Aláàfin Abípa
Aláàfin Abípa, òun ni a tún mọ̀ sí l Ògbólú tàbí Ọba Moró,[1] jẹ́ Àlááfín Ọ̀yọ́ àti àgbègbè rẹ̀. Wọ́n gbà pé ó wà ní ìtẹ́ ọba Àlááfín ní nǹkan bí sẹ́ńtúrì 16 àti 17. [2]
King Abipa/Ogbolu or Oba M'oro | |
---|---|
Orúkọ míràn | Oba M'oro |
Iṣẹ́ | Alaafin of the Oyo empire |
Nígbà èwe
àtúnṣeÀlááfín Abípa jẹ́ ọmọ bíbí was the son of Egunoju àti ọkàn nínú àwọn olorì rẹ̀. Wọ́n ní wón bí i lọ́nà lọ́jọ́ tí wọ́n ń ṣayẹyẹ kan lọ́nà àtisúnmọ́ ìlú Igboho (wọ́n fún lórúkọ láti inú ọ̀rọ̀ yìí a bí i sí ipà - 'ẹni tí wọ́n bí sí ipà ọ̀nà tàbí ẹ̀bá ọ̀nà').[2]
Kí ó tó di àkókò rẹ̀ ọba mẹ́ta tí jẹ́ lórí Ọ̀yọ́ sí Ìgbòho dípò Ọ̀yọ́ ilé nítorí ìbẹ̀rù àwọn Nupe àti àwọn mìíràn. Abípà ni Àlàáfíà Ọ̀yọ́ tí ó dá olú-ìlú Ọ̀yọ́ padà sí Ọ̀yọ́-ilé lẹ́yìn tí wọ́n ti borí àwọn ogún ti ó ń jàwọ́n láti ìta. Pípadà sí Ọ̀yọ́-ilé wáyé ní sẹ́ńtúrì kẹtàdínlógún (17 Century).[3]
Gẹ́gẹ́ bí àṣà, àwọn ènìyàn pàtàkì kan tí wọ́n fẹ́ kí olú-ìlú Ọ̀yọ́ ṣì dúró sí Ọ̀yọ́-Ìgbòho rán àwọn olórò òfegè láti lọ ṣe aṣojú ọfegè nígbà tí àwọn ènìyàn Abípà ṣe àbẹ̀wò sí olú-ìlú àtijọ́.[4] Abípà mọ nípa èyí, ló bá rán àwọn ọdẹ lọ láti mú àwọn olórò òfegè wọ̀nyí. Nítorí èyí ni wón ṣe ń pè é ní Ọba mórò, Ọba tí ó mú orò. Ìtàn yìí ṣì ń jẹyọ lásìkò ọdún ni Ọ̀yọ́ àti nígbà tí wọ́n bá fẹ́ fi ọba Àlááfín tuntun jẹ.[4]
Nígbà tí ọdún òye wọ Ọ̀yọ́-ilé, Abípà fi ọmọkùnrin aṣẹ̀ṣẹ̀bí rúbọ. Ìdí nìyí tí wón fi máa ń kì í ní "Ọba amórò tó f'ọmọ rẹ̀ rúbọ fún àlàáfíà ayé'.[4]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Law, Robin (1984). "How Truly Traditional Is Our Traditional History? The Case of Samuel Johnson and the Recording of Yoruba Oral Tradition". History in Africa 11: 195–221. doi:10.2307/3171634. ISSN 0361-5413. JSTOR 3171634.
- ↑ 2.0 2.1 Smith, Robert (1965). "The Alafin in Exile: A Study of the Igboho Period in Oyo History". The Journal of African History 6 (1): 57–77. doi:10.1017/s0021853700005338. ISSN 0021-8537.
- ↑ African sacred spaces : culture, history, and change. ISBN 9781498567428. OCLC 1077789018.
- ↑ 4.0 4.1 4.2 Smith, Robert (1988). Kingdoms of the Yoruba. Currey. ISBN 0852550286. OCLC 813599097.