Akumaa Mama Zimbi
Akumaa Mama Zimbi,tí a tún mọ̀ sí Dr. Joyce Akumaa Dongotey-Padi lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ ,[1][2] jẹ́ oníròyìn orí amóhùnmáwòrán àti rédíò Ghanaian, women's rights ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn, agbéròyìn orí ẹ̀rọ ayélujára, olùgbaninímọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó, àti òṣèrébìnrin ní Ghana. Akumaa jẹ́ mímọ̀ fún ìfanimọ́ra rẹ̀, síbẹ̀ tí ó múni lọ́kàn, ọ̀nà tí ó máa ń gbà sọ pé "Medaase" (Ẹ seun). Ọ̀nà tí ó máa ń gbà wé gèlè rẹ̀ yàtọ̀ pẹ̀lú náà wá láti ilé-iṣẹ́ Akumaa tí ó yàtọ̀ gédégédé. Díẹ̀ ni nǹkan tí a mọ̀ nípa ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀ àti ẹbí àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ pẹ̀lú. Síbẹ̀, ó di mímọ̀ pé ọlọ́pàá ni bàbá rẹ̀ ọkọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ oníṣòwò ní ẹni tí ó ti fẹ́ fún ó lé ní ọdún mẹ́rìnlélógún.
Ìgbési ayé ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ àti Ẹ̀kọ́
àtúnṣeAkumaa di bíbí ní ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù kọkànlá. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Krobo Girls Senior High School. Ó tún padà lọ sí Ghallywood Academy of Film Acting. Ó tún lọ sí Ghana Institute of Journalism.[3]
Ìgbésí ayé iṣẹ́
àtúnṣeAkumaa borí gẹ́gẹ́ bí Òṣèré ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ 1990s nígbà tí ó kópa nínú àfihàn Cantata tó gbajúgbajà gẹ́gẹ́ bí "ọmọ ọ̀dọ̀." Àfihàn yìí di ṣíṣe láti ọwọ́ Ghana Television Station. Ìnífẹ̀ẹ̀sí rẹ̀ nínú ìfiléde ìròyìn, pàápàá jùlọ nínú rédíò, bẹ̀rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2000s. Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò rẹ̀ pẹ̀lú Deloris Frimpong Manso, Akumaa jẹ́ kí ó di mímọ̀ pé Rosemary, Ọ̀rẹ́ rẹ̀ gidi gan-an, se kóríyá fún un láti ṣe àbẹ̀wò sí Joy FM, ẹ̀ka ti Tema, ní ọdún 2000 láti sọ̀rọ̀ nípa ìnífẹ̀ẹ̀sí rẹ̀ nípa ṣíṣe iṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú gbajú gbajà ilé-iṣẹ́ rédíò gẹ́gẹ́ bí akàròyìn.[4]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Akwasi, Tiffany (2018-06-12). "Who is Akumaa Mama Zimbi". Yen - Ghana news. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-03-09.
- ↑ Sasa, Tuandike (2018-06-12). "Who is Akumaa Mama Zimbi". Yen - Ghana news. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-01-11.
- ↑ Ndetei, Chris (2022-11-03). "Akumaa Mama Zimbi’s biography: age, boyfriend, net worth". Yen- Ghana news. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-01-28.
- ↑ Delay TV (2015-06-30), Delay Interviews Akumaa Mama Zimbi, retrieved 2018-10-26