Aláàfin Osiyago tàbí Aláàfin Oṣìyàgò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Aláàfin Ọ̀yọ́ tí ó j'ọba nílùú Ọ̀yọ́ láti ọdún 1690 sí 1692. [1] Ó jẹ́ ọba tí ó l'opò ọba nílòkúlò. Owó àti ọ̀rọ̀ ṣá ló ń k'ójọ láìbìkítà bí ìlú yóò ti dára tàbí tùbà-tùṣẹ. Kò kúkú pẹ́ púpọ̀ lórí oyè láti gbádùn gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tó kó jọ. Kò bójú tó àwọn ọmọ rẹ̀ d'ébi pé ọkàn nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pa ọmọ rẹ̀ obìnrin. Májèlé ni wọ́n padà fún òun náà jẹ ti ó fi kú. Odidi ọdún mẹ́rìndínlógójì ni ipò Aláàfin Ọ̀yọ́ fi ṣ'ófo lẹ́yìn ikú rẹ̀, tí ó fi jẹ́ wípé Baṣọ̀run ló ń darí ìlú Ọ̀yọ́ nígbà náà. [2]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe