̀, Ìṣọ̀lá kò ṣàì kọ ọlọ́kan ò jọ̀kan ìtàn ní ̀edè gẹ̀ẹ́sì tí ó sì tún ṣògbùfọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àpilẹ̀kọ ní èdè Gèẹ́sì English si ede abinibi re tii se ede Yoruba. Bi o tile je pe o ni : "afojusun apileko oun yoo da le àwujo Yoruba.[6]
Ní ọdún 2000, wón fi àmì ẹ̀yẹ (National Merit Award and the Fellow of the Nigerian Academy of Letters da lọ́lá fún iṣ́ẹ ribi ribi rẹ̀. Bákan náà ló tún jẹ́ olùkọ́ alábẹ̀wò sí ilé ìwé ẹ̀kọ́ àgbà ti ilẹ Jọ́gíà University of Georgia.[7]
Àwọn ẹbí rẹ̀
àtúnṣeAkínwùnmí Ìṣọ̀lá fẹ́ ̀iyàwó tí ó sì bímọ mẹ́rin.[8]
Ìpapòdà rẹ̀
àtúnṣeAkínwùnmí Ìṣọ̀lá kú nínú ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejì ọdún 2018, ti wón sì sín sí Ìbàdàn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ọmọ ọdún méjìdínlọ́gọ́rin (78) ni Ìṣọ̀lá ṣáájú ikú rẹ̀.[9]
Àwọn ìtọka sí
àtúnṣe- ↑ Nichols, Lee (20 February 1981). "Conversations with African Writers: Interviews with Twenty-six African Authors". Voice of America – via Google Books.
- ↑ "Google Groups". groups.google.com.
- ↑ Chima Anyadike; Kehinde Ayoola. Blazing the Path: Fifty Years of Things Fall Apart. African books Collective. ISBN 978-9-78-081-18-46. https://books.google.com.ng/books?id=bG77sRtJt4cC&pg=PP21&lpg=PP21&dq=akinwumi+isola+translator+english+yoruba&source=bl&ots=p8iadLa3nn&sig=0Q98glxXzRYeD5_XiGqkkqvk31g&hl=en&sa=X&ei=fpDMVOVozuOwBPibgIAP&ved=0CDkQ6AEwCTgK. Retrieved 31 January 2015.
- ↑ "Akinwunmi Isola (1939-2018)". The Sun Nigeria. 2018-03-03. Retrieved 2022-12-04.
- ↑ "I misrepresented Efunsetan Aniwura in my book". The Punch. Archived from the original on 8 August 2014. Retrieved 6 August 2014.
- ↑ PEN America 13: Lovers. PEN America Center. https://books.google.com.ng/books?id=HoP6dxyWPvAC&pg=PA217&lpg=PA217&dq=akinwumi+isola+translator+english+yoruba&source=bl&ots=kIXXMRiC-q&sig=DeTJU0sp2-Fp0BhD3D6nTz7p12A&hl=en&sa=X&ei=fpDMVOVozuOwBPibgIAP&ved=0CDYQ6AEwCDgK. Retrieved 31 January 2014.
- ↑ "Citation on Professor Akinwunmi Isola" (PDF). Nigerian National Nerit Award. Archived from the original (pdf) on 30 November 2016. Retrieved 19 February 2018.
- ↑ https://www.vanguardngr.com/2018/03/akinwunmi-isola-life-times-pioneer-yoruba-classical-literature/
- ↑ "Professor Akinwunmi Isola is dead". Lailasnews. Archived from the original on 17 February 2018. Retrieved 17 February 2018.