Aláàfin Kòrì
Aláàfin Kòrì jẹ́ Ọba Àlááfín Ọ̀yọ́ láàárín ọdún 1340. Lásìkò rẹ̀ ni ó wọ́n dá ìlú Ẹdẹ àti Òṣogbo sí lẹ̀.[1] Ìtàn sọ wípé, òun ló rán Tìmì lọ sí Ẹdẹ láti bá àwọn Ìjẹ̀ṣà jà. Lẹ́yìn ìjà náà ni Tìmì fi ara rẹ̀ jọba l'Ẹ́dẹ. Èyí ló fàá tí wọ́n fi ń pe òye ọba ìlú Ẹdẹ ni Tìmì. Odidi ọdún àádọ́ta ni Àlááfín Kòrì lò lórí ìtẹ́ Ọba Àlááfín. Èyí ni wọ́n fi ń sọ pé òun ni ìgbà rẹ̀ gùn jú nínú àwọn ọba Àlááfín Ọ̀yọ́
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Alaafin of Oyo: Wo Alàáfin 43 tó jẹ́ láti ìgbà ìwásẹ̀ ṣáajú Lamide Adeyemi tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wàjà". BBC News Yorùbá. 2022-04-24. Retrieved 2024-06-18.