Akanlo-ede
Àkànlò-èdè ni ìpèdè tàbí ìṣòro ni ṣókí ṣókí tí ó kún fún ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ìtumọ̀ rẹ̀ sì farasin. A ma n fi àkànlò-èdè ṣe àgbékalẹ̀ ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ sínú gbólóhun kan ni ṣókí nínú èdè Yorùbá.[1] Àkànlò-èdè jẹ́ lílo ọ̀rọ̀ tàbí awẹ́-gbólóhùn lọ́nà tó jinlẹ̀ tí ìtumọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ sí ìtumọ̀ òrèfé. Oun ni ìpèdè tí gbólóhùn inú rẹ̀ kò ní ǹǹkankan ṣe pẹ̀lú ìtumọ̀ rẹ̀.
Ìwúlò rẹ̀
àtúnṣeÀkànlò-èdè wúlò púpọ̀ fún elédè Yorùbá l'ọ́pọ̀lọpọ̀ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ pẹ́ ọ̀rọ̀ kan sọ. Àpẹẹrẹ:
- Júbà ehoro
- Gbèkurujẹ l'ọ́wọ́ ẹbọra
- Ṣe àyà gbàngbà
- Fárígá
- Fi àáké kọ́rí
- F'apá jánú
- Jẹ orí ahun [2] atbbl.
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Figure Of Speech". Lexico Dictionaries | English. Archived from the original on 2021-04-12. Retrieved 2019-09-18.
- ↑ "Akomolede BBC Yoruba: Ìtúmọ̀ Àkànlò èdè àti ìwúlò rẹ̀ lóde òní". BBC News Yorùbá. 2021-04-06. Retrieved 2024-01-21.