Akon Etim Eyakenyi (tí a bí ni 24 February 1960 ni Urue-Offong/Oruko, Nàìjíríà) je òtòkùlú olósèlú ní Naijiria.[1] Òun ló ún se asoju Akwa ibom South senetorial District ti ìpinlè Akwa Ibom ní ilé igbimo asofin àgbàa.[2] Wón diboyan sí ipo náà ní odun 2019. [3] O jawe olúborí pẹlu ibo 122,412 lapapo. Kí o to di pe ayan sí ipò Senato, o jẹ minisita teleri fun eto ilé, ilè ati idagbasoke ilu labé ijọba Aare Goodluck Ebele Jonathan. [4]

Akon Etim Eyakenyi
Minister of Lands, Housing and Urban Development
In office
2010–2015
Senator representing Akwa Ibom South senatorial district
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
2019
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí24 Oṣù Kejì 1960 (1960-02-24) (ọmọ ọdún 64)
Urue-Offong/Oruko, Akwa Ibom State, Nigeria

Àárò ayé àti èkó rè

àtúnṣe

A bi Eyakenyi ni 1960 si inú idile Oloye Uweh Isangedihi ni agbegbe ìjoba Urue-Offong/Oruko ti Akwa Ibom. Ni ọdun 1968 o lọ si Ile-iwe alakọbẹrẹ Ijọba, Uko Uyokim  nibiti o ti gba Iwe-ẹri akobere ní ọdun 1974. Ni ọdun kanáà, o forukọsilẹ wolé sí ilé-èkó Methodist Teachers College Olukọni Methodist ni Oron.

Ni ọdun 1983 Akon wolé si Ile-ẹkọ giga ti Calabar o si fun ni Nigerian Cerrificate(NCE) ni ọdun 1986. Ni ọdun 1990, o gba oye Bachelor of Education (B.Ed) lati University of Calabar. O 4 tèsíwájú nínú ìwé rè. O fé oko, wón sì bi omo àti omo-omo [5]

Isé àti Oselu rèA

àtúnṣe

Akon Eyakenyi bere ise oluko ní odun 1986, o tún sísé ní State Ministry of Education laarin 1993 sí 1999. Ni odun 1991, nigba to n sise oluko, won fi i se Alabojuto fun eto eko, odo, ere idaraya ati Asa ni Oron.

Ni ọdun 2000, a yan gegebi Komisona fun Ile-iṣẹ, oko-òwò ati Irin-ajo ni Ipinle Akwa Ibom lábé ijọba ti Victor Attah. Ni ọdun 2013, Godswill Akpabio yàn gẹgẹbi Alaga Igbimọ awon technical schools in ìpinlè Akwa Ibom. Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Alaga ìgbìmọ̀ náà títí di ìgbà tí Ààrẹ Goodluck Jonathan fi yàn án gẹ́gẹ́ bí Minisita fún ilẹ̀, Ilé àti Ìdàgbàsókè Ìlú ní ọdún 2014. [6]

Ni ọdun 2018, Eyakenyi kede erongba rẹ lati dije fun ile igbimọ aṣofin agba ati aṣoju agbegbe senatorial Akwa Ibom South. [7] Ni Oṣu Kẹwa ọdun 2018, o kopa ninu ìbò primary ẹgbẹ People's Democratic Party (Nigeria) lati ṣe aṣoju agbegbe senatorial Akwa Ibom South o si jawe olubori ninu awọn alakọbẹrẹ.[8] Ni 25 February 2019, a kede rè gegebi olubori ninú idibo gbogbogbo 2019 lati ṣe aṣoju agbegbe senatorial Akwa Ibom South.[2] [3]

Àwon Ìtókasí

àtúnṣe
  1. Ukpong, Cletus (2019-05-20). "9th National Assembly: We’ll not defect, PDP senator assures governor". Premium Times Nigeria. Retrieved 2022-05-21. 
  2. 2.0 2.1 Report, Agency (2019-02-25). "INEC declares PDP winner of Akwa Ibom South Senatorial seat". Premium Times Nigeria. Retrieved 2022-05-21. 
  3. 3.0 3.1 "INEC declares PDP winner in Akwa Ibom South Senatorial District". Daily Trust. 2019-02-25. Retrieved 2022-05-21. 
  4. "Affordable housing: private initiative to the rescue". The Nation Newspaper. 2017-07-06. Retrieved 2022-05-21. 
  5. "I Feel Blessed, Says Senate Newbie Akon Eyakenyi". THISDAYLIVE. 2019-04-19. Retrieved 2022-05-21. 
  6. "Profile – SENATOR AKON EYAKENYI". SENATOR AKON EYAKENYI – TRUE VERSION OF GOOD REPRESENTATION. 2022-03-16. Retrieved 2022-05-21. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  7. "SENATE 2019: AKON EYAKENYI DECLARES INTENTION, CONSULTS FRANK ARCHIBONG.". NetReporters Ng. 2018-08-04. Retrieved 2022-05-21. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  8. "PDP Sen primaries: Akpan, Ekpene, Eyakenyi emerge flag bearers in A-Ibom". Vanguard News. 2018-10-04. Retrieved 2022-05-21.